Bisọla to jale ni ṣọọbu ọga rẹ ti foju ba kootu

Spread the love

Kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, niluu Eko, ni wọn gbe Bisọla Bello, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja nitori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an. Ọja bii irinwo le mẹta Naira (403,000.00), lo ji lọdọ ọga rẹ.
Afurasi ọdaran naa to n gbe ni adugbo Mushin ni wọn wọ lọ siwaju Adajọ A. Ogundare, nibi ti wọn ti fi ẹsun ole jija kan an, eyi to ni oun ko jẹbi rẹ.
Agbefọba to n rojọ tako o ni kootu, Emmanuel Ajayi, ṣalaye pe ọjọ karun-un, oṣu yii, ni afurasi naa huwa ọhun laduugbo Olumorokun, Mushin. O ni ọja bii irinwo le mẹta Naira ni olujẹjọ naa ji ko lọdọ ọga rẹ, Titilayọ Fashina.
O sọ pe ontaja ni Abilekọ Fashina gba Bisọla, ṣugbọn lọjọ to ṣe ayẹwo bo ṣe n ta ọja lo ṣakiyesi pe awọn ọja naa dinku, bẹẹ ni ko si akọsilẹ owo ọja naa rara.
Ajayi ṣalaye pe Bisọla ko le ṣalaye bo ṣe nawo naa, eyi lo si fa a to fi dero teṣan ọlọpaa, lọdọ wọn lo si gba de kootu. Ẹsun naa tako abala kan ninu iwe ofin iwa ọdaran ti ipinle Eko ṣagbekale rẹ lọdun 2015, ẹwọn ọdun meje si ni ẹni to ba jẹbi rẹ yoo fi gbara.
Ṣa, Adajọ Ogundare faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira silẹ, pẹlu oniduuro meji to niṣẹ gidi lọwọ, ti wọn si n san owo ori wọn deede. Ọjọ keje, oṣu to n bọ, lo sun igbẹjọ mi-in si.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.