Bi ibo ọdun 1964 ti n bọ lọna, bẹẹ lọrọ Sẹnsọ tun da wahala silẹ laarin Sardauna, Akintọla pẹlu Ọkpara

Spread the love

Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 1964, ijọba Tafawa Balewa kede orukọ awọn eeyan ti wọn yoo ṣeto idibo to n bọ lọna ni Naijiria nigba naa. Ẹni to jẹ alaga ileeṣẹ eleto-idibo ko too di igba naa ni Oloye Kofo Abayọmi, ṣugbọn oun ti kọwe fi ipo naa silẹ, o ni oun ni awọn kinni kan ti oun fẹẹ ṣe, ati pe to ba ti di ọgbọnjọ, oṣu kẹrin naa, oun ko ni i wa sibi iṣẹ naa mọ. Eyi lo mu ki ijọba tete kede orukọ awọn eeyan tuntun ti wọn yoo di ipinlẹ kọọkan mu, ki eto idibo to n bọ nigba naa ma ṣe ni wahala kankan. Awọn marun-un ni wọn yan lẹẹkan, nigba to jẹ ijọba agbegbe maraarun-un to wa ni Naijiria nigba naa ni wọn ti fẹẹ ṣeto idibo yii. Wọn yan alaga ileeṣẹ yii fun ijọba apapọ, wọn si yan awọn mẹrin mi-in ti wọn yoo ṣe alaga ni Eastern Region, Mid-Western Region, Northern Region ati Western Region.

Orukọ ẹni ti wọn yan ti yoo ṣe alaga eto idibo yii pata ni Ọgbẹni Eyo Eyo Esua, oun gan-an ni olori ajọ aṣeto ibo. Tiṣa loun, oun si ni olori ileewe Baptist Academy, l’Ekoo, nigba naa, ati pe lasiko ti wọn ni ko waa ṣe alaga yii, oun ni akọwe-agba fun ẹgbẹ awọn tiṣa gbogbo ni Naijiria, nibi iṣẹ akọwe yii naa ni wọn si ti mu un pe ko waa ṣe olori awọn ti yoo ṣeto ibo to n bọ naa. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Anthony Aniagolu ni wọn mu pe yoo jẹ alaga ati aṣofin fun ipinlẹ Eastern Region, gbogbo aṣẹ ibo ti wọn ba di lati apa ibẹ, ọwọ rẹ ni yoo wa, oun ni yoo si jẹ oludari fun eto gbogbo to ba jẹ mọ ti ibo naa lọdọ wọn. Lọọya ni Aniagolu yii o, ọdun keji to ti n ṣe lọọya niyẹn ki wọn too yan an, nitori lati 1952 lo ti n ṣe agbẹjoro kaakiri ibi gbogbo ni Naijiria, oun si ni alaga ẹgbẹ awọn lọọya ọdọ wọn nilẹ Ibo.

Ọmọọba Ibinni kan, David Akenzua, ni wọn mu pe yoo ṣoju ipinlẹ Mid-West, to si jẹ oun naa ni yoo jẹ bii alaga pata fun wọn nibẹ, abẹ rẹ si ni aṣẹ gbogbo yoo ti maa jade lọdọ wọn. Lọọya ni Akenzua yii naa, ọmọọde lọọya ni, nitori 1961 loun ṣẹṣẹ bẹrẹ si i ṣe agbẹjọro ki wọn too yan an sipo ni 1964. Lati ilẹ Hausa ni wọn ti mu Alhaji Muhammadu Bello wa, oun naa ni yoo si ṣe alaga eto idibo lọdọ wọn lọhun-un, ti yoo si tun jẹ aṣoju Northern Region ninu igbimọ to n ṣeto ibo fun gbogbo Naijiria pata. Ko sẹni to mọ iṣẹ rẹ nigba ti wọn fi mu un yii, bo tilẹ jẹ pe wọn kan n sọ pe tiṣa ileewe alakọọbẹrẹ kan ni. Ni ti ilẹ Yoruba, Ọmọwe Joseph Adegbitẹ lẹni ti wọn mu n jẹ. Joseph Adegbitẹ ti kawe ni Amẹrika ko too pada si Naijiria, olori ileewe Baptist Academy to wa ni Ṣomolu si ni nigba ti wọn fi mu un yii.

Bi wọn ti kede orukọ awọn mẹrẹẹrin yii naa ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ, nitori wọn n sọ pe asiko idibo naa ko pẹ mọ, aaya si ti bẹ silẹ, o bẹ sare niyẹn. Awọn ti wọn yoo ṣeto ibo naa ni ohun ti awọn yoo kọkọ ṣe ni lati lọ si gbogbo ilu kaakiri, ki awọn si wo bi ile idibo ti ri, bo ba ṣe pe awọn ile idibo ti wọn lo nigba ibo to kọja ko dara mọ, ki awọn le mọ pe awọn yoo kọ awọn tuntun si awọn ibi ti tibẹ ko ba ti dara, awọn yoo ba ọba ati awọn ijọye pẹlu awọn araalu sọrọ, lẹyin naa ni awọn yoo le jokoo lati ṣe iṣiro awọn ohun ti awọn fẹ, ati ọjọ ti awọn le fi ibo naa si ti ko fi ni i la wahala tabi ko mu ariyanjiyan kankan lọwọ. Ni ti Ọgbẹni Esua ti i ṣe alaga ajọ ti yoo ṣeto idibo naa, o ni ohun kan ti oun fẹẹ sọ fawọn ọmọ Naijiria ni ki wọn fọkan wọn balẹ, eto ibo ti awọn yoo ṣe ko ni i ni bojuboju kan ninu o, idibo ti yoo han gbangba ni.

Nigba naa ni ọkan awọn oloṣelu ko soke, kaluku si n wo ibi ti ẹgbẹ rẹ ku si, ki wọn le tete ṣe atunṣe, nitori ọrọ ti han si wọn bayii pe ẹni to ba ni ero to pọ ju nile-igimbọ aṣofin ni yoo ṣe olori ijọba apapọ, nibi ijoba apapọ yii si ni agbara gidi wa lati lo fẹnikẹni. Ẹgbẹ NCNC lo kọ bẹrẹ ipalẹmọ tiwọn, wọn ni ohun ti awọn kọkọ fẹẹ ṣe ni lati pari ija to wa laarin awọn, ki awọn le lọ sinu eto idibo naa pẹlu iṣọkan, ti ko ni i si ẹnu meji ninu gbogbo ohun ti awọn ba ṣe. Ija buruku to wa ninu ẹgbẹ naa ni wọn fẹẹ pari, ṣe awọn Akintọla ati Fani-Kayọde ti fọ ẹgbẹ naa si meji, ọpọlọ awọn ti wọn si jẹ gidi ninu ẹgbẹ naa, paapaa nilẹ Yoruba, ni wọn n rọ wọ inu ẹgbẹ Akintọla lọ. Ija wa laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ naa pẹliu TOS Bemson, nitori oun n binu pe ọpọlọpọ anfaani to ba yọ ninu ẹgbẹ yii, awọn ọmọ Ibo ni wọn n jẹ ẹ.

Ija ọrọ naa ko ti i tan, koda, awọn Akintọla ti ni ko maa bọ ninu ẹgbẹ awọn. Nitori bẹẹ ni ẹgbẹ naa ṣe fẹẹ sare pari ija aarin wọn, ki wọn si le dojukọ ibo to n bọ lọna naa. Ẹgbẹ Action Group naa ko duro, bo tilẹ jẹ pe asiko naa ni wọn pari ọrọ ẹwọn olori ẹgbẹ wọn, Ọbafẹmi Awolọwọ, sibẹ, ẹgbẹ naa mọ pe ilu n fẹ tawọn. Ilu si n fẹ tiwọn loootọ o, ṣugbọn iṣoro ibẹ ni pe wọn ko lagbara, nitori awọn kọ ni wọn n ṣejọba, bẹẹ ni wọn ko si lowo ti wọn yoo na, nitori wọn ko si nidii owo ijọba. Ohun to ṣe jẹ pe nigba ti NCNC nawọ ọrẹ si wọn, kia ni wọn gba a, bo tilẹ jẹ pe awọn NCNC yii naa lo ba wọn debi ti wọn de yii. Nibi ti wọn ti n ṣe ipalẹmọ yii ni Akintọla ti ju ọrọ kan lulẹ, ọrọ naa si tun fa wahala gidi laarin awọn aṣaaju oloṣelu wọnyi. Akintọla ni esi sẹnsọ (census) ti wọn ka lọdun 1963 ni wọn yoo fi dibo naa.

Eleyii bi awọn to ku ninu gan-an ni. Idi ni pe wọn ko ti i yanju ọrọ sẹnsọ naa, awọn oloṣelu ilẹ Ibo lawọn ko gba esi naa, Okpara lo si n ṣe olori wọn. Ki lo si de ti oun  fi n binu bẹẹ. O ni sẹnsọ ti wọn ṣe yii, wọn ti fi gba ọpọlọpọ nọmba ti ko tọ si awọn Hausa fun wọn, bi wọn si ṣeto idibo lati ọdun yii titi di ọgọrun-un ọdun, awọn Hausa yii ni yoo maa pọ ju awọn to ku lọ, bẹẹ eru ati ojooro ni wọn ṣe nidii eto ikaniyan, ki i ṣe ohun ti sẹnsọ naa jẹ ni wọn gbe jade. Nigba ti awọn olori ijọba ilẹ Hausa, Ibo ati Yoruba pẹlu Mid-West lọọ ṣepade l’Ekoo, ti Akintọla pada de Ibadan lo sọ pe awọn ti fohun ṣọkan pe sẹnsọ ti awọn ka lọ lọdun 1963 lawọn yoo fi pin ijokoo si ile-igbimọ aṣofin Naijiria lasiko ibo ti wọn fẹẹ di ni 1964 yii, onikaluku yoo le tete mọ iye awọn aṣofin ti yoo wa lati adugbo oun.

Ṣugbọn Okpara pariwo, o ni ọrọ ti Akintọla sọ yẹn ki i ṣe ọrọ daadaa rara. O ni loootọ ni wọn gbe kinni naa wa sibi ipade awọn, ṣugbọn ibẹ naa loun ti tako wọn pe ala ti ko ni i le ṣẹ ni, nitori esi sẹnsọ naa ki i ṣe ohun ti awọn ti i yanju, ipalara ni yoo si jẹ fun adugbo toun bi wọn ba fi sẹnsọ naa ṣeto idibo lati yan awọn aṣofin sile-igbimọ apapọ, nitori aṣofin tiwọn ko ni i to ti awọn to ku, bẹẹ oun ko si mọ idi ti eyi fi gbọdọ ri bẹẹ. Ṣugbọn ko si ohun ti Okpara yii le ṣe, nitori labẹ ofin Naijiria igba naa, gbogbo ọrọ to ba ti jẹ mọ eto ikaniyan bẹẹ, abẹ ijọba apapọ lo wa, Tafawa Balewa lohun gbogbo wa ni ikawọ rẹ, ko si eyi ti Okpara tabi ẹni yoowu le ṣe. Iyẹn ni Akintọla ṣe sọ pe awọn ti yanju ẹ, ko too di pe Okpara waa ja irọ rẹ pe ki i ṣe gbogbo awọn lawọn fara mọ ọrọ naa, oun gẹgẹ bii ẹni kan, oun lodi si i.

Ẹni ti iba tun jẹ ki ọrọ naa lagbara diẹ ni Olori ijọba Mid-West, Denis Osadebey, ṣugbọn wọn ṣẹṣẹ da ijọba adugbo tirẹ silẹ ni, gbogbo ohun to le ri lọwọ ijọba apapọ lo ṣi n le kiri, o mọ pe bi oun ba lodi si Balewa, tabi Sardauna, oun ko ni i ri kinni kan. Nitori ẹ lo ṣe sọ pe aṣẹ ti oun gba lati ọdọ awọn eeyan oun ni pe ki oun tẹle Balewa, gbogbo ibi to ba n lọ ni ki oun maa ba a lọ. Bo si tilẹ jẹ pe eto sẹnsọ naa ko dara rara, Okpara nikan lo n pariwo, oun nikan lo n sọ pe ko daa, ko lẹnikeji, nitori Akintọla ti ni ibi ti Sardauna ba n lọ loun n lọ ninu iwa ati ọrọ ẹnu. Okpara pe Osadebay si kọrọ lati ṣalaye ọrọ fun un ko le ye e, pe nigbẹyin, awọn adugbo rẹ yoo padanu ọpọ nnkan bo ba fi jẹ kawọn eeyan yii lo esi sẹnsọ awuruju ti wọn ka naa, ṣugbọn Sardauna ati Akintọla ti ba a sọrọ, alaye Okpara ko si wọ ọ leti.

Nigba ti ọrọ naa yoo tilẹ fi idi jalẹ, Sardauna funra rẹ jade sita, o ni ọrọ kankan ko si nipa sẹnsọ mọ, awọn ti fagile e, awọn si ti fopin si i, eto ikaniyan ti Naijiria yoo maa lo fun igba pipẹ niyẹn, ko si sohun ti ẹni kan le ṣe si i. O ni bi ọrọ ti ri ni Akintọla wi yẹn, ki kaluku tete gba pe ko si ohun ti ijọba kankan yoo tun ṣe si sẹnsọ naa mọ, koda ko jẹ awọn nikan lo ku ti wọn n ṣejọba naa lọ. Bi Ṣango ba n paṣẹ lọwọ, ooṣa wo ni yoo tun sọ pe oun ko gba, nigba ti Sardauna ti wi bẹẹ, kia ni Balewa naa ti jade, o ni bi ọga oun ti wi lo ri, ijọba toun Tafawa Balewa ti ṣe sẹnsọ, awọn si ti pari rẹ, ẹni ti ko ba dun mọ nikan lo le maa fapa janu, ohun ti oun ṣe ni yoo mu Naijiria duro ṣinṣin. Ṣugbọn ọpọ ọmọ Yoruba lo n binu, paapaa awọn ti ki i ṣe oloṣelu, wọn mọ pe igbẹyin ọrọ naa ko le dara loootọ, yoo si ni Yoruba lara lọjọ iwaju.

Ṣugbọn gbogbo agbara Western Region ko si lọwọ ẹlomiiran mọ, ọwọ ijọba lo wa, olori ijọba si ni Oloye Samuel Ladoke Akintọla, oun yii kan naa si ni olori ẹgbẹ oṣelu rẹ, ẹgbẹ Dẹmọ, ko tun si ẹni to lagbara to o nidii a n ṣejọba, tabi ninu awọn oloṣelu ilẹ Yoruba, ohun to ba ṣe naa lo ṣe. Bo ba jẹ bi Okpara ti n ja lori ọrọ sẹnsọ naa ni Akintọla n ja ni, yoo ṣoro ki Sardauna ti i ṣe aṣaaju oloṣelu ilẹ Hausa ati igbakeji rẹ to jẹ olori Naijiria, Tafawa Balewa, too ri eru naa ṣe gbe, wọn ko ni i ri iye nọmba bẹẹ gba fawọn eeyan wọn, ti wọn yoo fi waa maa tẹnumọ ọn pe Hausa pọ ju gbogbo ilẹ Yoruba ati Ibo lọ. Ṣugbọn ọrọ oṣelu igba naa, ẹni to ba lagbara lo n jẹun ita ni, gbogbo agbojule Akintọla, ọdọ Sardauna lo wa, o mọ pe bi ko ba si Sardauna lẹyin oun, bii igba ti omi gbẹ lẹyin ẹja ni, nitori bẹẹ ni ko si ṣe le tako Sardauna yii ninu ohunkohun.

Yatọ si eyi, ijọba apapọ ti fi kinni kan tan Akintọla jẹ. Lasiko ti wọn fẹẹ da ileeṣẹ ti yoo maa ṣe irin silẹ ni Naijiria, igba akọkọ ti wọn yoo sọrọ naa niyẹn. Njẹ ibo ni wọn yoo da ileeṣẹ irin naa si, wọn ni laarin ilẹ Hausa ati ilẹ Ibo ni ọrọ naa bọ si, ko si ibi ti wọn yoo da ileeṣẹ irin silẹ si ni ilẹ Yoruba. Bẹẹ lawọn Ibo n fa ọrọ yii, wọn ni ọdọ awọn nikan ni ki wọn gbe e wa, awọn Hausa naa ni awọn ko gba, awọn ni kinni naa tọ si. Wọn fi Akintọla sẹgbẹẹ kan, oun n woye ọrọ naa. Nigbẹyin, wọn ni wọn yoo da ileeṣẹ irin silẹ ni ilẹ Hausa ati ilẹ Ibo, wọn yoo si fun ipinlẹ kọọkan ni aadọta miliọnu owo Pọn-un lati lọọ fi da a silẹ. Owo nla ragbadu ni iru owo bẹẹ yẹn nigba naa, owo to pọ gan-an ni. N lawọn oloṣelu ilẹ Yoruba ti wọn ki i ṣe ọmọlẹyin Akintọla ba bẹrẹ si i binu, wọn si n sọrọ si i pe alailojuti ni.

Wọn ni bo ba ṣe pe o lojuti ni, ṣebi oun naa yoo mọ pe oun ko le ri kinni kan gba lọwọ ijọba awọn Hausa, oun to ni oun n tẹle wọn ṣoo ṣoo kiri, ṣe oju rẹ si ti ja a bayii, ileeṣẹ irin ni wọn ni wọn ko ri ibi ti wọn yoo gbe e si nilẹ Yoruba afi ilẹ Ibo ati ilẹ Hausa yẹn. Akintọla fun wọn lesi akọ, o ni ọrọ naa ko ri bẹẹ. O ni lasiko ti wọn n wadii ibi ti wọn yoo gbe ileeṣẹ irin si, oun kọ loun n ṣejọba, Awolọwọ lo n ṣejọba, Awolọwọ ko si fun ijọba apapọ laaye lati waa wa ibi ti wọn le gbe ileeṣẹ naa si, o ni oun ko le ba Hausa ṣe. Gbogbo awọn eeyan kọ “haa,” wọn ni ki Akintọla sọ igba ti iru rẹ ṣẹlẹ, ti ijọba apapọ waa ba Awolọwọ pe awọn fẹẹ da ileeṣẹ irin silẹ nilẹ Yoruba to ni ki wọn ma ṣe e. Nigba ti ọrọ naa fẹẹ di wahala gidi, Akintọla pada lọọ ba awọn Sardauna, wọn si ni ko lọọ wa ibi kan wa, lo ba ni oun ti ri ibi ti wọn le gbe ileeṣẹ irin si.

O ni oun ti ni ki awọn eeyan oun wa agbegbe naa kan, wọn si ti ri ibi kan ni agbegbe Akoko, nibi to jẹ ileeṣẹ irin ti wọn ba gbe sibẹ yoo maa ṣiṣẹ bii aago lojoojumọ lai sinmi ni, pe irin pọ nibẹ bii kinnla. Eyi lo sọ fawọn Balewa, n lawọn yẹn ba sọ pe awọn yoo fun un ni owo tirẹ naa nigba ti awọn ba ti yanju ti awọn meji ti awọn ti kọkọ fẹnu si, awọn yoo wa ọna lati fun un lowo lati ṣe ileeṣẹ irin ti ilẹ Yoruba naa, koda bi ko jẹ ọdun kan naa pẹlu awọn ti awọn kọkọ fẹẹ ṣe e. Bi Akintọla ti gbọ eleyii lo fi ariwo bọnu, bo si tilẹ jẹ pe ko ti i si iwe tabi ohun kan ti awọn araalu le ri, o kọrin fun wọn pe, “O ti ṣe o, baba ti ṣe o, ohun to n ba wa lẹru baba ti ṣe o!” O ni ileeṣẹ irin n bọ nilẹ Yoruba, ki gbogbo ẹlẹgan tẹnu yẹyẹ bọ apo, ki wọn fi ete oke lu tilẹ, ki wọn sinmi ariwo pipa.

Ohun ti eyi fihan ni pe yatọ si ti ibẹru to wa pe Sardauan ko gbọdọ pada lẹyin oun, ileri ti wọn ti ṣe fun Akintọla lori ọrọ ileeṣẹ irin yii ti tun ka a lọwọ ko lati ṣe ohunkohun. Ohun to n sọ fawọn Yoruba to ba fẹẹ sọrọ ni pe akorede loun, oun ti n gba ire oriṣiiriṣii to wa ni Naijiria waa fun wọn. Bi ẹnikẹni ba si sọ loju rẹ pe ko ma ba Sardauna ṣe mọ, tọhun yoo ri ija rẹ, koda, yoo tun lọọ fi ẹjọ rẹ sun Sardauna funra rẹ, pe ko gbọ ohun ti awọn eeyan yii n sọ fun oun. Bẹẹ lo ṣe jẹ pe oun ko le ba Okpara da si ọrọ sẹnsọ, o ni oun mọ pe Hausa lo pọ ju gbogbo Naijiria lọ. Nigba ti ọrọ naa ka Okpara lara, o kuku tun gba ile-ẹjọ lọ. O ni kawọn adajọ ba oun da ẹjọ pe ki ijọba Balewa ma lo esi sẹnsọ ti wọn ṣe ni 1963 lati fi ṣeto idibo ọdun 1964, nitori sẹnsọ naa ni eru ati ojooro ninu, ipalara ni yoo si pada mu ba Naijiria lapapọ lọjọ iwaju.

Awọn adajọ ko ri ọna ti wọn yoo gba da Balewa lọwọ duro, wọn ni oun lo laṣẹ lori ọrọ sẹnsọ, iye ẹni to ba sọ pe o wa ni Naijiria naa lo wa nibẹ, nitori oun lo ni in, orilẹ-ede rẹ ni. Nigba ti ọrọ si ti da bayii ni awọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo ti tun ara wọn ko jọ, wọn gbaradi yatọ. NCNC ni ibo to n bọ lọna naa, awọn yoo mọ bi awọn yoo ti ṣe e ti awọn yoo fi gbajọba lọwọ awọn Balewa, bẹẹ lawọn AG naa si ni awọn yoo le Akintọla lọ dẹn-un dẹn-un, koda, ẹsẹ rẹ ko ni i balẹ rara. Ṣugbọn ẹrin ni Akintọla n fi wọn rin, o ni oun ti mọ ibi ti oun yoo gba mu wọn, ibi ti oun yoo si ti mu wọn, yoo ju ibi ti okete ba lu panpẹ ọlọdẹ lọ. Wọn ko ni i le bọ rara.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.