Bẹẹ ni Fayẹmi naa gbọdọ bikiafuu

Spread the love

Ohun to maa n baayan ninu jẹ ninu ọrọ awọn oloṣelu ilẹ yii naa niyẹn. Ki i ṣe pe wọn n tori araalu ṣe oṣelu wọn, tori ara wọn, ati awọn ohun to wa ninu wọn ni. Kayọde Fayẹmi ti wọle l’Ekiti bayii, boya wọn fowo ra a ni o, boya wọn ja a gba ni o, ohun to ba wu kaluku ni ko sọ, ṣugbọn ọkunrin naa ti wọle, oun ni yoo si ṣe gomina laipẹ jọjọ. Ṣugbọn lati igba ti wọn ti waa dibo fun ọkunrin naa tan, kaka ko sọrọ alaafia, ọrọ ija loun naa n sọ: bi ko ba ni oun yoo wadii Fayoṣe wo, oun yoo mọ bo ṣe nawo si, yoo ni gbogbo ohun ti wọn ṣe silẹ loun yoo tu palẹ, ati awọn ọrọ bẹẹ bẹẹ lọ. Bi ẹni meji ba ta ayo, ẹni kan naa ni yoo ja mọ lọwọ. Ayo eleyii tilẹ yatọ, ayo oṣelu ni, bo ba jẹ oore Ekiti lawọn ti wọn ba du ipo n wa, ko yẹ ki wọn wọle tan ko tun mu wahala kan dani. Bi eeyan ba si jagun to ba ṣẹgun, ki i fipa taari aboyun ti wọn ko logun, nitori ko mọ ohun ti ọmọ inu aboyun yoo da lọla. Aṣeju ni baba aṣetẹ, agba to ba wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri. Fayẹmi ti wọle ibo, koko pataki to wa nibẹ niyẹn. Bo si ti wọle yii, fila ma-wobẹ ni ko de; ko de fila ipakọ-o-gbọ-ṣuti, olori ẹlẹgan lo bajẹ, ko ma da si ọrọ ti ẹnikẹni ba n sọ. Ohun kan ṣoṣo to yẹ naa ni ko jokoo, ko ko awọn ọmọran jọ, ki wọn wadii iṣoro Ekiti, Ọlọrun si ṣe e, oun naa ti ṣe gomina ibẹ ri, ko wo ọna to dara ti oun yoo gba fi ṣe ijọba tuntun yii, ki inu awọn ara Ekiti le dun si i, ohun to si ṣe ti wọn fi n sọrọ rẹ laidaa tẹlẹ, ko ma ṣe bẹẹ mọ, ki wọn le pada si i sọrọ rẹ ni rere. Ohun to yẹ ki oun mura si ree, ki i ṣe ariwo lati gbẹsan. Bo ba n pariwo ẹsan, to n pariwo ẹsan, bi ẹsan ba de loootọ, ẹsan yoo ke lori oun naa nijọ kan o. Ẹ jẹ ka jọ ba Fayẹmi sọrọ, ko tete mura silẹ, iṣẹ to wa niwaju rẹ yii ju ọrọ ẹsan gbigba lọ.

 

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.