Banki Apapọ gbaṣakoso ileefowopamọ Skye, Polaris ni wọn n je bayii

Spread the love

Lati ọjọ Aje, Mọnde, ana, ni ileefowopamọ Skye Bank, kaakiri orileede yii ti yi orukọ wọn pada, Polaris bank ni wọn si n jẹ bayii. Eyi waye latari bi Banki Apapọ ilẹ wa (CBN), ṣe gbaṣakoso banki naa, idi rẹ ni pe wọn ni gbogbo igba ni banki naa n ya owo lati ileefowopamọ apapọ lati le doola ara wọn ninu ọpọ gbese ti wọn jẹ, ti ko si ni gbedeke asiko kan ti wọn fẹẹ san an pada. Pẹlu bi nnkan si ṣe n lọ ni ileefowopamọ ọhun, bi Banki Apapọ ilẹ wa ko ba tete gbe igbesẹ, ọrọ naa yoo buru ju ohun ti wọn ro lọ.

Gomina fun Banki Apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, lo sọ eleyii di mimọ nibi ipade awọn oniroyin kan to waye niluu Eko lọsẹ to kọja. O ṣalaye pe owo to to ẹẹdẹgbẹrin biliọnu (786 B), ni Banki Apapọ naa ti gbe kalẹ fun banki tuntun yii gẹgẹ bi owo-ẹya lati fi le bẹrẹ iṣẹ, ti sisanpada rẹ ko si ni i wọ banki tuntun naa lọrun rara.

O waa fi ọkan awọn to ba ni owo ni asunwọn Banki Skye lọkan balẹ, o ni ko si nnkan kan to maa ṣe owo wọn. O fi kun un pe Ajọ ti n doola okoowo nilẹ yii, iyẹn ‘Asset Management Corporation of Nigeria’ (AMCON), ni yoo maa dari Banki Polaris, pẹlu alaye pe awọn alaṣẹ Banki Skye tẹlẹ naa yoo wa lara awọn igbimọ adari tuntun ileefowopamọ yii. Emefiele ni gbogbo awọn to ba ni asunwọn ni Banki Skye tẹlẹ ni wọn ti di onibaara Banki Polaris, ti awọn oṣiṣẹ banki naa yoo si di oṣiṣẹ banki tuntun yii lẹsẹkẹsẹ.

Lati ọdun 2016, ni Banki Apapọ ti n doola Skye Bank, ko too di pe wọn waa gbaṣakoso rẹ bayii. Ṣa, lati ana, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ileefowopamọ apapọ ilẹ wa ti gbegile gbogbo nnkan to ba jẹ mọ idokoowo-pọ (Shares) pẹlu Banki Skye tẹlẹ, gẹgẹ bi agbekalẹ ofin.

Igbesẹ yii lo mu ki ọpọ awọn onibaara banki naa tẹlẹ maa sare gba owo wọn jade lasunwọn banki yii, nitori wọn ko mọ ohun to le ti idi igbesẹ tuntun ti Banki Apapọ ilẹ wa gbe yii jade. Ṣugbọn awọn alaṣẹ tuntun yii ti fi wọn lọkan balẹ pe ko sewu.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.