Bo ba jẹ loootọ ni Buhari fẹran Naijiria, ko ni i ṣe eleyii to ṣe yii

Spread the love

Bi wọn yoo ba wi, wọn aa ni Buhari ni baba awọn. Bi wọn yoo ba sọ, wọn aa ni awọn ko rẹni to fẹran Naijiria to Buhari. Ti mo ba ti n gbọ iru awọn ọrọ wọnyi, tabi ti n ba n ka wọn, paapaa lẹnu awọn ọdọ, awọn ọmọde wa, tabi awọn agba kọọkan ti wọn ro pe awọn mọ ohun ti awọn n sọ ṣugbọn ti wọn ko mọ ọn, niṣe ni mo maa n beere ninu ara mi pe ṣe awọn eleyii ko riran ni. Mo maa n beere pe ṣe awọn eeyan yii ko ni laakaye ni. Bi wọn ba fọ loju inu, ṣe wọn tun fọ loju ode ni. Ṣe awọn ko mọ pe Buhari ko ṣiṣẹ fun Naijiria ni, awọn Hausa-Fulani ni Buhari waa ṣiṣẹ fun, gbogbo ariwo ti a si n pa, ko seyii to kan an nibẹ, ohun to fẹẹ ṣe naa lo n ṣe lọ. Bi Naijiria ba fẹẹ bajẹ, ko kan Buhari, bi awọn Fulani ba ti le ri gbogbo ọrọ, owo ati awọn alumọọni ile yii ko, abuṣe buṣe. Ṣugbọn awọn eeyan wa loju lasan ni, wọn ko riran.

O le pẹ o le ya ni, awọn Fulani yii yoo fi ogun ja wa, ogun naa yoo si buru fun Yoruba pupọ gan-an. Ọrọ yii le ma ṣe ogun ọdun, o le ma ṣe ọgbọn ọdun, ṣugbọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ni. Ọna kan ṣoṣo ti Yoruba fi le bọ ni ki awọn naa mura silẹ, ki wọn ti gbaradi, ki wọn mọ pe ohun ti yoo ṣẹlẹ ni. Ṣugbọn ta ni yoo gbaradi, ta ni yoo mura silẹ, ṣe awọn to jẹ bi o ti n sọrọ yii ni wọn n pe ọ ni ayiri ati agbaaya, ti wọn n sọ pe nitori to o jẹ PDP lo ṣe n sọ isọkusọ lẹnu. Bẹẹ nigba ti kinni naa ba de, lọjọ to ba ṣẹle, ti ki i baa ṣe pe Yoruba ti murasilẹ, iji lile ti yoo ja nilẹ Yoruba yoo ju eyi ti a ti ri nibikibi lọ. Wọn ko ni i ri wọn pa ni Naija-Delta, nitori gudugudu lawọn yii, wọn ko fi igba kankan tura silẹ, bẹẹ ni wọn o le ri wọn mu nilẹ Ibo naa, nitori awọn ko fi ọjọ kan yee mura ogun. Ṣugbọn imura wo ni Yoruba ṣe silẹ, ta ni yoo ja fun wa.

Ojumọ kan, imura kan lawọn Fulani n ṣe, awọn eeyan wa ni wọn ko ri wọn. Awọn oloṣelu Yoruba ko riran, awọn to riran ti gbabọde, ole ati iwa ọdalẹ wọn ko jẹ ki wọn mọ ohun to n ṣẹlẹ ni ayika wọn. Bi ko ba waa jẹ bẹẹ ni, bawo ni wọn o ṣe ni i ri igbaradi tawọn Fulani n ṣe, bawo ni wọn o ṣe ni i ri imura Buhari, ki wọn si mọ pe Buhari lawọn eeyan yii fẹẹ lo lati gba ilẹ yii fun Fulani, tabi lati sọ gbogbo ẹya to ku di ẹru wọn. Iṣẹlẹ kan waye lọsẹ to kọja yii, ohun to yẹ ko pa ẹni to ba ni arojinlẹ lẹkun ni. Ṣugbọn ẹrin lawọn oloṣelu fi n rin, inu wọn n dun, awọn ti ko niye ninu paapaa n sọ pe lara oriire ti ijọba Buhari ko de niyẹn, lara aṣeyori ti ẹgbẹ awọn n ṣe la ri yẹn. Wọn ko mọ pe kinni naa ki i ṣe aṣeyọri, aṣedanu ni; wọn ko mọ pe kinni naa ki i ṣe oriire fun Naijiria, nnkan ti yoo pada ko ba wa lẹyin ọla ni.

Ijọba orilẹ-ede Nairjia ati ti orilẹ-ede Nijee (Niger Republic) tọwọ bọ iwe adehun kan. Iwe adehun naa ni pe wọn yoo kọ ileeṣẹ ifọpo (Refinery) kan si Katsina, wọn yoo waa ṣe ọna reluwee lati ilu Katsina yii titi wọ orilẹ-ede Nijee. Njẹ ẹ mọ ohun ti wọn ni awọn ṣe fẹẹ ṣe e, wọn ni ki Nijee le maa ta epo bẹntirooliu rẹ fun wa ni Naijiria ni. Epo bẹntiroolu ti Nijee ba ta fun wa yii, Katsina ni wọn yoo ti maa fọ ọ, nibẹ ni wọn yoo si ti maa pin in kari. Awọn ti wọn mọ nipa eto ọrọ-aje ti kọkọ sọ fun Buhari pe kinni naa ko le mu ere wa, aṣedanu lasan ni, ko pa a ti. Ṣugbọn ko gba, o ni ohun ti oun fẹ ni ki wọn ṣe. Nigba ti olori orilẹ-ede Nijee si waa jokoo ti i nibi lọsẹ to kọja, Buhari mu minista to n ri si ọrọ epo bẹntiroolu lẹyin, o ni ko lọọ tọwọ bọ iwe adehun yẹn lorukọ Naijiria, oun naa si duro ti wọn gbagbaagba.

Iyẹn lawọn ti wọn ti kọ pe awọn ko fẹẹ gbọn n tori ẹ jo si o. Bẹẹ ibeere akọkọ to yẹ ki awọn eeyan yii beere ni pe ki lo de to jẹ Katsina ni wọn ṣe e si, kin ni wọn gbe ile ifọpo lọ si Katsina si? Nigba ti wọn ba kọ ile ifọpo si Katsina, wọn yoo ṣẹṣẹ ṣe titi oju-irin lati ibẹ, wọn yoo waa ni ki Nijee maa ta epo fun wọn. Ninu orilẹ-ede Nijee, ati Naija Delta tiwa, ewo lo sun mọ Katsina julọ. Lọna keji, ki lo de ti wọn tun n lọọ kọ ileeṣẹ-ifọpo mi-in si Katsina, nigba ti ọkan wa ni Kaduna ti ko ṣiṣẹ daadaa. Ṣebi bi Buhari ba fẹẹ ran ilu yii lọwọ, ṣebi eyi to wa ni Kaduna lo yẹ ki wọn tunṣe. Ṣugbọn awọn Buhari mọ ohun ti wọn n ṣe. Wọn mọ ọn daadaa. Orilẹ-ede Nijee ati Katsina pẹlu Sokoto jọ paala ni, ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ Naijiria, orileede Nijee ni abule wọn wa, ibẹ ni orirun wọn.

Awọn ẹya ti wọn wa ni Nijee, ẹya mẹta to pọ ju naa ni Fulani, Tuareg ati Bororo. Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn wa ni Sokoto, Katsina ati awọn ilẹ Hausa mi-in. Ibi ti awọn Fulani, Bororo ati Tuareg si n ba wọ Naijiria niyi, ti awa ko si mọ iyatọ laarin wọn. Lati orilẹ-ede Nijee ni Uthman Dan Fodio ti gbe ogun Jihaad rẹ wọ Naijiria tiwa, ọpọlọpọ awọn ti wọn si n ṣe ọba ati ijoye lawọn ilẹ Hausa yii, ọmọ Nijee lo pọ ninu wọn. Nibẹ ni oko ati abule wọn wa, awọn abule mi-in si wa to jẹ bo ṣe wa ni Nijee, bẹẹ naa lo wa ni Naijiria, ọmọ ile kan naa lawọn ti wọn wa nibẹ. Iyẹn la ki i ṣe e da wọn mọ yatọ bi wọn ba wọ Naijiria, bi a ko ba pe wọn ni Fulani, a oo pe wọn ni Bororo, bi o ba si beere ibi ti wọn ti wa, wọn aa ni Sokoto ni. Bẹẹ wọn ki i ṣe ara Sokoto, ara Nijee ni wọn, awọn ara North si maa n lo wọn lasiko ibo daadaa.

Iyẹn ni Buhari ṣe fẹẹ fi owo Naijiria tọju ilẹ Nijee. Iyẹn ni wọn ṣe ni ka lọ sibẹ ka maa lọọ ra epo bẹntiroolu. Ọrọ ti ko ṣee gbọ seti rara ni. Njẹ ẹ mọ pe ninu awọn orilẹ-ede ti a ti le ri epo ni gbogbo ilẹ Afrika yii, Naijiria ni nọmba waanu, ipo kẹtadinlogun ni Nijee wa si wa. Pabambari ni pe epo ti Nijee yoo ṣe fun odidi ọdun kan, ọjọ meji ni Naijiria yoo fi ṣe e. Ẹyin naa tun le ṣe iṣiro ẹ. Garawa epo mọto ẹgbẹrun lọna ogun (20,000 barrels) ni wọn n ṣe ni Nijee lojumọ kan. Bẹẹ ni Naijiria, miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna irinwo (2,400, 000 barrels) lawa n ṣe, epo ti a ba si ṣe lọjọ kan, oṣu mẹfa geere ni orilẹ-ede Nijee yoo lo lati fi ṣe e. Bawo waa ni awa ti a n ṣe epo ti Nijee yoo fi oṣu mẹfa ṣe lọjọ kan yoo ṣe lọọ maa ra epo ni Nijee? Iru ayipada-si-aburu wo niyẹn. Bẹẹ ki i ṣe ayipada-si-aburu, awọn Buhari mọ ohun ti wọn n ṣe.

Bi wọn ba pari rẹ, wọn yoo maa fi ile ifọpo naa rọ owo dọla lọ si Nijee ni, wọn aa ni awọn ti ra epo, tabi awọn san asansilẹ fun wọn, bẹẹ epo bẹntiroolu ti a n ṣe ni Naijiria naa la oo maa lo, wọn kan fẹẹ maa lu wa ni jibiti ni. Bi Buhari ba fẹran Naijiria, to si jẹ loootọ lo fẹẹ maa ra epo ni Afrika, ṣebi Cameroon lo wa lẹgbẹẹ wa yẹn, Cameroon sun mọ Naija Delta, ko si ṣẹṣẹ niidi ki wọn kọ ọna reluwee tabi ile ifọpo, oju-omi ni wọn yoo gbe e gba, laarin wakati kan pere, epo naa yoo wọ orilẹ-ede Naijiria, ni ilẹ Ibo tabi Naija-Delta. Ṣugbọn Buhari ko ni i ṣe bẹẹ, nitori ki i ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe niyẹn. Eto idagbasoke Naijiria kọ lo wa lọkan wọn. Ohun to wa lọkan wọn ni lati ko owo rẹpẹtẹ pamọ si orilẹ-ede yii, ki wọn maa fi ra ohun ija pamọ, ki wọn lo owo wa fun idagbasoke ibẹ, nigba ti wahala ba ṣẹlẹ, orilẹ-ede yẹn ni wọn yoo ti maa gba gbogbo eelo ogun ti wọn ba fẹ.

Buhari fẹẹ pa wa lara ni. Wọn fẹẹ gba owo wa ki wọn fi kọ orilẹ-ede nla fawọn Fulani, nigbẹyin, wọn yoo fọ Naijiria, bi Naija Delta ba ni oun ko lepo mọ, wọn aa ti ko epo wa lọ sibẹ, wọn yoo si ti ni owo rẹpẹtẹ lọwọ lati fi ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Bawo leeyan yoo ṣe lọwọ si gbogbo eleyii tawọn kan yoo si ni eeyan daadaa ni, to jẹ bi o ba ti sọrọ ni wọn yoo ti gbe ẹnu soke pe PDP ni ọ. Ko si omugọ to buru ju laye yii ju ẹni to ri ootọ, to si da a mọ pe ootọ ni, ṣugbọn to taku pe irọ tawọn kan n pa fun un loun yoo maa tẹle kiri. Lọjọ ti ohun ti a n wi yii ba ṣẹlẹ, iru wọn ni aburu ati inira to pọ julọ yoo ba. Oju awa ko ni i ribi o.

 

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.