Bẹẹ awọn wolii atawọn aafaa ko ni i tẹnu b’epe n’Ibadan bayii

Spread the love

Bi oyinbo ba fẹẹ lọ, yoo maa ṣu saga ni. Ijapa n lọ sile ana rẹ, wọn ni lọjọ wo ni yoo de, o ni o di ọjọ ti oun ba tẹ. Afaimọ ki iru ọrọ bẹẹ ma jẹ sisọ si gomina ipinlẹ Ọyọ, Alaaji Isiaka Abiọla Ajimọbi. Kin ni yoo fa a, awọn owo-ori kan ti ijọba naa fẹẹ maa gba lọwọ awọn eeyan ni. Ṣe ẹ ri i, ko si ohun to buru ninu ka gba owo-ori, dandan lowo-ori fawọn eeyan ti wọn ba n gbe ni ilu kan, bi wọn si ti n ṣe e lorilẹ-ede agbaye kaakiri ree ti nnkan wọn fi n dara. Ijọba ko le ni owo tan, bẹẹ ni wọn gbọdọ maa lowo lọwọ lati fi gbọ bukaata, ijọba ti ko ba lowo yoo tẹ loju araalu gbogbo ni. Ṣugbọn ki i ṣe pe ijọba yoo ji lọjọ kan ni wọn yoo bẹrẹ si i gba owo-ori. Ohun yoowu ti ijọba ba fẹẹ gba owo-ori le lori, wọn yoo ti kọkọ ṣe kinni naa fun awọn araalu. Bo ba jẹ wọn fẹẹ ṣeto ẹkọ-ọfẹ, ti wọn si fẹẹ gba owo-ori lori rẹ ni, wọn yoo ti kọkọ ṣeto naa ti araalu yoo foju ri i pe ohun to dara ni, eyi ni ko ni i jẹ ko nira fun wọn lati sanwo naa. Ẹ fi ọrọ titi ti wọn maa n gba owo too-geeti (toll gate) ṣe apẹẹrẹ ẹ. Ijọba yoo ti ṣe titi naa tan, titi ọhun yoo si dara, yoo wulo, awọn eeyan yoo waa maa gba a, inu wọn yoo si dun lati maa sanwo bi wọn ba ti n gba ibẹ, nitori wọn mọ pe owo ni ijọba na, bẹẹ ni wọn ko ni i fẹ ki titi naa bajẹ ko ma ṣee gba mọ, ohun ti wọn ṣe n sanwo niyẹn. Ṣugbọn orilẹ-ede tiwa yii ni ẹnikan yoo kan deede ji nijọ kan, ti yoo ni nitori oun ni gomina, oun fẹẹ maa gba awọn owo-ori kan, awọn eeyan si gbọdọ san an. Ajimọbi ni awọn yoo maa gba owo eto aabo lọwọ awọn oniṣọọṣi ati awọn onimọṣalaaṣi. Iru eto aabo wo ni ijọba Ajimọbi ṣe fawọn oniṣọọṣi ati onimọṣalaaṣi to yatọ si eyi to n ṣe fawọn araalu o. Ṣe wọn n ko awọn ọlọpaa lọ sibẹ ni, abi Ajimọbi ti ṣeto awọn ẹṣọ kan to n sanwo oṣu fun to jẹ ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi nikan ni wọn n lọ. Bawo leto aabo naa ṣe ri, nibo ni ijọba Ajimọbi si ti n ṣe e. Igba wo ni wọn ti bẹrẹ, anfaani wo si ni araalu ti ri nibẹ. Eleyii ko si, nitori ijọba Ajimọbi ko ti i bẹrẹ eto aabo kankan fẹni kan. Ọda owo lo mu wọn, wọn si n wa gbogbo ọna lati fi gbowo. Ko sibi ti wọn ti n ṣe bẹẹ. Bi owo ba tan lọwọ Ajimọbi, ko kọri si Abuja, nigba ti ko ba le pese iṣẹ tabi ṣeto tawọn araalu yoo fi rowo ti wọn yoo si san-owo ori tuntun fun wọn. Ko lọ si Abuja ko lọọ gbowo lọhun-un, ko ma da kun iṣoro araalu, ko ma di ohun tawọn eeyan naa yoo fi epe sin in jade bo ba ti n lọ.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.