Bawo l’Agbaje yoo ti ṣe e l’Ekoo

Spread the love

Jimi Agbaje ni oludije ipo gomina l’Ekoo, oun lo n du ipo naa lorukọ PDP, o si ti nawo nara, bẹẹ lo ṣe wahala gidi lori kinni yii. Amọ kinni kan wa to da bii pe ọkunrin Agbaje funra rẹ ko fọkan si o. Iyẹn naa ni pe oun nikan lo n da kiri, araalu ko gbohun awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn, ko sẹni to sọrọ kan ninu awọn PDP to ti wa tẹlẹ, kaluku da a da kinni ọhun, afi bii ẹni pe oun nikan lo wa ninu ẹgbẹ wọn. Bẹẹ ọrọ Eko yii ki i ṣe nnkan kekere, ọrọ Eko yii ki i ṣe ipinlẹ ti eeyan le ku giiri wa ti yoo sọ pe oun yoo ṣe gomina ibẹ, ologbo to ba fẹẹ pa akere ni, toju-timu rẹ ni yoo wọmi lọ, iṣẹ nla ni fun oloṣelu to ba fẹẹ gbajọba Eko lọwọ APC, lọwọ awọn Tinubu. Ṣugbọn gbogbo igbesẹ ti oun n gbe yii, gbogbo bo ti n rin in yii, to jẹ oun nikan naa lo n lọ to n bọ yii, igba wo ni yoo fi rẹ ija, igba wo ni agbara rẹ yoo fi pin. Ọrọ oṣelu ki i ṣe ohun ti eeyan yoo mu bo ti mu un yii, bi ẹgbẹ PDP si tuka ju bẹẹ lọ l’Ekoo, oun lo yẹ ko wa ọna lati ko ẹgbẹ naa jọ pada, ko sun mọ awọn agba ti wọn ti jọ n ja tẹlẹ, ki wọn le jọ ṣiṣẹ pọ. Ṣebi oun naa ri awọn APC bi wọn ti ṣe e, koda nigba ti ija de lori ẹni ti wọn yoo yan, ti Ambọde ati Sanwo-Olu si kọju ija sira wọn, ko si ohun ti a pada gbọ ju pe wọn ti pari ija naa, Ambọde ti n kiri lorukọ Sanwo-Olu, bẹẹ ni awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ko si fi ara wọn silẹ. Ẹgbẹ to nikan lati ṣe niyẹn, ki i ṣe ẹgbẹ ti wọn ti ba ara wọn ja ija ajaku akata ki ibo too de rara. Ẹni to ba gbe iru iyapa bayii lọ si oju ija, iru wọn ki i mu nnkan kan bọ, wọn yoo na an wọn yoo fẹrẹ pa a ni. Eko yatọ si awọn ipinlẹ to ku, nibi ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo naa ti n ṣejọba lati ogun ọdun, ẹgbẹ oṣelu wo ni yoo waa sare le wọn kuro lori oye naa ti ko ni i ja ija to le, eeyan ko si le ja ija to le bo ba jẹ oun nikan lo n ja ija naa lorukọ ẹgbẹ, afi ki gbogbo awọn ti wọn ba lagbara ninu ẹgbẹ naa jọ ṣa ara wọn jọ. Loootọ ọgọọrọ eeyan ko nigbagbọ ninu Agbaje tabi PDP pe wọn yoo wọle ibo yii, ṣugbọn awọn naa ko waa gbọdọ ja ija naa bii ẹni to ti mọ pe oun ko ni i wọle, nitori bo ba di ọjọ mi-in ti wọn ba tun pada wa, awọn eeyan yoo pariwo ole le wọn lori ni. Ki Jimi Agbaje ba awọn agbaagba ẹgbẹ rẹ ṣe o, nitori ko si igi kan to le dagbo ṣe.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.