Bẹẹ lepe awọn APC mu wọn ninu PDP girigiri

Spread the love

Bi awọn ẹgbẹ PDP yoo ṣe ṣe aye ara wọn ni ipinlẹ Ogun ti ibo to n bọ yii fi le ja mọ wọn lọwọ ko ye ẹnikan, wọn yoo fidi-rẹmi bii igba ti wọn ja si koto ni, ko si si ẹni ti yoo gba wọn, wọn yoo kan maa kigbe fọ-nọtin ni. Ọtọ lẹni ti wọn ti sọ pe o wọle ibo tẹle, wọn ni ọmọ Baba Ijẹbu, Ladi Adebutu, ti wọn n pe ni Ladoo lawọn mu, wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si wọn l’Abuja. Ṣe gẹgẹ bii orukọ rẹ, Buruji Kaṣamu ti ṣeto ọna ẹburu ti yoo ba yọ si gbogbo wọn. O ku dẹdẹ ki wọn fi ontẹ lu orukọ Adebutu lawọn adajọ yẹgi mọ wọn lọrun, ti wọn ni awọn ọmọ PDP ti Kaṣamu lawọn mọ, awọn naa si ni wọn le fa eeyan kalẹ lati du ipo gomina, ki i ṣe awọn ti wọn mu Adebutu rara. Ẹgbẹ PDP pooyi dẹgidẹgi, wọn ni awọn ma ti yọ Kaṣamu kuro ninu ẹgbẹ, awọn ti le e danu, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn mọ. Ṣugbọn awọn adajọ ko gba, awọn ni kin ni wọn n sọ ti ko dun leti, Buruji Kaṣamu ti wọn ri yẹn, eeyan PDP ni. Titi di bi a ti n wi yii, ko sẹni kan to da orukọ ẹni ti yoo du ipo gomina Ogun lorukọ PDP mọ, kaluku kan n sọ eyi to ba a lẹnu mu ni. O si daju pe bi ki i baa ṣe pe awọn ogun ọrun bẹ silẹ lojiji, rabaraba bayii ni PDP yoo ṣe ti APC yoo fi gba igba oyin lọwọ wọn, ti wọn yoo si gbe igba ata le wọn lọwọ. Amọ ki lo maa n fa ija rẹpẹtẹ bayii ninu awọn ẹgbẹ oṣelu yii? Ko si nnkan kan nibẹ naa ju ilabẹ lọ. Ohun ti kaluku yoo jẹ ni wọn ṣe maa n lakaka lati jẹ olori tabi alagbara ninu ẹgbẹ wọn, oun naa ni wọn ṣe n du ki wọn jẹ gomina tabi ọmọ ile-igbimọ aṣofin. Bẹẹ agbara ti wọn n wa kiri yii, agbara lati le ri owo ilu naa ni, ti wọn yoo maa jẹ ounjẹ ọfẹ, ti wọn yoo maa wa mọto ọfẹ kiri, ti wọn yoo maa na owo ijọba yalayolo, ti wọn yoo ji owo ko titi ti yoo fi yọ nifun wọn. Ija ti wọn maa n ba ara wọn ja yii iba dara bo ba jẹ nitori mẹkunnu ilu yii ni, to ba jẹ nitori ki Naijiria tabi ipinlẹ wọn le daa ni wọn ṣe n bara wọn ja, ti ki i ṣe nitori ti apo ara wọn nikan. Ki kaluku mura si i, bo ba ti jẹ lati fiya jẹ araalu yii ni, eedi yoo maa di wọn, bẹẹ ni ẹfun yoo maa fun wọn, wọn yoo maa ba ara wọn ja ti wọn yoo fi jara wọn sihooho bii awọn ọmọ oloṣo ni. Awọn akiusi gbogbo.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.