Bi ọmọde ba kọ iyan ana, awọn agba yoo fitan balẹ fun un

Spread the love

Nigba ti mo fẹẹ bẹrẹ ọrọ awọn Fulani ati ọrọ Shehu Uthman Dan Fodio atawọn ọmọlẹyin rẹ, mo sọ kinni kan ti ẹ ko ba gbagbe, iyẹn naa ni pe n ko fẹ wahala awọn ti wọn n sọ ọrọ ẹsin. Ko si ohun to kan mi nidii ọrọ ẹsin, ọrọ itan ni a n sọ. Itan ohun to ṣẹlẹ si wa ati bo ṣe ṣẹlẹ si wa, ati idi ti a fi ni iṣoro ti a ni. Ohun ti mo fẹ ki ẹ mọ ni pe ki i ṣe Fulani lo bẹrẹ ẹsin Islaam, awọn naa gba ẹsin yii gẹgẹ bi Hausa, Yoruba ati ẹya to ku ṣe gba a ni, ẹni kan ko si ju ẹni kan lo nidii ẹsin naa rara. Ede Fulani ki i ṣe ede Larubawa, awọn naa ni ede tiwọn, Fulfude ni. Nitori bẹẹ, ki ẹnikẹni ma gbe Fulani ga ju ẹya tirẹ, tabi ẹya tiwa lọ. Awọn kan n tẹ atẹjiṣẹ si mi, wọn si mura ija lori ọrọ yii, nitori pe a darukọ Dan Fodio. Nibi ti ọpọlọpọ wa ti maa n ṣi laakaye ati imọ lo niyi, nitori a oo fi ohun to yẹ ka gbajumọ silẹ, eyi ti ko to nnkan la oo ma le kiri.

Ohun ti mo n sọ, to da mi loju, to si wa ninu awọn itan gbogbo ni pe, gbogbo ẹni to tẹle Dan Fodio waa jagun ẹsin kọ ni musulumi: awọn ipanle, awọn ẹru, awọn talaka ati awọn Hausa ti wọn ro pe awọn ọba wọn n fiya jẹ awọn lo pọ ju ninu awọn to wa, ṣugbọn awọn Fulani lo pada waa ṣe olori wọn. Awọn Fulani yii ni wọn pada di ọba nilẹ Hausa loni-in, wọn pa gbogbo awọn ọba Hausa ti wọn wa nibẹ pata. Dajudaju, ki i ṣe nitori ẹsin nikan ni wọn ṣe pa wọn, nitori ki wọn ma baa gbajọba pada lọwọ wọn ni. Mo sọ ọ pe ninu ogun naa, awọn mẹta naa lo ṣe pataki julọ: Dan Fodio funra rẹ, ọmọ rẹ Bello, ati Abdullahi, aburo rẹ. Bello lo ṣaaju ogun ti apa ọtun, Abdullahi lo si ṣaaju ogun ti apa osi, aafa lawọn mejeeji naa, wọn nimọ daadaa. Bẹẹ ni wọn si jagun naa ti wọn ṣẹgun.

Nigba ti wọn jagun tan, Dan Fodio pin agbegbe naa fun wọn bi wọn ti jagun rẹ, o fi Bello ṣe olori ọwọ ọtun, iyẹn si fi ibujokoo rẹ si Sokoto, o pe ara rẹ ni Sultan. Bẹẹ lo fi Abdullahi si Gwandu, ti iyẹn si n jẹ Amiir tabi Emir. Ọrọ naa ko dija tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti Dan Fodio ku, ti wọn waa sọ pe Sultan lolori awọn ọba gbogbo, Abdullahi fẹẹ binu, ọdun 1820 ni wọn si yanju ọrọ naa laarin ara wọn. Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹtẹẹta yii ko jẹ ọba ri nibi kan, ti a ko si le pe wọn ni ọmọ ọba, sibẹ, wọn fi imọ kuraani ṣe olori awọn eeyan lọna ti ko ko inira ba wọn. Ṣugbọn a ko le sọ bẹẹ ni awọn ilẹ Hausa to ku, abi meloo ni aafaa, tabi ẹni to mọ kuraani lamọdunju ninu awọn ti wọn ṣe ọba ilẹ Hausa wọnyi. Iyẹn lo ṣe jẹ pe lẹsẹkẹsẹ ti wọn gbajọba tan ni iwa ibajẹ ti tun pada, iwa naa si buru ju ki awọn Dan Fodio too gbajọba lọ.

Awọn ọrọ wọnyi ki i ṣe ahesọ, tabi awawi asan. Ẹni to ba raaye lati ṣewadii rẹ, awọn iwe wa ti yoo ka, ti yoo si ri alaye gbogbo: Awọn iwe bii ‘The Making of Northern Nigeria’ ti Sir Charles Orr kọ, ti Macmillan tẹ jade ni 1911; ‘The Northern Tribes of Nigeria’ ti C. K. Meek kọ, ti wọn tẹ jade ni 1925, ‘History of Yoruba’ ti Samuel Johnson kọ, ti wọn tẹ jade lọdun 1921, ‘The Dual Mandate In Tropical British Africa’ ti Lord Fredrick Lugard kọ ni 1922, ‘Nigeria Under British Rule’ ti William M. Geary kọ, ti wọn tẹ jade ni Britain ni 1927, ‘History of Nigeria’ ti Sir Alan Burns kọ, ti wọn tẹ jade ni 1929, ‘History of West Africa’ ti J. F. Ajayi ati Michael Crowder kọ, ti Longman tẹ jade ni 1974, ‘The Sokoto Caliphate’ ti D.M. Last kọ, ti Longman si tẹ ẹ jade lọdun 1977; ‘The Conquest Of Northern Nigeria’ ti Richard Dusgate kọ, ti wọn tẹ jade ni 1985, ati awọn iwe bẹẹ bẹẹ lọ.

Iṣoro wa ni pe awọn ọmọ isinyii ki i kawe itan, wọn ko le ṣe iwadii lori ohun kan, ahesọ ọrọ ni wọn yoo maa gbe kiri. Bi o si sọ kinni kan fun wọn, kia ni wọn yoo ti da a si agidi, wọn yoo maa ṣe bii ẹni to mọ ju ọ lọ, ṣugbọn sọ pe ki wọn ṣalaye lori ohun ti wọn n sọ yii, wọn yoo ni ẹnu ẹnikan lawọn ti gbọ ọ. Gbogbo awọn iwe wọnyi lo sọrọ lori Fulani ati Jihad Usman Dan Fodio. Ohun ti wọn si fi ẹsẹ rẹ mulẹ ni pe ki i ṣe Islam nikan lawọn ti wọn ba Dan Fodio jagun fi tori ẹ tẹle e, awọn ẹru ti wọn fẹẹ bọ loko ẹru, awọn ti wọn yawo, ti wọn ko fẹẹ san an pada, awọn ọdọ ilu ti ko ri ṣe, ati awọn ti wọn feran ogun pọ ninu awọn ọmọ ogun naa. O da bii ki eeyan maa sọ loni-in yii pe gbogbo ẹni to n lọ si iṣẹ ṣọja ni Naijiria ni wọn n lọ nitori wọn fẹran Naijiria, tabi ki eeyan ni gbogbo awọn to n ṣe ẹgbẹ APC tabi PDP lo n ṣe e nitori pe wọn fẹẹ tun Naijiria ṣe.

Bo ba jẹ nitori ẹsin Islam ni, ki lo de ti awọn Fulani lọọ kọlu wọn ni Borno? Ọba ibẹ, Mai Ahmed, musulumi ododo pọnnbele ni, o si kan ẹsin naa nipa fun awọn eeyan rẹ debii pe keferi ko pọ lọdọ wọn. Ṣugbọn awọn Fulani ti wọn ti n gbe ibẹ dide ogun si i, wọn le e danu lori oye, wọn si fẹẹ fi ipa gba Borno, ki Muhammed El- Kanemi too dide, to si le awọn Fulani ole, ajagun-jẹun, to n fi orukọ ẹsin Islam purọ naa lọ. Itan fidi ẹ mulẹ gan-an pe eeyan daadaa ni Dan Fodio, ṣugbọn awọn to tẹle e nkọ? Gbogbo yin lẹ saa n sọ loni-in pe eeyan daadaa ni Buhari, o daa pupọ, ki i kowo jẹ, ṣugbọn awọn ti wọn n tẹle Buhari yii nkọ, awọn ti wọn n ko owo ilu jẹ, ti wọn n fi ẹlẹyamẹya ba gbogbo ohun to n ṣe jẹ. Tabi bi Naijiria ṣe yẹ ko wa lo wa yii ni. Bi ọrọ awọn Fulani naa ti ri niyẹn.

Ẹnikan naa kọwe si mi to ni wọn ni ọmọ Ọba Sokoto ni Ọba ilu Ilọrin, mo si rẹrin-in, mo digbolulẹ. Bii ti bawo? Ki Jihaad abi Dan Fodio too de rara ni Islam ti wa nibi, Alimi to pada waa fi rikiṣi gbajọba lọwọ Afọnja si ti wa ni Kuwo to n ṣiṣẹ aafa rẹ jẹẹjẹẹ. Ọmọ Yoruba kan toun naa jẹ musulumi, Ṣọlagbẹru, wa ninu awọn ti wọn n tọju rẹ tipẹ nibẹ. Ẹsin yii ti de ilẹ Yoruba daadaa nigba naa. Ni asiko Alaafin Aolẹ ni bii ọdun 1790, iyẹn ni bii ọdun mejila kawọn Dan Fodio too de rara, ọkunrin Hausa kan wa l’Ọyọọ ti wọn n pe ni Alajaeta, o ti pẹ nibẹ. Lọjọ kan lawọn ole kole ẹ, ni wọn ba ji Kuraani ẹ gbe lọ. O lọọ ba Alaafin Aolẹ pe ko jọwọ ba oun wa ẹru oun, o ni boun o ri gbogbo ẹru, boun ba ti ri Kuraani, abuṣe buṣe. Alaafin paṣẹ, wọn si ri gbogbo ẹru, afi Kuraani nikan. Ni Aolẹ ba binu, o ni baba oun yoo wa a foun. Lo ba fi Ṣango wa a, ni Ṣango ba jo ile Baṣọrun, nibẹ ni wọn ti ri Kuraani Alajaeta.

Nitori iṣẹ tira ni Afọnja ṣe ranṣẹ si Alimi, oun n wa agbara kun agbara nitori ogun tijọba ilẹ Yoruba gbe ti i lẹyin to ti dalẹ Alaafin ni. Ohun to ṣe ranṣẹ pe Alimi niyẹn. Lo ba fun un ni ibi ti yoo maa gbe, igba ti Alimi de lo bẹrẹ si i ko awọn Hausa to ti n ṣe iṣẹ ẹru, awọn ti wọn n ṣe iwọfa, ati awọn alagbaṣe, pẹlu awọn Fulani to n daran jọ, ti wọn si fi ọdọ rẹ ṣe ibudo. Awọn ni wọn pada waa di ọmọ ogun Alimi, ti wọn si jagun pa Afọnja to ranṣẹ pe wọn. Nibo waa ni Alimi ti jẹ ọmọ Ọba Sokoto. Koda, Sokoto funra ẹ ko ti i fẹsẹ mulẹ ni gbogbo asiko ti a n wi yii, ẹ ma jẹ kawọn eeyan fi itan ti ko lẹsẹ nilẹ nibi kan tu yin jẹ o. Kinni kan tun wa ti ẹ ko mọ, iyawo Alimi to jẹ Fulani ko tete bimọ, ni wọn ba sọ fun un ko ṣe saraa nla, ko fi ọmọbinrin kan tọrẹ fun aafaa Ọlọrun to ba mọ. Iyawo loun ko mọ aafaa mi-in ju ọkọ oun lọ, n lo ba fi ọkan ninu awọn ọmọ Yoruba to n ba a ṣiṣẹ ta a lọrẹ.

Eyi ni pe Yoruba ni Iya Abdusalami to kọkọ jẹ Emir ilu Ilọrin. Ẹni to ba sọ pe irọ ni, ko juwe ile iya ọba naa fun wa ni Sokoto abi Gwandu, abi ko sọ apa ile awọn Alimi funra rẹ fun wa. Ọpọ ọba Yoruba lo ṣa ni adugbo tiwọn ni Ile-Ifẹ, bi ọrọ ṣe ri niyẹn.

Ṣugbọn ki i ṣe ohun ti a fẹẹ sọ niyẹn. Ohun ti a n wi ni pe ni ibẹrẹ pẹpẹ, Hausa wa, Yoruba wa, Ibo wa, ki awọn Fulani too de. Igba ti awọn Fulani de ni wahala bẹrẹ, ohun to si fa wahala naa ko ju pe awọn eeyan naa ko ni orirun kan pato, ati iwa buruku to wa lọwọ wọn, iyẹn iwa ka fi tipatipa gba nnkan oni-nnkan, ka si pa tọhun nitori rẹ, ka si sọ kinni naa di tiwa titi aye. Dajudaju, ko sẹni ti yoo sọ pe iru nnkan bẹẹ yẹn wa ninu Kuraani, iwa awọn Fulani funra wọn ni.

Mo kan ya sibi lọsẹ yii ni, nitori awọn atẹjiṣẹ ti mo gba, a oo maa ba itan naa bọ lọsẹ to n bọ.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.