Bọọda Kaṣamu, ẹ yee fi mẹkunnu ṣe yẹyẹ mọ, ko daa o

Spread the love

Ọlọrun nikan lo mọ ọjọ ti iru awọn eeyan bii Buruji Kaṣamu, Sẹnetọ lati ipinlẹ Ogun yoo sinmi a n fi awọn eeyan ilu ṣe yẹyẹ, a n sọ awọn araalu di alumanjiri bii awọn ara ilẹ Hausa. Lasiko ipari aawẹ to lọ yii, Buruji ko ọpọlọpọ baagi jọ, ninu baagi kekere yii lo ko ẹbun ti yoo fun awọn eeyan si, ko si too di ọjọ naa ni wọn ti kede, ti wọn ni ki gbogbo eeyan waa to soju ode gbangba, ki wọn maa gba ounjẹ itunu ati owo taṣẹrẹ ti yoo fun wọn. N lawọn eeyan ba rọ de, bi wọn si ti n de ni wọn n ya wọn ni fọto, ti wọn n ya wọn ni fiimu, ki wọn le fi wọn royin ero to pọ rẹpẹtẹ lọdọ Kaṣamu. Yatọ si iyẹn, baagi ti wọn fi gbe nnkan ọdun aawẹ naa si fun wọn, ipolongo ibo bi Kaṣamu yoo ṣe tun pada si ile-igbimọ aṣofin lẹẹkeji lo wa nibẹ, ọkunrin naa n polowo ara rẹ ni. Ẹ wo o, Ọlọrun ko ṣee tan jẹ o. Ṣe Kaṣamu n polongo ibo rẹ ti ọdun to n bọ ni, abi o n ṣiṣẹ laada? Ṣe ọkunrin yii n ṣe oore fawọn eeyan ni, abi o n lo wọn fun oṣelu tirẹ lasan. Ko si tabi-ṣugbọn nibẹ, eyi ti ọkunrin oloṣelu yii ṣe ko ni kinni kan i ṣe pẹlu ofin Ọlọrun lasiko aawẹ, oṣelu loun n ṣe, o kan lo orukọ Ọlọrun ati asiko ofin Ọlọrun lati fi lu awọn araalu ni jibiti ibo lasan ni. Amọ ta la ri ba wi bi ki i ṣe awọn ti wọn lọọ to si gbangba ti wọn n reti ounjẹ tọrọ kọbọ, eyi to si buru ni pe ounjẹ ti ẹlomiiran le ra nile rẹ ti yoo jẹ ni wọn tori rẹ sa a sinu oorun yẹn. Ẹyin naa ẹ yee jẹun ọran, ẹ yee jẹ ijẹkujẹ kiri, ẹ yee tojubọle. Ohun ti awọn oloṣelu n lo niyẹn, iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan ja ni wọn maa n lo, wọn yoo lọọ gba owo to tọ si yin lati fi tun agbegbe yin ṣe ni Abuja, wọn yoo maa fi iyẹn ṣe afẹfẹyẹyẹ, wọn yoo ran ọmọ wọn nileewe, wọn yoo da ileeṣẹ silẹ, wọn yoo maa waa ṣe saara ounjẹ fẹyin. Ẹyin naa ẹ ronu kẹ ẹ yee tẹle wọn, adiyẹ lasan ni wọn pe yin, wọn ti mọ pe igbakigba ti awọn ba ti fẹẹ ko ẹyin, bi awọn ba ti ju agbado silẹ, ẹ oo maa sare bọ ni. Bi Kaṣamu ti ṣe yii naa ni Saraki ati baba rẹ ṣe n’Ilọrin ti wọn fi mu awọn eeyan ibẹ, ti idagbasoke kan ko si debẹ ba wọn, oun naa ni wọn ṣe nilẹ Hausa titi dasiko yii, kinni naa si pọ laarin awọn ti wọn n ṣe ẹgbẹ PDP. Wọn ti nigbagbọ pe ti awọn ba ti fun araalu ni wan-wan taosan, tabi ti awọn di ounjẹ kuduru sibi kan, wọn yoo dibo fawọn. Iru nnkan bẹẹ ko dara, ẹtan ni, ẹ ma jẹ ki awọn eeyan bii Kaṣamu tan yin pa. Wọn ko wa lati tun aye yin ṣe, wọn waa ba yin laye jẹ lati fi tun aye tiwọn ati tawọn ọmọ wọn ṣe ni. Ẹ yẹra fun wọn ki wọn too sọ ori yin di korofo!

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.