Bakare foogun sinu nnkan mimu ọmọ ọdun mẹrinla, lo ba fipa ba a lopọ

Spread the love

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu ọkunrin onigbajamọ kan, Bakare Ismail, ẹni ọdun mejidinlogun, wọn ni ṣe lo fi oogun sinu nnkan mimu ọmọ ọdun mẹrinla, lo ba fipa ba a lopọ.
Bakare ni wọn lo tan ọmọ naa lọ sile awọn obi rẹ ni adugbo Banjọ, Owutu, ni Ikorodu, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu to kọja. Chike Oti ti i ṣe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe afurasi ọdaran naa fun ọmọbinrin yii ni nnkan mimu to ti fi oogun oorun si, lẹyin ti ọmọ naa si mu un tan lai mọ lo sun lọ fọnfọn.
Nigba ti ọmọbinrin yii ji lo ri ẹjẹ lara rẹ, iṣẹlẹ yii lo si fi to ẹni to jẹ alaboojuto rẹ leti. Ẹni naa lo mu ẹjọ lọ si ẹka to n ri si ọrọ lakọ-labo (Gender section), ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikẹja. Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye, wọn ni ọmọ naa sọ pe nigba ti ẹgbọn oun ran oun niṣẹ ni Bakare pe oun pe oun fẹẹ ri oun fọrọ kan, nigba ti oun si wọ ile rẹ lo fun oun ni ọti ẹlẹridodo, oun ko si mọ igba ti oorun gbe oun lọ. Ọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri yii ni ẹjẹ loun ri loju ara oun nigba ti oun ji.
Ṣa, awọn ọlọpaa ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ni afurasi naa ti sọ pe ko si ootọ nimu ẹjọ ti ọmọbinrin naa ro kalẹ.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.