Bi nnkan ti n lọ l’Ekiti bayii

Spread the love

O daju pe awọn ọmọ ati ara Ekiti ti n ri iran oriṣiiriṣii wo bayii, awọn oloṣelu ti gba gbogbo ilu ati agbegbe kan, kaluku lo si n ṣe ki iyọ dun tirẹ, kaluku lo fẹ ki wọn dibo fun ẹgbẹ oun. Ko si ibi ti ija naa ti dun ju aarin Fayoṣe ati Fayẹmi lọ, Ifa lorukọ awọn mejeeji, ẹni ti Ifa yoo waa gbe ninu wọn lẹnikan ko ti i mọ. Ṣugbọn ikilọ wa fun wọn, ki wọn ma ko ọkan awọn eeyan Ekiti soke, ki wọn ma le awọn araalu lere, ki wọn ṣe eto ipolongo ibo wọn bii ti awọn ọlaju, ki wọn ma huwa bii ara-oko. Awọn ti wọn lọọ ya posita Kọlapọ Oluṣọla ti yoo du ipo gomina lorukọ ẹgbẹ PDP ko ṣe daadaa rara. Ko si ẹni meji ti yoo ṣe iru ere naa ju ọmọ ti wọn jẹ ti APC lọ. Eeyan ko si le ba wọn wi o, awọn PDP naa ti ya posita APC, ti wọn n fi ọbẹ ati bileedi rẹ oju Fayẹmi ninu posita rẹ to lẹ kaakiri. Awọn ti ṣe tiwọn ki awọn APC too ṣe tiwọn naa fun wọn pada. Ṣugbọn ko yẹ ki o le to iyẹn, bo ba jẹ ire Ekiti lawọn oloṣelu yii n wa, to jẹ wọn fẹẹ waa ṣe daadaa fara ilu ni, ko yẹ ko le to bẹẹ rara. Ki ẹgbẹ ọtun polongo, ki wọn sọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe fun araalu, ati bi ara yoo ti dẹ araalu to lasiko tiwọn. Ki ẹgbẹ osi naa jade, ko ṣe ipolongo tirẹ, koun naa sọ daadaa to ni fawọn eeyan, ati ohun rere ti ki wọn maa reti bi awọn ba gbajọba. Iyẹn lawọn araalu yoo fi wo wọn, Ọlọrun si kuku ṣe e, awọn mejeeji ti wọn ṣaaju eto yii ni wọn ti ṣe gomina ri, awọn eeyan si gbọdọ mọ ẹni to ṣe daadaa ninu wọn. Ohun kan naa kọ ni yoo wu wa, bi awọn kan ti n fẹ ti APC lawọn kan yoo fẹ ti PDP, ṣugbọn kinni kan wa to so gbogbo eeyan ibẹ pọ, iyẹn naa ni pe ọmọ Ekiti ni gbogbo wọn, wọn ko si gbọdọ ba ilu jẹ nitori ibo lasan, ki kaluku fẹsọ ṣe ni. Kawọn araalu naa ṣọra o, ki kaluku kilọ fọmọ rẹ, ko ma jẹ ki wọn fi ọmọ oun ṣe tọọgi, nitori gbogbo awọn ọmọ awọn eeyan yii ni wọn wa niluu oyinbo ti wọn n kawe, awọn mi-in si ti ṣoriire ni tiwọn. Ẹni to ba waa n wo ọmọ rẹ to n yọ ada to n yọ ibọn, to n ṣe tọọgi lẹyin oloṣelu, ko gbọdọ pariwo bi iru ọmọ bẹẹ ba ku lojiji soju ija, ohun to jẹ lo yo o. Ẹ ma ba Ekiti jẹ nitori ibo o, nitori ibo rẹpẹtẹ lo ṣi n bọ ti a oo di l’Ekiti, ka ma fi ẹyọ kan yii sọ ilu dahoro.

(69)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.