Bi ilẹ ba n gbe oṣika, ti ko gbe oloootọ . . .

Spread the love

Nigba ti ilẹ ba n gbe oṣika, ti ko ba gbe oloootọ, bo ba pẹ titi, oore a maa su ni i ṣe. Ko si ki oore ma su ni ni ṣiṣe, abi nigba ti eeyan ba ṣe oore, to ṣiṣẹ rere titi, ti ko ri ere nibẹ, to waa jẹ awọn ti wọn n ṣebajẹ, awọn ti wọn n ṣe aidaa, awọn ni wọn jokoo sibi kan ti wọn n ko ere ẹni to n ṣe rere. O maa n dun-un-yan, yoo dun-un-yan wọnu egungun. Idi naa ni pe kinni naa lodi si ofin iṣẹda-aye, o lodi si ofin ati ilana Ọlọrun. Bi Ọlọrun ti da aye ni pe o sọ pe ki gbogbo ẹda maa ṣe daadaa, ẹda to ba ṣe daadaa, yoo ri ẹsan daadaa gba, nitori eyi ni Ọlọrun ṣe lodi si gbogbo afibi-san-oore. Bi ẹnikan ba ṣe daadaa, ti wọn da daadaa pada foun naa tabi fun ọmọ rẹ, tabi idile rẹ, tabi ki ẹni ti wọn ṣe daadaa fun naa tilẹ ṣe daadaa tirẹ siwaju fun ẹni ti ko mọ rara, daadaa yoo maa gbilẹ si i ni, aye yoo si dara fun gbogbo eeyan, yoo dun lati gbe.

Ọrọ ‘June 12’ ati oore ojiji ti awọn Buhari ṣe fun Abiọla, tabi ti wọn n purọ tan ara wọn pe awọn ṣe fun Yoruba ni mo ro debẹ. Ohun yoowu ti ipilẹ rẹ ba jẹ aburu, ti a wa n gbiyanju lati fi alupayida oore kan bo o mọlẹ, nitori pe ipilẹ rẹ ti jẹ aburu, aburu loun naa yoo maa jẹ. Nigba ti eeyan ba gbin werepe, nigba ti yoo ba hu jade, ewe dudu to tutu ni yoo mu wa, amọ nigba to ba dagba tan, yoo mu iwa werepe jade. Bi ọrọ aye naa ti ri niyi, ẹnikan ki i gbin alubọsa ko ni ẹfọ loun yoo fẹ, ohun ti a ba gbin la a ka. Ko si oore ti awọn eeyan yii le ṣe fun Abiọla tabi fun Yoruba ju ki wọn ti gbe ijọba rẹ fun un nigba to wọle ibo ta a di lọ. Ohun ti iba mu alaafia wa niyi, ohun ti iba mu idagbasoke ba Naijiria niyi, ti afẹfẹ oriire naa yoo si kan ilẹ Yoruba lara. Eeyan wọle ibo wọn ko gba fun un lati ṣejọba, o waa di ẹyin ọdun mẹrindinlọgbọn, wọn ni wọn fi orukọ rẹ sọ papa-iṣere, bi kinni naa iba ṣe dara to, o ku sibi kan.

Meloo meloo lawọn ti wọn ku ikuugbona nidii ọrọ yii, meloo meloo lawọn ti aye wọn bajẹ pata ti ko latunṣe lori ọrọ ‘June 12’, meloo meloo lawọn ti wọn wa laye bii oku, to jẹ ọrọ ‘June 12’ yii lo sọ wọn da bi wọn ti da. Ṣugbọn gbogbo eleyii ko ni i dun ni, bo ba ṣe pe ijọba apapọ laye Buhari yii ranti awọn eeyan yii ninu ayẹyẹ ti wọn ni wọn ṣe. Bi mo ba sọrọ, wọn yoo ni mo koriira awọn kan, n ko fẹran Bọla, n ko fẹran Bisi, kin ni wọn gba lọwọ mi. N ko le fẹran wọn nitori pe elete ni wọn, detedete ni wọn, ete aburu si pọ lọwọ wọn. Emi, ati awọn mi-in ti wọn mọ ọpọ itan ilẹ yii, ko le fẹ tiwọn nitori aburu ni ipilẹ ọpọlọpọ awọn ohun ti wọn n ṣe. Bi wọn ba ṣe aburu tan, wọn yoo fi ariwo, ati awọn iwa abosi mi-in bo o mọlẹ, awọn ti wọn ko ba si mọ, wọn yoo ro pe daadaa ni wọn n ṣe.

Loju awọn ọmọde oni, nigba ti wọn ri Bọla tepọn niwaju awọn Buhari, loju wọn, awọn ti ri ongbeja dẹmokiresi, ati awọn ti wọn wa fun ‘June 12’. Ṣugbọn loootọ loootọ ni mo wi fun yin, bi wọn ba n sọrọ awọn ti wọn ja fun ‘June 12’ ati awọn to yẹ ko to siwaju lọjọ ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ yoowu to ba ba ti asiko ‘June 12’ naa mu, ki i ṣe awọn ti ẹ ri niwaju yẹn lo gbọdọ wa nibẹ, wọn jinna si i gan-an ni. Loootọ ni Bọla wa niluu oyinbo lasiko wahala naa, ṣugbọn ki i ṣe ọrọ ‘June 12’ lo le e lọ, ija laarin oun ati Abacha lo le e kuro niluu. Ọrọ ọjọ mi-in niyẹn. Ati pe Amẹrika loun n gbe tẹlẹ, bii igba to sa pada lọ sile to ti wa ni. Kin ni ka ti waa sọ ti awọn ti ko leeyan l’Amẹrika, ti wọn ko gbebẹ ri, ti wọn si sa lọ nitori ọrọ yii, nigba ti iku n le wọn. Wọle Ṣoyinka, Bọlaji Akinyẹmi, Corlenius Adebayọ, Alani Akinrinade ati awọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ.

Bisi wa ni Naijiria, ṣugbọn n ko mọ iru iṣẹ to ṣe gan-an ti yoo fi wa niwaju nibikibi ti wọn ti n sọrọ ‘June 12’. Ko si awọn ọmọ tabi awọn eeyan Abraham Adesanya, Adekunle Ajasin, Ṣolankẹ Ọnasanya, Bọla Ige, Ganiyu Dawodu, Fredrick Faseun, Bẹẹkọ Ransome Kuti, Olu Ọnagoruwa, Adeniji Adele nibẹ, ati awọn ti wọn wa laye bii Ayọ Adebanjọ, Kofo Akerele Bucknor, Frank Kokori, Ayọ Ọpadokun, Godwin Kanu, Ezeife, Iṣọla Williams, Umar Dangiwa, Gani Adams pẹlu ọpọ eeyan ti wọn ja ija ‘June 12’ yii lati ibẹrẹ titi dopin. Awọn wọnyi ni wọn duro lai sa lọ sibi kan, ti wọn si foju wina ogun Abacha, yatọ si awọn ti wọn jokoo sibi kan ti wọn n fi orukọ Abiọla jẹun lasan. Njẹ ẹnikẹni ranti lọọya ti wọn n pe n Alao Aka-Baṣọrun, ṣebi ọrọ yii naa lo fa aisan lile fun un to si pada ja siku ẹ. Meloo leeyan tilẹ fẹẹ ka.

Bi ko ba si orukọ awọn wọnyi ninu awọn ti wọn pe sibi ayẹyẹ ‘June 12’, awọn wo waa ni wọn pe ti wọn jokoo siwaju yii, kin ni nnkan pataki ti wọn ṣe ninu ija yii jare? Iyẹn ni mo ṣe sọ pe bi ilẹ ba n gbe oṣika, ti ko ba gbe oloootọ, oore yoo su awọn ti wọn ba n ṣe e. Mo ranti daadaa pe ko sẹni to fẹẹ ri Ṣẹgun (Ọṣọba) nile Abiọla lọjọ ti wọn gbe oku ẹ wale, o wa ninu awọn ti wọn pariwo le pe awọn ko fẹẹ ri, nitori awọn irin to rin nigba ti ogun naa n lọ lọwọ. Ṣugbọn loni-in yii, awọn ni wọn jokoo siwaju, wọn ni wọn n ranti Abiọla. Ọrọ ti mo n sọ yii yoo da bii ọrọ aṣiwere loju awọn mi-in ni, wọn yoo ni baba were yii tun de. Ṣugbọn Ọlọrun mọ pe bo ṣe ri ni mo ṣe n sọ ọ yii. Awọn ti wọn jokoo siwaju nibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ fun Abiọla yii, paapaa lati ilẹ Yoruba wa nibi, mọ lọkan ara wọn pe ijokoo bẹẹ ko tọ si awọn. Wọn mọ daadaa!

Loju tiwọn, wọn yoo ro pe awọn lawọn gbọn ju, awọn lawọn mọ ọgbọn ayinike ati ayinipada, awọn lawọn mọ ọgbọn oṣelu julọ. Ṣugbọn ajẹgbe kan ko si ninu adiyẹ irana, bi wọn ti jẹ ti lagbaja naa ni wọn yoo jẹ ti tamẹdun. Ki gbogbo ẹni to si n ṣe oore ma tori ibajẹ awọn oṣika ati ere ojiji ti wọn n jẹ ba ọkan jẹ, ki wọn ma si tori ẹ ṣiwọ oore. Idi ni pe aarọ ati ọsan aye ẹni ko jẹ nnkan kan, igbẹyin lo ju. Mo mọ pe nibikibi ti Ẹgbọn Ṣẹgun ba wa, yoo maa dun un pe oun ko ṣe apọnle kan fun Abiọla, oun jẹ ki ija adugbo ati ija ọmọ ile-sile di oun loju lati ṣe ohun to yẹ. Titi aye ni yoo maa gbe ọgbẹ naa kiri lọkan ara rẹ, ko si si ohun ti ẹnikẹni le ṣe siyẹn, nitori oun naa mọ pe iru agbara ti oun ni ni Naijiria fun ọdun mẹjọ, oun ko tun le ni iru rẹ mọ, o tun di aye atunwa. Bẹẹ naa ni yoo ri fun awọn aferu-gbabukun, awọn ajegun-mọyan, awọn ti wọn n jẹ nibi ti wọn ko ti ṣe.

Bẹẹ ni mo ti sọ fun yin pe oore ti Fulani ba ṣe fun ni ko too pọn. Mo ti wi fun yin tipẹ, eleyii ki i ṣe oore, igbaniloju ni wọn n pe e. Wọn rẹ wa jẹ tan wọn fi han wa, wọn si n beere pe ki la fẹẹ ṣẹ. Eeyan ṣiṣẹ ṣiṣẹ lati wa ounjẹ aladun funra rẹ, o gbe ounjẹ naa kalẹ tan, o ku ko maa jẹ ẹ, ẹ sare gbe awo ounjẹ kuro niwaju rẹ, o pariwo pe ohun ti ẹ ṣe yii ko daa, ẹ gba a loju, ẹ gba a lẹnu, ẹ ti i sinu tubu, o ku si yin lọwọ nibẹ, nigba ti eegun rẹ waa ti jẹra ninu saree tan, ẹ ni ẹ ranti pe oun lo sebẹ nigba kan. Ṣe iyẹn ji Abiọla dide ni, abi o tun gbogbo ohun to bajẹ ṣe, abi o mu apọnle kan ba Yoruba!. Ẹtan lasan ni. Awọn ti Fulani n lo si mọ bẹẹ, ṣugbọn ko si ohun ti wọn ko le ṣe lati ta Yoruba fun wọn. Mo ti sọ fun yin pe ko si ohun ti Fulani ko le fi tọrẹ, ṣugbọn Fulani ki i fi ipo agbara oṣelu silẹ, ẹni ti wọn ba da lọla bayii, ẹni ti wọn mọ pe o ti ku ko le ṣe ohunkohun fun wọn ni.

Awọn ti ẹ n ri lẹyin wọn yii ti sọ ile nu, bẹẹ ọmọ to ba si sọ ile nu ti so apo iya kọ, nigba ti tiwọn yoo ba ṣẹlẹ si wọn, yoo buru jai ju ti Abiọla lọ. Ẹ jẹ ki wọn maa jẹ ki wọn maa mu ninu ibajẹ o, ẹyin ṣoore-ṣoore ẹ ma bọkan jẹ o, ẹyin  ẹ maa ṣe oore ati iṣẹ rere tiyin lọ. Lọjọ kan, Ifa yoo yan ẹbọ, ọpẹlẹ yoo gba ẹran, iyawo yoo lọ ata, ṣugbọn ko ni i jẹ nibẹ. Oju gbogbo wa yii naa ni yoo ṣe.

 

(66)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.