Banki agbaye bẹrẹ iṣẹ akanṣe omi onibiliọnu mẹta l’Ekiti

Spread the love

Banki agbaye (World Bank), ti bẹrẹ iṣẹ akanṣe onibiliọnu mẹta ati miliọnu ẹẹdẹgbẹrin (3.7b) Naira, lẹka omi to mọ gaara lati odo Ẹrọ Dam fun ipinlẹ Ekiti bayii.

Lopin ọsẹ to kọja ni Ọmọwe Khairy Al-Jamal ko awọn igbimọ banki agbaye naa waa ri Gomina Kayọde Fayẹmi, nibi ti wọn ti kede pe iṣẹ naa gbọdọ bẹrẹ ni kia lati gbogun ti aini omi to mọ gaara ati kawọn eeyan maa lo awọn odo nilokulo.

Al-Jamal ṣalaye pe ọdun 2014 ti Fayẹmi kuro lori aleefa lo yẹ ki iṣẹ naa bẹrẹ, ṣugbọn ijọba to ṣẹṣẹ lọ ko gbe iṣẹ naa fun kọntirakitọ kankan, ko si si eto lati ran banki agbaye lọwọ ati lati to ọpa omi lati odo Ẹrọ gba Ifaki ati Iworoko lọ si Ado-Ekiti.

O waa sọ pe ko si asiko mọ bayii nitori oṣu kẹfa, ọdun 2020 niṣẹ naa gbọdọ pari.

Nigba to n fesi, Fayẹmi ṣeleri atilẹyin fun eto naa ni gbogbo ọna nitori omi wa lara iṣoro ipinlẹ naa tijọba n gbiyanju lati wa ojutuu si, ati pe o yẹ ki odo Ẹrọ ti maa ṣanfaani fun Ekiti.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.