Bi wọn ṣe da Amosun duro ninu APC

Spread the love

Bi igbimọ amuṣeṣe (National Working Committee) lẹgbẹ oṣelu APC ṣe kede lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja pe awọn ti da Gomina Ibikunle Amosun ati Rochas Okorocha, ti ipinlẹ Imo duro ninu ẹgbẹ naa lawọn eeyan ti n reti esi lọdọ awọn gomina yii. Ṣugbọn titi digba ta a pari iroyin yii, Amosun ko sọrọ, bẹẹ ni Okorocha ko wi nnkan kan.

Idahun Gomina Ibikunle Amosun lo tilẹ jẹ awọn eeyan logun ju lapa ilẹ Yoruba nibi, nitori laipẹ yii ni gomina naa jawe olubori ninu ibo sile igbimọ aṣofin agba lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ṣugbọn ayọ naa ko ti i tojọ meloo ti igbimọ apapọ APC fi pepade siluu Abuja, ti wọn si fẹnu ko pe afi dandan kawọn yọ ọwọ Amosun lawo oṣelu ninu ẹgbẹ naa fungba diẹ.

Koda, niṣe lawọn kan ninu ipade naa fẹ ki wọn kuku yọ Amosun ati Okorocha lẹgbẹ patapata. Wọn ni ijiya ‘lọọ rọ ọ kun nile’ yii kere si iwa agabagebe ti wọn hu si ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ.

Ṣe igbimọ NWC yii ti leri tẹlẹ pe awọn yoo fiya jẹ Ibikunle Amosun, nitori bo ṣe wa ninu ẹgbẹ APC, to si kọ lati ṣatilẹyin fun ondije dupo gomina tẹgbẹ naa fa kalẹ nipinlẹ Ogun, iyẹn Ọmọọba Dapọ Abiọdun.

To jẹ Adekunle Akinlade to jẹ ọmọ APM ni Amosun n kampeeni fun lojukoroju, ti gomina yii si tun leri nita gbangba pe oun ko ni i ti Dapọ lẹyin, Akinlade ni yoo gbapo lọwọ oun.

Eyi ko ti i tan nilẹ to tun fi di pe wọn ju ike omi, lailọọnu piọ wọta ati okuta mọ Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn eeyan ẹ lori lọjọ kọkanla, oṣu keji, ti wọn waa polongo ibo l’Abẹokuta.

Ohun tawọn ẹgbẹ naa lapapọ sọ ni pe Amosun lo wa nidii iṣẹlẹ naa. Wọn ni oun lo ran awọn ọmọọta wa lati da oju agbo naa ru, to fi di pe wọn n lẹko mọ odidi aarẹ orilẹ-ede wa.

Ẹsun ti wọn fi kan Rochas Okorocha ti ipinlẹ Imo naa ko se lẹyin pe o n ṣegbe lẹyin ọmọ ẹgbẹ AA, dipo APC, bẹẹ inu ẹgbẹ Onigbaalẹ loun wa, ṣugbọn agabagebe oṣelu wa lara tiẹ naa, o si n ṣoju meji bii ọbẹ.

Koda, a gbọ pe o ṣee ṣe ki Arakunrin Rotimi Akeredolu ti i ṣe gomina ipinlẹ Ondo paapaa kawọ pọnyin rojọ lori iwa ṣiṣe oju meji ninu oṣelu yii.

Wọn ni bo ṣe jẹ pe Atiku lo rọwọ mu l’Ondo, ti wọn kọyin si APC nibẹ ko ṣẹyin iwa Akeredolu rara. Wọn ni ṣeku-ṣẹyẹ ni gomina naa.

Yatọ sawọn yii, awọn meji mi-in ti igbimọ NWC tun da duro ninu ẹgbẹ ni minisita to n ri si ọrọ Niger Delta, Usani Uguru, ati adari agba nileeṣẹ Voice of Nigeria, Osita Okechukwu.

Ileri ti igbimọ NWC ṣe pe awọn yoo fiya jẹ Amosun lẹyin idibo, ni wọn muṣẹ lọjọ Jimọ to kọja yii, ti wọn da gomina yii duro lati ma le ṣe ohunkohun lorukọ ẹgbẹ APC.

Igbeṣe yii dun mọ ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun, kia ni Tunde  Ọladunjoye ti i ṣe akọwe ipolongo wọn si ti gbe atẹjade sita, nibi to ti sọ pe idaduro Amosun yii tilẹ kere, o ni o yẹ ki wọn yọ gomina danu patapata ninu ẹgbẹ ni.

Ọladunjoye sọ pe ki i ṣe asiko yii lo yẹ ki wọn ṣẹṣẹ da Amosun duro, o ni ohun to yẹ ki wọn ti ṣe fun un tipẹ ni pẹlu awọn iwa agabagebe, ati ti alaimoore to ti hu sẹgbẹ to ṣe oore nla fun un.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe niṣe ni ki NWC yọ Gomina Amosun danu lẹgbẹ APC, ko le jẹ ẹkọ fawọn oloṣelu alaimoore bii tiẹ.

Gbogbo eyi lo mu kawọn eeyan maa reti esi latọdọ Gomina Ibikunle Amosun, tabi ko tiẹ fọrọ sawọn amugbalẹgbẹẹ feto iroyin ẹ lẹnu, ṣugbọn ko ti i ṣeni to gbọ ohunkohun latọdọ awọn eeyan naa titi ta a fi pari iroyin yii.

(60)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.