Bawo ni PDP yoo ṣe ṣe e tọrọ o ni i di gidigbo-gidigbo

Spread the love

Awọn PDP naa lawọn yoo ta fọọmu ẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ ni miliọnu mejila, bo tilẹ jẹ pe eleyii ko pọ ju fun ẹni to ba fẹẹ du ipo naa, sibẹ, owo nla ni. Yatọ si owo yii, ọpọlọpọ owo ni awọn ti wọn fẹẹ du ipo yii ti n na lati ko ero jọ, ati lati je ki wọn wọle lọjọ ti wọn ba dibo abẹle wọn. Ẹni to ba ri ero ti Kwakwanso ko wọ ilu Abuja lọsẹ to kọja yii lọjọ to n kede pe oun fẹẹ du ipo aarẹ yoo mọ pe owo kekere kọ lo n na. Tabi ti Abubakar Atiku to ti n nawo lati ọjọ yii ni, tabi ti Saraki to ṣẹṣẹ de, tabi tawọn bii Dankwabo ati awọn bẹẹ bẹẹ lọ. Iru awọn owo bayii, ko sẹni ti yoo na an ṣere, iyẹn lo ṣe jẹ pe iṣoro wa fun ẹgbẹ naa lati duro papọ mọ lẹyin ti wọn ba dibo abẹle wọn tan. Awọn eeyan nla nla lo fẹẹ du aarẹ lorukọ ẹgbẹ naa, Jona Jang naa ti jade, Makarfi wa nibẹ, Aminu Tambuwal loun lo tọ si, ati awọn to ku bẹẹ bẹẹ. Njẹ awọn yii yoo na iru owo bẹẹ wọn yoo si jokoo jẹẹ bi wọn ko ba wọle. Alaga ẹgbẹ naa, Uche Secondus, ti sọ pe bẹẹ ni, ko sẹni ti yoo ja bi ibo ba kọja ti wọn ko wọle. Ṣugbọn oun naa mọ pe ọrọ oṣelu ko ri bẹẹ, afaimọ ko ma jẹ ohun ti yoo fọ ẹgbẹ naa ka niyi, nitori gbogbo wọn lo fẹẹ du ipo aarẹ. Ṣugbọn ka beere paapaa, ki lo de ti ero pọ bẹẹ ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ ninu ẹgbẹ kan ṣoṣo? Ko sohun meji to fa a, bẹẹ ni ki i ṣe fun ire Naijiria paapaa, kaluku wọn n wa agbara ati owo ni. Ko ju bẹẹ lọ. Afi ki Ọlọrun saanu awa mẹkunnu ilẹ yii o.

 

 

 

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.