Bawọn ajẹrii ṣe n yale kiri lawa naa yoo polongo ibo kiri nipinlẹ Ogun— Adebutu

Spread the love

Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, ondije dupo gomina labala kan lẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun, ti ṣalaye pe ọna tawọn ajẹrii Jehofa n gba yajule kiri polongo ihinrere ni ẹgbẹ PDP naa yoo gba lati polongo ibo to n bọ yii, o lawọn yoo maa yajule kiri ni.

Ọjọ Aiku, Sannde ijẹta yii, lo sọrọ naa l’Abẹokuta, lẹyin ipade pẹlu awọn ẹgbẹ to n polongo ibo fun Atiku, ti wọn si n kede oun naa kiri gẹgẹ bii ẹni to yẹ ko di gomina ipinlẹ yii lọdun ta a wa yii.

Adebutu sọ ọ di mimọ pe ẹgbẹrun lọna aadọta olupolongo ibo ni wọn yoo maa fẹsẹ rin yale onile nipinlẹ Ogun, ti wọn yoo maa ba wọn sọrọ lori idi to fi yẹ ki wọn gbe Atiku Abubakar wole sipo aarẹ, ki wọn si gbe Adebutu sipo gomina.

Nigba to n ṣalaye ohun to fa idi eyi, ọmọ Baba Ijẹbu naa sọ pe awọn ti gbọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti pari eto lati doju eto idibo to n bọ yii ru, ti wọn si ti mura lati ṣe magomago ti wọn yoo fi sọ pe ẹgbẹ wọn lo wọle.

O ni gbogbo ọgbọn tẹgbẹ Onigbalẹ fẹẹ lo lawọn ti ja, ẹgbẹ PDP si ti kọ awọn eeyan ti yoo bojuto ibo bi wọn ba ṣe n di i, ti ko fi ni i si pe wọn ṣe magomago nibi kankan.

Bakan naa ni Adebutu bu ẹnu atẹ lu bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe kọ lati buwọ luwe atunṣe to waye lori eto idibo ilẹ wa. O koro oju si ete ti wọn ni aarẹ n da lati fọjọ kun asiko ti giwaa ọlọpaa, Idris Ibrahim, yoo fẹyinti, ati bawọn INEC paapaa ṣe n huwa bii ẹni to n ṣegbe lẹyin awọn ti ko yẹ.

Sẹnẹtọ yii sọ pe apẹẹrẹ foju han pe ẹgbẹ APC, paapaa nipinlẹ Ogun, fẹẹ mọ-ọn-mọ doju ọrọ ru ni, ṣugbọn PDP ipinlẹ yii ko ni i gba, o lawọn yoo dena gbogbo eru ti wọn ba fẹẹ ṣe ninu ibo naa ni.

Ẹ o ranti pe ile-ẹjọ ko gba abala Ọladipupọ Adebutu wọlẹ nipinlẹ Ogun, eyi to mu ajọ eleto idibo ilẹ wa gbe orukọ Buruji Kashamu sita gẹgẹ bii ondije dupo tootọ ti kootu fọwọ si.

Ṣugbọn pẹlu bi ẹjọ naa ṣe wa ni kootu to, Ladi Adebutu fọwọ sọya pe oun loun yoo di gomina Ogun lọdun yii. O loun yoo gbaṣẹ lọwọ Amosun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii.

 

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.