Bi Ambọde ba bọ ninu eleyii, odidi ẹran ni yoo fi rubọ

Spread the love

Bi ẹgbẹji ba ṣe ọmọ fun ni, iba leeyan yoo yọ mọ o, nitori ẹgbẹji to ṣe ọmọ fun ni le pada waa gba ọmọ lọwọ ẹni, oore ti Ọlọrun ba ṣe fun ni nikan ni ki i ni iregun ninu. Ipo ti gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde, wa bayii ki i ṣe ipo kan to dara fun ẹni to ti wa nipo ọla nla tẹlẹ. Wọn fẹẹ yọ ọ kuro nipo naa, wọn si fẹẹ gba ijọba lọwọ rẹ ki wọn gbe e fun ẹlomiiran. Ko si si ẹni to wa nidii ọrọ yii ju ẹni to fi i sipo naa lọ, Aṣiwaju Bọla Tinubu. Ọkunrin ti wọn n pe ni Jagaban yii le ni tirẹ lọwọ o, ko jẹ oun naa n wa ọgbọn ti yoo fi maa ko owo Eko gẹgẹ bi awọn kan ti n sọ naa ni, ṣugbọn awọn eeyan ko royin Ambọde funra rẹ daadaa, paapaa awọn ti wọn ṣiṣẹ fun un lati di gomina. Ko si ẹni ti ko mọ awọn ohun to ṣe fun Babatunde Faṣọla to ṣe gomina tẹlẹ ki oun too de, to sọ ọkunrin naa di alejo nile ijọba, bẹẹ ọwọ rẹ lo ti gba kinni naa, o si ti ba a ṣiṣẹ ri. Gbogbo awọn ti wọn ni ọja ti wọn fi n da si idagbasoke Eko lọkunrin naa yẹju wọn, bẹẹ ni ki i ṣe pe o le wọn kuro lọdọ ijọba lati le ba ijọba tọju owo, boya ko sọ pe wọn n na inakunaa tabi pe wọn n ji owo ijọba. Oun n le wọn, o n fi awọn eeyan tirẹ sibẹ ni, nitori ẹ ni awọn olori ẹgbẹ naa ko si ṣe sọrọ rẹ daadaa. Oun lo delẹ yii o. Bo ba jẹ Aṣiwaju wọn nikan lo ṣẹ ni, ṣe awọn ọga ninu ẹgbẹ to ku yoo lọ lati ba a bẹ ẹ, ṣugbọn awọn ọga ẹgbẹ gan-an lo ṣẹ, ko si sẹni ti yoo ba a bẹbẹ laarin wọn. Bẹẹ, bi wọn ba yọ ọ kuro nipo to wa yii lasiko yii, ohun to tumọ si ni pe gbogbo ẹtọ pata to tọ si i gẹgẹ bii gomina to ba fẹyinti lẹyin ọdun mẹjọ ko ni i kan an lọwọ, yoo kan pada si aarin ilu gẹgẹ bii korofo ni, nitori gomina to ba lo ọdun mẹjọ rẹ pe lori oye nikan lofin sọ pe ki wọn maa ṣe ẹtọ fun, oun ko si si ninu wọn niyẹn. Oun naa mọ eleyii, o si jọ pe ohun to ṣe mura si ẹbẹ ti wahala si ba a loju mejeeji niyi. Bi Ọlọrun ba jẹ ko ri ọna ba yọ nibẹ, yoo maa ṣọpẹ ni o, bi ko ba si ri ọna ba yọ, yoo mọ pe iwa oun naa lo koba oun. Eeyan ki i gbagbe ibi to ba ti ba gun oke, bo ti wu ki ibẹ ri jagajaga to, ẹkọ mi-in si tun ni pe bi eeyan ba tori pe oun n ba olori ilu tabi olori ẹgbẹ ṣọrẹ, ko gbọdọ ri awọn ti wọn jẹ isọngbe iru aṣaaju bẹẹ fin, bo ba ri wọn fin tabi to ba ta wọn nu, nijọ ti ija ba de laarin oun ati olori ẹgbẹ rẹ, wọn yoo da a da iṣoro rẹ ni. Bi Ambọde ba le bọ ninu okun ti wọn dẹ silẹ fun un yii, afi ko fodidi ẹran rubọ.

(93)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.