Bi Buhari ba sọ bẹẹ, nnkan n bọ niyẹn o

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn gomina ilẹ yii ṣepade lọsẹ to kọja, ọrọ pataki kan to si jade nibẹ ni pe nnkan yoo le koko ju bayii lọ. Aarẹ ni ki kaluku mura silẹ, kekere ni gbogbo ariwo ti awọn eeyan n pa bayii, eto ọrọ-aje ilẹ wa yoo tubọ buru si i laipẹ rara, bi eleyii ba si ti ṣẹlẹ, nnkan yoo tubọ nira fun awọn eeyan, kinni naa ko si ni i yọ ẹni kan ku rara o. Bo ba jẹ ẹlomi-in lo sọ bẹẹ, tabi to ba jẹ awọn oloṣelu PDP lo gbe eleyii jade, gbogbo aye yoo pariwo pe ase nla ni wọn n bẹ, irọ nla ni wọn n pa. Ṣugbọn Buhari funra rẹ lo sọ eleyii o, ọrọ ti eegun ba si sọ, ara ọrun lo sọ ọ. Ohun ti yoo ṣẹlẹ ni Buhari ti sọ yii. Ṣugbọn awọn to ba sọrọ yii gan-an ni iṣoro wa. Eyi ti awọn gomina n ṣe ninu aburu nilẹ yii ko kere, ọbayejẹ ati awọn ọmọ atoko-waa-bale-jẹ lo pọ ninu wọn, awọn ọmọ oju-o-rọla-ri. Bi wọn ba ti de ile ijọba ni wọn yoo gbagbe ibi ti wọn ti n bọ, gbogbo owo to si tọ si araalu ni wọn yoo na tan, ti wọn yoo fi ṣe iranu, ti wọn yoo si ni ẹnikan ko gbọdọ bi awọn nitori wọn ti ro pe ko sẹni to to awọn laye mọ. Oṣelu ni wọn yoo gbaju mọ, bi wọn yoo ṣe lọ lẹẹkeji ni wọn yoo maa ṣe, tabi bi wọn yoo ṣe fi ẹni to ba jẹ ọmọ tiwọn sipo, ko le bo awọn aṣiri owo buruku ti wọn ti ko jẹ. Gbogbo owo to yẹ ki wọn fi ṣe iṣe ilu, to yẹ ki wọn fi ṣeto ọgbin, to yẹ ki wọn fi la titi ati ṣe awọn ohun mi-in ti yoo mu iṣẹ wa fun araalu, gbogbo rẹ ni yoo ba inakunaa ati iranu lọ, wọn yoo ko idaji owo naa jẹ, wọn yoo si fi eyi to ku ṣe iranu pẹlu awọn eeyan wọn. Owo awọn ijọba ibilẹ wa nibẹ, bi wọn ba ti gba owo naa lati Abuja, wọn yoo ha a mọ ọwọ ni, wọn yoo si ni ko si alaga kansu to gbọdọ sọrọ, eyi to ba sọrọ lasan, wọn yoo yọ ọ ni. Awọn yii lo yẹ ki Buhari beere owo lọwọ wọn, ko beere bi wọn ṣe n nawo ti ijọba n fun wọn. Lẹyin naa ni ko dojukọ awọn minisita rẹ, ko si fa awọn to n jẹ owo ilu jade ninu wọn. Gbogbo awọn oloṣelu ati oṣiṣẹ ti owo ilu n ha si lọwọ, ṣugbọn ti wọn n mu kinni naa jẹ nitori pe wọn jẹ eeyan oun Buhari funra ẹ, tabi wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa ni ki aarẹ tu jade ninu ijọba wọn, ko si le wọn danu kuro nidii owo, ki owo awọn araalu le to wọn lọwọ. Nigba ta a fẹẹ dibo fun Buhari, lara ohun to ṣeleri fun gbogbo ọmọ Naijiria ni pe oun yoo pese iṣẹ fun wọn. Ijọba rẹ ko pese iṣẹ o, kaka bẹẹ, wọn ba eto ọrọ aje jẹ debii pe awọn ti wọn niṣẹ lọwọ tẹlẹ ko niṣẹ mọ, wọn si n pọ si i lojoojumọ ni. Bi ijọba Buhari ba pese iṣẹ faraalu, iṣẹ ko ni i ṣẹ wọn, nnkan ko si ni i nira fawọn araalu bi oun funra rẹ ti sọ. Ọrọ ijaya lọrọ ti Buhari sọ yii, ṣugbọn kin ni Buhari ati ijọba rẹ ti ṣe, ọna wo lawọn naa ti gba lati mu idẹra ba araalu, kin ni wọn yoo ṣe ti nnkan yoo fi rọgbọ fun wa. Ohun ti Buhari gbọdọ ronu nipa ẹ ree o, ko si tete mu nnkan ṣe kiakia. Iya to n jẹ awọn ọmọ Naijiria bayii ti pọ ju, nnkan ko tun gbọdọ le koko fun wa ju bayii lọ, afi ti Buhari funra ẹ ba fẹẹ maa ṣa oku awọn eeyan ni titi o, iyẹn awọn ti ebi ba lu pa. Ọlọrun ma jẹ ka ri i.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.