Balogun-Fulani dagunla si aṣẹ ẹgbẹ APC, o yan awọn oludije ile-igbimọ aṣofin

Spread the love

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Kwara, Ishọla Balogun-Fulani, atawọn ikọ rẹ ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC apapọ paṣẹ pe wọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa ti dagunla si aṣẹ yii pẹlu bi wọn ṣe yan awọn oludije fun ile igbimọ aṣofin agba ati aṣofin ipinlẹ ninu eto idibo ọdun 2019.

Balogun-Fulani ni oniyẹyẹ lawọn to n paṣẹ yii, nitori oun ṣi ni ofin mọ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara. Nitori naa, eto idibo abẹle ti oun atawọn ikọ ti awọn jọ n dari ẹgbẹ ba ṣe lo maa jẹ ojulowo. Idibo yoowu to ba waye yatọ si eyi toun ṣe yii, bii fifi akoko ṣofo ni.

Akọwe ẹgbẹ APC ni igun ti Balogun-Fulani n dari, Ọnarebu  Christopher Tunji Ayẹni, lo kede orukọ awọn oludije to pegede naa ni ile ẹgbẹ APC to wa lọna Onikanga, lagbegbe GRA, niluu Ilọrin.

Ayẹni sọ pe awọn tẹle ilana ti igbimọ to n ṣakoso ẹgbẹ lapapọ la kalẹ lati yan awọn oludije naa.

Ọnarebu Umar Ọlanrewaju Babatunde ni wọn yan lati dupo sẹnẹtọ Aarin-Gbungbun Kwara, Arabinrin Dada Bukọla Elizabeth lo maa ṣoju ẹkun  Ọffa/Ifẹlodun/Ọyun nile igbimọ aṣoju-ṣofin.

Wọn kede Ọnarebu Usman Babalafia lati ṣoju ẹkun Kaima/Baruten, ti AbdulHameed Ali, yoo ṣoju Ilọrin West/Asa.

Awọn oludije ti wọn kede fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni; Lawal Sodiq (Owode Onire), Mohammed Ndakwa (Patigi),  Victor Ọlabọde Rotimi (Ekiti), Musa Buge Alhassan (Gwanara/Ilesha), ati Gabriel Babatunde (Isin).

Awọn mi-in tun ni; Salman Hakeem (Ilọrin North), Ọlarinoye Lasun (Ọjọmu /Balogun),  AbdulKadir Ọlarewaju (Ilọrin South),  Alhaja Mulikat Onagun (Ilọrin West), ati Suleiman Kudirat (Ilọrin East), Victoria Ọdẹdina (Sharẹ/Oke-Ọdẹ) Issa Adaara Jimoh (Ipaye/Malete/Oloru).

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.