Bawo ni yoo ṣe ṣe e ni 2019: AWỌN ỌTA BUHARI MA N PỌ SI I NI O

Spread the love

Awọn eeyan ti ro pe Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Ọgagun Ibrahim Babangida nikan ni inu n bi si Aarẹ Muhammadu Buhari, tabi pe awọn nikan ni iṣoro rẹ ti ko ni i jẹ ko wọle si ipo aarẹ lẹẹkan si i lọdun to n bọ, iyẹn ọdun 2019. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ mọ rara, o fẹrẹ jẹ pe ojumọ kan, ọta kan, ni fun baba agbalagba ara Daura naa, ọna ti yoo si gbe e gba lawọn ti wọn n tẹle e ko ti i mọ. Loootọ ni wọn n leri ni gbangba pe ko si ohun to le di Buhari lọwọ, yoo wọle gedegbe lasiko ibo naa ni. Ṣugbọn nnkan to wa nibẹ ni pe ọkan awọn naa ko balẹ, idi si ni pe awọn ọta ti wọn n jade si ọkunrin naa ni gbogbo ọna yii ki i ṣe awọn ti wọn ṣee foju kekere wo, nitori pupọ ninu wọn ki i ṣe awọn ti wọn fẹẹ ba Buhari du ipo naa, pupọ ninu awọn, awọn ti wọn ko ni kinni kan i ṣe pẹlu eto idibo ni, ṣugbọn ti wọn ni ẹnu laarin ilu daadaa.

Bo ba jẹ awọn bii Atiku Abubakar, Rabiu Kwankwanso, Sule Lamido ati awọn kọọkan mi-in ti wọn n leri pe awọn naa fẹẹ du ipo aarẹ, koda titi dori Oloye Bukọla Saraki, ni wọn ba n binu si Buhari. Awọn eeyan yoo ni nitori ti awọn naa fẹẹ du ipo aarẹ yii kan naa ni, ṣugbọn bi ọrọ ba di ti apapọ ẹgbẹ awọn onigbagbọ, iyẹn Christian Association of Nigeria (CAN) to di ti Baba Adeboye, to di ti Bishop Oyedepo ati awọn aṣaaju Musulumi kan pẹlu awọn eeyan ti wọn lero lẹyin rẹpẹtẹ bẹẹ, nnkan yoo le diẹ fun Buhari ko too wọle. Ọrọ ti awọn eeyan wọnyi ba sọ lawọn ọmọlẹyin wọn maa n tẹle, agaga to ba di ọrọ ka dibo bayii, ohun ti iṣoro ṣe wa pupọ fun Buhari lọdun to n bọ yii niyẹn. Bẹẹ yatọ si awọn yii, awọn pupọ ni ilẹ Hausa naa ti n dide, wọn ni ko ni i ṣee ṣe fun un lati tun pada sipo naa, ohun to ba gba lawọn yoo fun un.

Ko ya ki awọn eeyan lati Benue, Plateau, Adamawa, Taraba ati pupọ ninu awọn ara Kaduna foriji Buhari, nitori igbagbọ wọn ni pe oun lo jẹ ki awọn Fulani ti wọn n pa awọn yii maa pa awọn. Gẹgẹ bi gbogbo aye ti n ronu lawọn naa ti n ronu, wọn mọ pe bi Buhari ba fẹẹ le awọn eeyan naa ni adugbo wọn, ọjọ diẹ ni yoo na an lati le wọn danu kiakia. Bẹẹ ki i ṣe akọkọ niyi ti ija ti n ṣẹlẹ laarin awọn eeyan naa, ọjọ pẹ ti wọn ti n ba ara wọn ja, ko si si ohun to n fa ija naa ju pe awọn Fulani ti wọn wa ni awọn adugbo yii fẹẹ sọ ara wọn di olori awọn ara Tiv ati awọn eeyan to ku ni gbogbo ipinlẹ yii lọ. Awọn Kristẹni lo si tun waa pọ ju ninu wọn, ohun ti ọrọ naa ṣe da bii ọrọ ẹsin niyi. Bẹẹ ki i ṣe ọrọ ẹsin, ija laarin awọn ti wọn ba awọn eeyan lori ilẹ wọn, ti wọn si fẹẹ fi agidi gba ilẹ naa ni.

Ni bayii, TY Danjuma ni awọn eeyan naa ri bii olori wọn, lati Benue yii titi de Adamawa, de Taraba ati agbegbe ti wọn n pe ni Southern Kaduna, nibi to jẹ kidaa awọn Kristẹni lo wa nibẹ. Oun paapaa ti di ọta awọn Buhari, nitori o ti sọ fun awọn eeyan naa pe ki wọn dide ki wọn ja, ki wọn gbeja ara wọn, ko ma di pe awọn Fulani yoo pa wọn tan, nigba ti ijọba apapọ to yẹ ko daabo bo wọn ko ṣe kinni kan. Ori ọrọ yii kan naa ni olori ẹgbẹ awọn Kristẹni ti wọn n pe ni CAN fi binu, olori ẹgbẹ naa, Samson Ayọkunle, si sọ pe awọn ko ni i sinmi lati maa ṣe iwọde titi ti Buhari yoo fi le awọn Fulani apaayan yii lọ, tabi titi ti oun funra rẹ yoo fi fi ijọba silẹ. Ọkunrin naa leri pe ko si Kristẹni ti yoo dibo fun Buhari, nitori bii igba ti ijọba rẹ mura lati pa awọn ẹlẹsin naa run kuro ni ilẹ wọn ni, ti awọn Fulani yoo si gbalẹ wọn, bẹẹ wọn kan n fi ẹsin Islaamu boju ni, nitori ẹsin naa ko sọ pe ki wọn maa paayan kiri.

Ohun ti Ẹni-Ọwọ David Oyedepo ti ijọ Winners sọ naa ree, oun n binu gidi si Buhari ni. O ni, ”Mo koriira ijọba yii nitori pe ẹmi eeyan ko jọ wọn loju. Eeyan ko le maa ba iṣẹ Ọlọrun jẹ ki inu mi dun si tọhun, mo koriira ẹni to n ba iṣẹ baba mi jẹ! Ayipada ni wọn sọ pe awọn fẹẹ ṣe fun wa, ṣugbọn ẹnu dun i rofọ, nibi ti ayipada naa ba wa de ree o!” Bayii ni Biṣọọbu Oyedepo wi, ọsẹ to kọja yii si ni Ẹni-Ọwọ Adeboye ti ijọ Ridiimu kin ọrọ rẹ lẹyin. Baba naa sọ pe, “Biṣọọbu kan waa ba mi, o ni oun fẹ ki n sọ ẹni ti yoo wọle bii olori Naijiria lọdun 2019, ṣugbọn mo sọ fun un pe ohun ti Ọlọrun fi han mi ni pe, bi ipaniyan to n lọ kaakiri nilẹ yii ko ba dawọ duro, ko ni i si ibo didi ni Naijiria debii pe ẹnikẹni yoo di aarẹ. Nitori bẹẹ, bi ijọba yii ba fẹẹ dibo, ti wọn si fẹẹ maa ba iṣẹ wọn lọ, afi ki wọn sinmi a-n-paayan

kiri!”

Ko too di igba naa ni Pastor Tunde Bakare ni tirẹ ti n sọ pe ijọba yii ko ṣe rere fun awọn araalu, ijọba inira gbaa ni. Aimoye igba ni Bakare ti gbe awọn iwaasu to le koko jade, ko si si igba kan ti ki i fi ẹhonu han lori bi Buhari ti n ṣe ijọba rẹ, bo tilẹ jẹ pe ọrẹ ati alajọsọ ni wọn.

Bi ọrọ naa ti n lọ lọtun-un losi niyẹn o, o si jọ pe awọn Kristẹni ti fimọ ṣọkan lati kọyin si Buhari. Ṣugbọn awọn ẹlẹsin Islaam kan naa ti dide, awọn ti wọn mu olori wọn ni Kaduna. Sheik Ibarahim El-ZakZaky, Olori ijọ awọn musulumi kan ti wọn n pe ni Shiite ti wa latimọle bayii ti n lọ si bii ọdun meji. Ninu oṣu kejila, ọdun 2015, loun ati awọn ṣọja kan kọju ija sira wọn, ti awọn ṣọja si pa awọn ọmọ ẹyin rẹ, ti wọn pa igbakeji rẹ, ti wọn si mu un timọle. Lori ọrọ naa ni iyawo rẹ ku si o, nigba ti wọn ko si fi i silẹ, awọn ọmọ ẹyin rẹ dide loṣu to kọja yii, wọn si ṣe iwọde to lagbara niluu Abuja. Nigba naa ni wọn bẹrẹ si i pariwo, ti wọn n pe Buhari ni ole, ti wọn n ṣepe, ti wọn si n pe orukọ Ọlọrun pe pẹlu agbara Allah, Buhari ko ni i pada ṣejọba Naijiria lọdun 2019.

Eyi to yaayan lẹnu ju ni ti awọn ẹgbẹ Arewa. Awọn ti wọn jẹ ọdọ ninu ẹgbẹ naa ni wọn kọkọ binu, wọn ni Buhari ko ṣe nnkan kan fawọn, ti awọn naa si n sọ pe awọn yoo pe gbogbo awọn ọmọde ilẹ Hausa ki wọn ma dibo fun un. Lẹyin ti wọn ni awọn agbaagba ẹgbẹ naa paapaa sọrọ, wọn ni bi Buhari ba n ṣejọba rẹ bayii, ko daa, afi ko ṣe atunṣe bo ba fẹ atilẹyin awọn. Ghali Na’abba, olori awọn aṣofin tẹlẹ nilẹ yii lo fọba le e ṣa o, oun ni lati ọjọ ti Naijiria ti n bọ, lati ọjọ ti wọn ti n ṣejọba ibẹ, ko si ijọba kan to bajẹ, to buru, ti ko si leto ilọsiwaju bii ti Buhari yii. O ni ko si oore kan ti ijọba naa n ṣe fun ilu, eeyan ko si le tori pe o jẹ ọmọ agbegbe ilẹ Hausa ki eeyan ni ko maa ṣejọba naa lọ.

Nigba naa ni gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Alaaji Balarabe Musa sọrọ, oun si sọ pe bo ba jẹ lasiko ti a wa yii, bi awọn aṣofin ba le yọ Buhari, ki wọn tete yọ ọ ni iba dara julọ. Bayii ni ọta baba arugbo to n ṣe olori Naijiria yii n pọ si i, eto ti yoo ṣe, ati ọgbọn ti yoo da ki ọdun 2019 too pe, ti awọn eeyan yoo fi wa lẹyin rẹ, oun nikan funra rẹ lo mọ, oun nikan naa ni yoo si mọ bi yoo ti ṣe e. Ṣugbọn bo ba ṣe bi nnkan ti wa yii ni, eto idibo ọdun to n bọ naa yoo le koko fun Baba Buhari!

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.