Biṣọọbu Ajakaye si Fayẹmi: Fopin si riran awọn eeyan lọ silẹ mimọ pẹlu owo ijọba

Spread the love

Biṣọọpu ijọ Katoliiki ipinlẹ Ẹkiti, Rẹfurẹndi-agba Felix Ajakaye, ti gba Gomina Kayọde Fayẹmi nimọran lati fopin si riran awọn eeyan lọ silẹ mimọ pẹlu owo ijọba.
Nibi eto idupẹ to waye lọjọ Aiku, Sannde ijẹta, ninu ijọ St Patrick’s Catholic Cathedral Church, to wa niluu Ado-Ekiti, ni alufaa naa ti gba gomina tuntun niyanju. O ni ki Fayẹmi fagile ki awọn kan maa fowo ijọba lọ silẹ mimọ nitori awọn mi-in ti sọ ọ di ọna ijẹ ti wọn fi n gbọ bukaata ara wọn.
Bakan naa lo gba gomina niyanju lati mọ awọn ti yoo yan sipo nitori awọn kan wa ti wọn maa n lagbara ju gomina, awọn lo si n ba ijọba jẹ.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ‘’Ọlala julọ, ẹ yan awọn eeyan gidi sipo ninu ijọba yin. Ẹ ma yan awọn ‘gomina sọ pe, Ẹgbẹyẹmi sọ pe…’ ti wọn maa n forukọ eeyan huwa ika.
‘’Irin-ajo iṣẹ iranṣe keji niyi fun yin, ki i ṣe asiko lati gbẹsan lara ẹnikẹni, nitori Ọlọrun lo ni ẹsan lọwọ.’’
Nigba to n fesi, Fayẹmi ṣeleri lati ṣiṣẹ takuntakun fun idagbasoke ipinlẹ naa, bẹẹ lo bẹ gbogbo eeyan lati foriji ijọba nitori awọn igbesẹ kan wa tawọn le fi ṣẹ wọn, ṣugbọn fun ilọsiwaju Ekiti ni.
Ṣe ṣaaju ni Alhaji Raheem Arikewuyọ Olowoyọ to jẹ Awiye Adinni Ekiti ti gba Fayẹmi nimọran pe ko fi ọrọ Ayọdele Fayoṣe to gbejọba silẹ ṣarikọgbọn, nitori kete ti agbara kuro lọwọ rẹ lo balẹ sọdọ ajọ to n gbogun ti magomago owo, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC).

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.