Bi ẹ ba bu Ọbasanjọ, ẹ jare ẹ daadaa

Spread the love

Ki i ṣe tuntun bayii mọ pe Atiku ati awọn agbaagba ilu kan lọ si ile aarẹ ana, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati lọọ bẹ ẹ, eyi to jẹ tuntun ni ọrọ ti awọn eeyan n sọ lẹyin ipari-ija naa. Bi awọn kan ti n bu Ọbasanjọ, bẹẹ ni awọn kan n ki i, ṣugbọn lori ọrọ yii, awọn ti wọn n bu u ri ọrọ sọ. Bi wọn si ti ri ọrọ sọ ni pe gbogbo ohun ti oun naa ti sọ jade, to fẹnu ara rẹ sọ, eyi to kọ sinu iwe ni wọn n hu jade bayii, ti wọn n ni awọn ọrọ to sọ nipa Atiku ree o, oun lo sọ pe ole ni, oun lo sọ pe onijibiti ni, koda, o sọrọ naa titi debii pe bi oun ba dariji Atiku, Ọlọrun ko ni i dariji oun. Ọrọ awọn oloṣelu, nnkan ni. Ko sẹni to mọ ohun ti Atiku ṣe to bẹẹ to ka Ọbasanjọ lara, boya loootọ lo jale rẹpẹtẹ debii pe ọga rẹ yii ko le dariji i ni o, abi wahala to ṣẹlẹ laarin oun ati ẹ nigba ti Atiku fẹẹ gbajọba lọwọ Ọbasanjọ ni 2003, ti Ọbasanjọ si fẹẹ ṣe ẹẹkeji, abi nigba ti Atiku dẹ Ọbasanjọ sawọn aṣofin lati ri i pe Ọbasanjọ ko ṣe ijọba Naijiria lẹẹkẹta. Ko si ohun to le ka oloṣelu lara laye yii ju ki ẹnikan dide ko fẹẹ gbajọba lọwọ rẹ lọ, tabi ko ma jẹ ko ṣe ijọba nigba to ba fẹẹ ṣe e, nitori ninu iṣejọba ni agbara oloṣelu wa. O ṣee ṣe ko jẹ awọn nnkan wọnyi lo fa gbogbo eebu, gbogbo iṣọrọsọ ati aṣiri-titu ti Ọbasanjọ ṣe fun Atiku. Ọbasanjọ lo kọkọ tu aṣiri tawọn eeyan fi mọ pe Atiku ji owo kan ko, ati pe awọn ileeṣẹ to da silẹ, owo ijọba wa ninu wọn, bo si ti n sọrọ rẹ lo n fi epe le e pe Atiku kọ ni yoo ṣe aarẹ Naijiria loju oun. Ohun to fa eebu fun baba agba yii ree, nitori awọn eeyan ti fọkan si i pe layelaye, Ọbasanjọ ko ni i dariji Atiku, ṣe wọn kuku ti sọ ọ kaakiri pe Ọbasanjọ ko lẹmi-in idariji. Nigba to waa dariji Atiku lojiji bayii, nigba ti ko sẹni to ro o rara, ohun to fa eebu ree. Ẹkọ ti eleyii kọ wa naa ni keeyan ma sọrọ tan, ohun yoowu to ba de, ki eeyan mọ ohun ti yoo sọ silẹ laarin igboro, nitori bi oni ṣe ri ọla ki i ri bẹẹ, ọjọ a si tun maa pa eeyan wọle kan lẹẹmeji. Igba kan ṣa wa ti Ọbasanjọ yii naa n beere fun iranlọwọ Atiku, ti Atiku si ran an lọwọ. Gbogbo bi Ọbasanjọ si ti bu Atiku nigba naa to, ọkunrin naa ko da esi pada, bẹẹ ko ṣee ṣe ki oun naa ma ni awọn aṣiri ijọba kan lọwọ, ko ṣee ṣe ki oun naa ma mọ awọn kinni kan nipa Ọbasanjọ to jẹ bo ba sọ ọ yoo le. O daju pe bi Ọbasanjọ funra rẹ naa ba ka awọn ọrọ to ti sọ sẹyin tẹlẹ pẹlu eyi to ṣẹṣẹ sọ pe oun dariji ọmọọṣẹ oun yii, oun naa yoo mọ pe agbalagba ki i sọrọ tan, nitori ohun to n jo ni lara loni-in, bi ina ẹ ba lọ silẹ, o le pada waa mu itura ba ni o. Amọ ju gbogbo ẹ lọ, ọrẹ tuntun ti Atiku ati Ọbasanjọ bẹrẹ yii, bo ba jẹ eyi ti yoo mu idẹra ba Naijiria ni, ki ọrẹ naa tọjọ, ko maa dagba si i. Ṣugbọn bo ba jẹ ọrẹ wọn tuntun yii yoo mu ipalara ba Naijiria ati awọn eeyan inu rẹ, ajatuka ni ti agbaarin, bi wọn ṣe bẹrẹ ọrẹ naa lojiji ni yoo tun tuka lojiji, lagbara Ọlọrun

(49)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.