Bo ba sọ pe oun o le fẹsẹ oun rin, ẹ gbe e jare

Spread the love

Iroyin to daa lo jade lọsẹ to kọja pe awọn ọlọpaa agbaye ti fi orukọ obinrin ti wọn n pe ni, Diezani Madueke, minisita fun ọrọ epo bẹntiroolu laye ijọba Jonathan sita, wọn ni ibikibi ti wọn ba ti ri ọmọbinrin yii ni ki wọn ti mu un, ki wọn si ṣeto bi wọn yoo ti sọ ọ loko pada si Naijiria yii kiakia. Intapo (Interpol) lorukọ awọn ọlọpaa agbaye to n wa obinrin naa bayii, o si daju pe ko le pẹ, ko le jinna, ki wọn too ra a mu. Awọn owo buruku to sọnu laye Jonathan, awọn ole ti wọn ja laye rẹ ati awọn owo NNPC, ileeṣẹ elepo ilẹ wa to n lọ si bii biliọnu owo dọla, wọn ni ko si eyi to ṣẹyin obinrin yii nibẹ, wọn si ti pe e titi ko dahun, o sa lọ lati igba ti Buhari ti gbajọba. Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yoo ha ya ọ, ki lo n le obinrin naa kiri bo ba jẹ loootọ lọwọ rẹ mọ, ki lo sa lọ fun lati bii ọdun mẹrin nilẹ yii nigba to mọ pe oun ko ṣe nnkan kan. Nigba to kọkọ lọ nilẹ yii, niṣe lobinrin naa lọọ ya fọto, to fari kodoro, to ni arun kansa n yọ oun lẹnu. Ẹni ti kansa ba mu to bo ti yọ ninu fọto nigba naa, iru obinrin bẹẹ ko tun le si laye mọ. Ṣugbọn kaka ki kansa ṣe obinrin yii leṣe, niṣe lo n jaye ori rẹ kiri, wọn si pe e nile ko dahun, o jokoo si London, nibi to sa si. Ṣugbọn ni bayii ti ọrọ ti ni ọwọ awọn ọlọpaa agbaye ninu, ibi ti yoo gba ni ẹnikan ko mọ, ọna to fẹẹ gbe e gba ti ọwọ awọn araalu ko ni i to o loun naa ko mọ, nitori ko si ibi ti Intapo ko si, wọn yoo mu un laipẹ jọjọ, bi ọwọ ba si tẹ ẹ, wọn yoo sọ yẹyẹ loko wa si Naijiria, yoo waa foju kan awa to ko owo wa jẹ.

 

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.