Bi wọn ṣe sọrọ Omiṣore, bẹẹ naa lo ri

Spread the love

Nigba ti wọn n dibo l’Ọṣun, ti wọn ni ibo ẹgbẹ APC ku diẹ ko pe, ti awọn aṣaaju ẹgbẹ ati awọn olori ẹgbẹ PDP sare jannajanna, ti wọn lọọ ba Omiṣore nile, ti wọn ni ko ma ba ẹlomi-in ṣe, ẹgbẹ to ti fi ọdun gbọgbọrọ ṣe ki ija too de ni ko ran lọwọ, ti awọn aṣaaju APC naa sare balabala, tawọn naa lọọ ka Iyiọla mọle, ti wọn ni awọn ni ko ran lọwọ ki awọn le wọle, awọn dadandindin, awọn ẹni ti ko gbọn, awọn ẹni ti ko mọran, wọn ni nitori ifẹ awọn ara Ọṣun, nitori ilọsiwaju Ileefẹ, ati nitori ki Naijiria le daa ni Omiṣore ṣe fi ẹgbẹ PDP tirẹ silẹ, to ba APC lọ. Ni bayii, ẹni to ba woye ọrọ yoo ri i pe Omiṣore ko ṣe kinni kan nitori Ileefẹ, tabi nitori awọn eeyan Ọṣun, nitori ara rẹ ni. Omiṣore ni ẹjọ lọdọ awọn EFCC, wọn ti gba pasipọọtu rẹ pamọ, bẹẹ ni owo ti oun naa ji ko lati ọjọ yii to ku lọwọ rẹ, ko ti i le na an, nitori awọn EFCC n ṣọ ọ. Lara adehun ti awọn APC ṣe ni pe ko ni i ni ẹjọ kankan niwaju EFCC mọ bo ba le dọrẹ APC, bẹẹ ni wọn yoo da pasipọọtu rẹ pada fun un, owo yoo si tun tidi ẹ yọ fun un. Igbesẹ akọkọ ti ṣẹlẹ bayii, EFCC ti da pasipọọtu Omiṣore pada fun un, itumọ rẹ si ni pe ọwọ rẹ mọ, ẹsẹ rẹ mọ, nitori oun ṣaa ti wẹ iwẹ odo bii awọn ọmọ Sẹlẹ, EFCC ti wẹ ẹsẹ rẹ kuro nigba to ti di ọmọ APC, ko si ibẹru tabi ifoya mọ, ko maa jaye ori rẹ lọ ni. Ẹni kan waa jokoo sibi kan, o ni Naijiria yoo toro, ta ni ko mọ pe yoo maa bajẹ si i ni. Epe kọ o, bi yoo ṣe maa ri niyẹn, afi lọjọ tawọn EFCC ati ijọba Buhari yii ba ṣe ohun ti gbogbo aye n ṣe ti wọn fi n nilọsiwaju. Ẹ yee kun atike fole kẹ ẹ lo fain, abosi niru iwa bẹẹ, Ọlọrun o fẹ ẹ!

(112)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.