Beeyan ba ti ri Shittu n’Ibadan, ọrọ gbogbo yoo ye e

Spread the love

Bi ile kan ba jẹ ile daadaa, ti ile naa ni alaafia, to jẹ ile to ni ilọsiwaju ati idagbasoke, bi ẹ ba ti ri awọn ti wọn n jade nibẹ, iwa wọn lẹ o fi mọ pe ile rere ni wọn ti wa, pe ọkan wọn balẹ, wọn si nilọsiwaju. Bo ṣe ri ni ọrọ ile ẹyọ kan yii naa lo ri lọrọ ijọba, bi ẹ ba fẹẹ mọ bi ijọba kan ti ri, awọn eeyan ti wọn wa ninu ijọba naa ni kẹ ẹ wo. Loni-in yii, awọn eeyan n sọrọ Ajimọbi to n ṣe gomina l’Ọyọ lọwọ, wọn n sọ bo ṣe maa n sọrọ kaṣakaṣa sawọn eeyan ati bi ki i ṣee fẹẹ gbọ ti ẹlomiiran mọ tirẹ, awọn orukọ ti ko dara ti wọn sọ ọ niyi lọdọ wọn. Ṣugbọn bi eeyan ba ri Minisita Adebayọ Shittu lọsẹ to kọja nigba ti oun ati ọdọ kan to loun fẹẹ du ipo aarẹ, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, tọhun yoo ti mọ idi ti ijọba Buhari fi ri bo ṣe ri yii, ati idi to ṣe jẹ bi ọkunrin naa ba di gomina ipinlẹ Ọyọ to n le kiri yii, tirẹ yoo buru ju ti Ajimọbi lọ. Igba ti eeyan ba le lọ si ojutaye, to n sọrọ fatafata bẹẹ, to n pariwo mọ ẹni ti wọn jọ n sọrọ lori, ti wọn bi i leere pe kin ni ijọba rẹ fẹẹ ṣe, to da a si agidi, ti wọn ni ko ṣalaye ohun ti ijọba rẹ ti ṣe, to da a sija, to n bu eebu, to n laagun, lori redio, ti awọn eeyan si n fi fidio ka wọn, iru ẹni bẹẹ yoo ni iṣoro lati ṣe olori ijọba. O digba ti awọn ti wọn n ṣejọba ilẹ yii ba le jokoo, ki wọn ronu, ki wọn ṣe ayẹwo awọn ti wọn fẹẹ fi ṣe minisita tabi ṣe gomina finnifinni, ko ma jẹ lagbaja lo fa a kalẹ, tamẹdo lo ni ka fi ṣe e, nigba naa ni awọn ti wọn n ṣejọba yoo too le ṣejọba daadaa. Bi Buhari ba mọ Shittu daadaa, o ṣee ṣe ko ma fi i sipo to fi i si. Ṣebi ki i ṣe oun nikan ni minisita lati ilẹ Yoruba, o ṣe waa jẹ ọrọ tirẹ nikan ni wọn n sọ kiri. Bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn n sọ ọ daadaa naa, odi ni wọn n sọ ọ si; bẹẹ ni ki i ṣe ẹni kan lo n sọ ọ, ọpọ eeyan lo n sọ ọ. Ohun ti Shittu ṣe gbọdọ tun ọrọ ara rẹ yẹ wo niyẹn, iyẹn bo ba jẹ loootọ lo fẹẹ ṣe gomina awọn ara Ọyọ o.

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.