Bi eleyii ba di gomina, yoo kan maa paayan lọ ni

Spread the love

Bo ba ṣee ṣe ni, ko yẹ ki ọkunrin kan ti wọn n pe ni Tonye Cole du ipo gomina lorukọ ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Rivers, o yẹ ki ẹgbẹ naa fi ẹlomiiran rọpo rẹ kiakia ni. Bo ba tiẹ jẹ pe orilẹ-ede ti nnkan wa ti n ṣiṣẹ daadaa bii tawọn orilẹ-ede gidi lagbaaye ni, ọkunrin yii ko ni i gboorun ipo naa rara, nitori ko si ko ma ṣe ẹwọn, ẹni to ba si ti ṣẹwọn lẹẹkan ki i dedii iṣẹ ijọba. Ẹgbẹ APC ti mu Cole, o si n ṣe kampeeni kaakiri adugbo wọn. Ṣugbọn nibi to ti n ṣe kampeeni kiri lọjọ Satide yii, kia lawọn mọto rẹ ti pa eeyan meji, oun naa si wa ninu mọto naa, wọn pa awọn obinrin olobinrin ti wọn n rin lọ jẹẹjẹ tiwọn. Ilu kan ti wọn n pe ni Obua ni awọn dẹrẹba Cole ti pa awọn obinrin yii, wọn ni wọn n lọ loju titi nibẹ, lojiji si ni ọlọkada kan jade si wọn. Nibi ti wọn ti n yiwọ pe ki awọn ma kọlu ọlọkada ni mọto naa ti lọọ pa awọn to pa, to si ṣe awọn mi-in leṣe. Ki i ṣe pe mọto ko le ni asidẹnti, bẹẹ ni ki i ṣe pe awọn nnkan aṣiṣe bayii ko le ṣẹlẹ, ṣugbọn eleyii ki ba ti le to bẹẹ bi ko jẹ ere asapajude ti awọn dẹrẹba to to tẹle ara wọn naa n sa pelu Tonye Cole to fẹẹ di gomina. Niṣe ni wọn n wa mọto bii igba ti Cole ti di gomina, ti wọn si n sa ere buruku laarin igboro. Ere ti wọn n sa yii lo jẹ ki wọn lọọ pa awọn ẹni-ẹlẹni. Ọlọpaa ko mu ẹnikankan lori ọrọ yii, eleyii ko si daa. o yẹ ki wọn mu Tonye, ki wọn ti i mọle, ki wọn si ba a ṣẹjọ awọn afimọto paayan, ki dẹrẹba rẹ si fẹwọn jura. Ṣebi oun naa wa ninu mọto, bo ba sọ fun awọn ti wọn gbe e ki wọn ma sare buruku bẹẹ, ko si ohun ti yoo fa iku ojiji fun awọn araalu to n lọ jẹẹjẹ tiwọn rara. Bi eleyii ba di gomina, yoo ma ti paayan ju! Ẹ tete yaa da a jokoo ko ma di gomina o, iru wọn ni i fi ọwọ ọla gba mẹkunnu loju lẹnu.

(42)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.