Bọla, ẹ ma ta wa fun Fulani, eleyii o daa o

Spread the love

Ọrọ ti mo fẹẹ sọ yii, n ko fi ibinu sọ ọ o. Nitori bẹẹ, n ko fẹ kẹyin naa fi ibinu gbọ o. Laakaye ni mo fẹ ki ẹ fi gbọ o, nitori gẹgẹ bi mo ṣe maa n wi, asiko yii ki i ṣe asiko to yẹ ka ba ara wa ja, ka ṣalaye ọrọ funra wa ni. Mo n sọrọ bayii nitori n ko fẹ kawọn eeyan Bọla (Tinubu), bẹrẹ ibinu ojiji ni. Awọn ni wọn ki i fi ara balẹ gbọrọ, to o ba ti sọrọ ti o mu ẹnu kan Bọla, bii igba pe o kan wọn ni eewo ni, wọn yoo bẹwu silẹ, wọn yoo gbe apẹrẹ wọ, wọn si le bu iya rẹ ki wọn fi baba rẹ le e. Bẹẹ ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn n ja ajaku-akata yii ko mọ aburo wa yii rara o, koda, ẹlomi-in ko ba a pade ri ninu wọn. Awọn iroyin ti wọn n gbọ, boya irọ boya ootọ, boya eke tabi ariwo lasan, awọn ọrọ ti wọn n gbọ yii ni wọn fi n sọrọ, ti wọn fi n huwa, to si jẹ bi awọn ti wọn mọ Bọla daadaa ba sọ pe iwa rẹ ree, eebu lawọn yii yoo maa bu wọn.
Ohun ti mo ṣe fẹ ki wọn baralẹ ka ọrọ mi ree, ki wọn ma ti i wọ ẹwu ibinu titi wọn yoo fi ka a tan. Bọla sọrọ kan lọsẹ to kọja ni, ọrọ naa jo mi lara. Bo ba si jẹ nigba ti mo ṣi n binu rẹpẹtẹ ni, n ba binu debii pe ori iba maa fọ emi gan-an alara. Ṣugbọn mo binu diẹ, mo mumi ni, nitori n ko fẹ ohun to le mu ẹjẹ mi ru soke rara. Bọla sọ pe ki Buhari tete ṣe ofin kan, ki wọn gba gbogbo ilẹ ti awọn onilẹ ati ijọba ipinlẹ kọọkan ko lo, ki wọn gba wọn kia, ki wọn gbe wọn fawọn Fulani onimaaluu, kawọn Fulani yii le maa ribi ṣiṣẹ aje wọn. Ko duro sibẹ. Bọla ni ko sohun to n fa ija ati arinkiri awọn Fulani yii ju omi lọ. O ni omi ni wọn n wa kiri, wọn n wa ibi ti wọn ti le mu omi, tawọn maaluu wọn naa yoo si mu omi ni. Ẹni ti orungbẹ ba n gbẹ, ko si iwakiwa ti ko le hu. Ohun to jẹ ki wọn maa pa awọn eeyan kiri niyẹn. Bi Bọla ti wi ree.
Mo ti sọrọ kan nibi yi lẹẹkan. Mo ni nigba ti wọn ba darukọ Ladoke Akintọla loju awọn agbaagba ilẹ Yoruba, ti wọn ba poṣe tabi ti wọn ba n ṣepe, tabi ti wọn ba n pe awọn oṣelu to ba n huwa bii Akintọla ni ọdalẹ ati akotileta, tabi ti wọn n pe wọn ni ọta Yoruba, ki i ṣe pe Akintọla ko ni daadaa kan to ṣe nigba to fi n ṣejọba ilẹ Yoruba, oun naa ṣe iwọnba to le ṣe. Ohun to ṣe fun Yoruba ti Yoruba ko fi dariji i ni pe o ta wa fun Fulani, o ko wa si abẹ Fulani, o sọ wa di iranṣẹ wọn. Ajaga to fi bọ wa lọrun nitori ọrẹ rẹrunrẹrun to ba Sardauna ṣe ko kuro lọrun wa titi doni. Gbogbo iṣoro to ba wa nilẹ Yoruba, ti a ba ja titi ti ko lọ, gbogbo idaamu ogun abẹle, gbogbo ariwo ATUNTO (Restructuring), ti a n pa loni-in yii, awọn eso aburu ti ọrẹ Sardauna ati Akintọla mu wa si ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ niyẹn.
Eyi to buru ju ninu ohun to ṣe fun wa ni eto ikaniyan (census), akọkọ ti wọn ṣe ni Naijiria to fihan pe apapọ Yoruba ati Ibo pọ gan-an ju awọn eeyan ilẹ Hausa lọ. Sardauna mọ ewu buruku to wa ninu eyi, o mọ pe bi wọn ba fi le sọ pe Ibo ati Yoruba pọ ju Hausa lọ, yoo ṣoro ki Hausa too ṣe olori ijọba Naijiria. Bi wọn ko ba si ṣe olori ijọba, yoo ṣoro ki wọn too maa pin ọrọ, owo ati awọn ohun-alumọọni gbogbo to jẹ ti Naijiria sọdọ ara wọn. Sardauna mọ eleyii, ṣugbọn Akintọla ṣe bii ẹni pe oun ko mọ. Igba ti wọn ti fọtẹ gbe Awolọwọ sẹwọn ni Sardauna ti n fọgbọn halẹ mọ Akintọla pe to ba fẹ ki oun maa ṣe atilẹyin foun, afi ko maa ṣe ohun tawọn ba fẹ fawọn, iyẹn lọrẹ apapandodo ti Akintọla n ba Sardauna ṣe, to wa n halẹ kiri ilẹ Yoruba pe alagbara loun, ko sohun ti oun pa ti ko ku, nitori oun lọrẹ Ahmadu Bello nilẹ Yoruba.
Akintọla tan awọn ọba Yoruba, o purọ fun wọn pe sẹnsọ ti wọn ka yẹn, bi awọn ba ti Ibo lẹyin, awọn aa di ẹru Ibo gbẹyin ni o, ki awọn ba Hausa lọ lo daa, ki awọn gba ohun ti Sardauna n wi, nitori anfaani wa ninu ka gba pe awọn Hausa pọ ju wa lọ loootọ, bo tilẹ jẹ pe irọ ni. Bẹ lawọn ọba Yoruba jade, ti wọn ni awọn wa lẹyin Akintọla, ohun to ba ṣe lawọn ṣe, aṣoju awọn ni. Awọn eeyan bii Ricahrd Akinjide, Adisa Akinloye, Rẹmi Fani-Kayọde, ati awọn ọdọ igba naa ti wọn n tori owo ati ipo ṣe oṣelu tẹle Akintọla, wọn ni ohun to n ṣe lo daa. Abọ ẹ niyi o! Ṣebi sẹnsọ naa lo sọ gbogbo Naijiria sabẹ akoso Fulani titi doni, nitori lati ọjọ naa, ko sẹni to le ka sẹnsọ kan ti wọn yoo sọ pe Yoruba ati Ibo pọ ju Hausa lọ. Irọ naa lo n ba wa ja titi doni, ti ijọba Naijiria ko yee sọ pe Kano lo pọ ju Eko lọ.
Iru iwa ti Akintọla hu nijọsi naa ni Bọla atawọn eeyan rẹ bẹrẹ yii, koda, mo fẹrẹ le sọ pe n ko ri iyatọ kan laarin Akintọla ati Bọla. Oun tilẹ tun buru ju Akintọla lọ. Ki i ṣe owo ni Akintọla n wa, ipo ati agbara oṣelu lo n wa. Ṣugbọn ki i ṣe ipo ati agbara nikan ni Bọla n wa, oun n wa owo gidi, nitori o mọ pe owo nikan loun le fi ra awọn eeyan, nitori awọn to ba ti fun ni tọrọ-kọbọ yoo maa pariwo kiri pe awọn ko ri iru rẹ ri ni, bo tilẹ jẹ pe owo ọjọọla wọn, owo to tọ si awọn ati ẹbi wọn, owo to yẹ fun idagbasoke gbogbo ilu lo n rogun sọwọ oun nikan, to si n ha diẹ le awọn lọwọ nibẹ. O mọ daadaa pe ko si bi oun ti le ri iru owo bayii pẹlu iṣẹ ọwọ oun ati ọna mimọ, ọna kan ṣoṣo ti owo bẹẹ fi le wọle ni ka jale nidii oṣelu ti a ba n ṣe. Nigba tanfaani si ṣi silẹ, o ṣe ohun to wa lọkan ẹ. Bẹẹ ẹni kan o ni i ji owo ijọba ko tun maa bajọba ja, wọn yoo ran an lẹwọn ni.
Eyi lo n fa awọn ọrọ to n tẹnu ẹ jade lasiko yii, ki i ṣe pe Bọla ko mọ ohun to dara. Bẹẹ ni ki i ṣe pe ko fẹran Yoruba bi aaye ẹ ba wa, o kan jẹ pe bi ina ba ta jo ni to ta jo ọmọ ẹni, tara ẹni la a kọkọ gbọn danu ni. Ọrọ Yoruba kọ lo ṣaaju ninu iwe-eto tirẹ, ọrọ tara ẹ lo ṣaaju, bo ba tẹ ara ẹ lọrun lo too kan iran Yoruba. Ko sohun to buru ninu iyẹn, bi ki i baa ti i ṣe owo ati orukọ Yoruba lo n lo lati fi ko ọrọ tirẹ jọ. Tabi bawo ni Bọla yoo ṣe dide ti yoo sọ pe ki ijọba apapọ gba ilẹ ti awọn eeyan ko ba lo lọwọ wọn ni gbogbo ipinlẹ to n bẹ ni Naijiria, ki wọn si sọ ibẹ di aaye fawọn Fulani ki wọn maa sin maalu wọn nibẹ, nitori pe wọn o ri omi mu. Ṣe ẹyin ti ẹ mọ Bọla daadaa, tabi ẹyin ti ẹ n tẹle ọrọ ati oṣelu ẹ, ṣe ẹyin naa ro pe iru ọrọ bẹẹ le jade lẹnu ẹ ṣaa. Ṣe ka sọ pe ko gbọn ni tabi ko mọ itan to.
Bọla gbọn o, o si mọ itan daadaa. O mọ pe ko siyatọ ninu ohun ti oun sọ pẹlu tawọn Buhari ti wọn fẹẹ da abule Fulani silẹ ni gbogbo ilu nla orilẹ-ede yii; o mọ pe ko siyatọ ninu ọrọ ti oun sọ pẹlu eyi ti ẹgbẹ awọn Fulani onimaalu sọ pe baba awọn lo nilẹ ni ibikibi ni Naijiria, awọn si lẹtọọ si i. Tabi ṣe ko si odo ni Sokoto ati Kano ni, tabi Maiduguri, ti maaluu ti le mumi ni! Tabi ṣe dandan ni fun ijọba Naijiria lati pese owo atawọn eelo ti Fulani yoo fi ṣe iṣẹ aje wọn fun wọn ni. Bọla gbe Amẹrika daadaa, ṣe bi ijọba ilu ti oun gbe ṣe gba ilẹ onilẹ ti wọn gbe e fun awọn kan pe ki wọn maa da maalu kiri ibẹ ree ni, tabi oun ri maalu nigboro Amẹrika. Ṣe Bọla yoo sọ pe oun ko mọ pe ilu ati ilẹ ti Fulani ba dasẹ wọ, ko sẹni ti yoo le wọn jade mọ ni. Ṣe Bọla fẹẹ ta wa fun Fulani loootọ loootọ ni. Eleyii o daa o!

(99)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.