Bẹẹ ni kinni kan tun n rugbo bọ

Spread the love

Nigba ti nnkan kan ba n ru igbo bọ, ti igbo bẹrẹ si i mi lọ, to n mi bọ, tawọn ti wọn wa leti igbo naa ko ba tete mura silẹ ki wọn le mọ ohun to n bọ yii, bi kinni naa ba yọ si wọn lojiji, afaimọ ko ma gbe wọn mi, wọn ko si ni i le sọ pe ẹnikan lo ṣe awọn, wọn yoo mọ lọkan ara wọn pe awọn lawọn fi aimọkan ati iwa aika-nnkan-si pa ara awọn. Iroyin n jade lọtun-un losi bayii pe inu awọn ṣọja Naijiria ti wọn n jagun Boko Haram ko dun rara, nitori awọn iya to n jẹ wọn ati ipakupa ti wọn n pa awọn eeyan wọn. Lẹyin awọn ti wọn pa ni ipakupa ni Metele lọjọsi, awọn ọmọ ogun Boko Haram yii tun kọlu awọn mi-in nitosi ibẹ naa, wọn si pa ṣọja kan, awọn meje farapa bajẹ, bi wọn yoo si ku bi wọn yoo ye, ko ti i si ẹni to le sọ taara. Iroyin to si n lọ ni pe awọn ṣọja naa fẹẹ binu, wọn fẹẹ kọju ibọn si awọn ọga wọn, tabi ki wọn sọ pe awọn ko jagun Boko Haram mọ, ki awọn aṣaaju Naijiria naa ko awọn ọmọ tiwọn ki wọn maa lọọ jagun nibẹ. Bi eleyii ba ṣẹlẹ, wahala gidi ni yoo da silẹ fun ijọba ati gbogbo awọn ti wọn ba wa nidii ijọba. Koda ọrọ naa le le ju bo ṣe wa yii lọ. Ṣugbọn kaka ki awọn ti wọn wa nidii ọrọ tun ọrọ ṣe, ohun ti ọga ṣọja, Buratai, n sọ ni pe awọn kan lo n lo awọn ṣọja yii, awọn oloṣelu lo n da si ọrọ wọn. Ṣe ọrọ gidi lo n ti ẹnu ẹni to jẹ olori ṣọja jade yẹn. Ọrọ gidi niyi abi ọrọ alufansa lasan! Bo ba tiẹ jẹ awọn oloṣelu lo n lo wọn, ṣe ẹnu ọga ṣọja la oo ti gbọ ọ ni. Ki lo de ti oun ko ṣe itọju awọn ọmọ rẹ daadaa, ko fun wọn ni ohun ti wọn fẹẹ ti awọn oloṣelu ko fi ni i lo wọn mọ, ti wọn yoo si mọ pe iṣẹ ṣọja lawọn gba, iṣẹ lati daabo bo ilu ni. Ṣugbọn nigba ti ṣọja to n daabo bo ilu ko jẹun, ti awọn ọmọ awọn to n daabo bo si n jẹun ajẹyo, ti kaluku n ran ọmọ tirẹ lati lọọ kawe loke okun, igba wo lawọn ṣọja yii ko ni i binu. Aarẹ Buhari to si yẹ ko sọrọ naa ko sọrọ, nitori awọn kan ti ko ara wọn jọ ti wọn n tan an, wọn ni awọn fẹran bo ṣe n jagun Boko Haram yii. Ogun ti eeyan n ja ti oku n sun rẹpẹtẹ bayii ni gbogbo igba, ti awọn kan si ko ara wọn jọ ti wọn ni awọn fẹran bi olori ogun naa ṣe n jagun yii, ṣe o ṣẹṣẹ yẹ ki wọn sọ fun Buhari pe awọn ti ọpọlọ wọn ti daru lo n sọ bẹẹ, wọn ko si fẹ rere foun, wọn fẹẹ ti ohun ṣubu lasan ni. Ṣugbọn awọn oloṣelu tiwa ki i ṣe bẹẹ, aburu ni inu wọn maa n dun si, yoo ti ṣẹlẹ ki wọn too maa fi ika abamọ bọnu. Ẹ maa ṣe e lọ o, aafaa to ni iyan yoo mu ni, ọmọ oun naa ko kuku ni i jẹ yeepẹ. Bi ojo ko si rọ, ti agbado ko gbo, oju takọ-tabo ni yoo ja a!

 

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.