Bẹẹ alabosi ni gbogbo wọn o

Spread the love

Awọn ti wọn n mu ti ẹ n ri nitimọle yii, awọn ti wọn ko ba ṣe ẹgbẹ APC ni o, awọn ti wọn ko ba gba ti Buhari tabi awọn ti wọn ba n sọ ododo. Bi wọn si wi lọ ti wọn wi bọ, ijọba yii yoo ni awọn n gbogun tiwa ibajẹ ni, nitori rẹ ni wọn ṣe n binu awọn. Ṣugbọn wọn ko gbogun tiwa ibajẹ, awọn gan-an tun n da kun iwa ibajẹ ni. Ẹ wo ọrọ ọkunrin kan ti wọn n pe ni Orji Uzor Kalu, gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ. Wọn lọkunrin yii jale, ni EFCC ba mu un, wọn n ba a ṣẹjọ. Ile-ẹjọ gba beeli ẹ, wọn ni wọn yoo bẹrẹ ẹjọ rẹ laipẹ. Nigba ti asiko to lati bẹrẹ ẹjọ, wọn wa Uzor Kalu ti, wọn ko ri i. Ko pẹ ni wọn ni ara rẹ ko ya ni, o ti fẹẹ ku, o wa nileewosan ni Germany. Awọn ọlọpaa wadii, wọn ri i pe irọ ni, ni wọn ba kede orukọ rẹ pe awọn n wa a, wọn ni ẹni to ba ba awọn ri i ko mu un. Amọ ta lo fẹẹ ba wọn ri i. Uzor Kalu duro sẹgbẹẹ Adams Oshiomhole, alaga APC, lọsẹ to kọja yii, nigba ti wọn lọọ ṣe ipolongo ibo wọn nilẹ Ibo, wọn jọ n kiri ni, wọn jọ n lọ, wọn n bọ ni. Ẹni to jale tawọn ọlọpaa ati EFCC lawọn n wa niyẹn. Beeyan ba ti jẹ APC, o ti di eeyan mimọ, to ba si ti n purọ fun Buhari, o ti deeyan gidi. Lọjọ wo la fẹẹ ṣe iru eleyii da. Gbogbo awọn to n ṣebajẹ bayii, Ọlọrun yoo ma mu wọn o. Ko si bi wọn ṣe le ṣe e, Ọlọrun yoo mu wọn, o ku diẹ ni!

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.