Baba agbalagba fika gbabale ọmọ ọdun mẹfa n’Ileṣa

Spread the love

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni baba ẹni ọdun mejilelọgọrin (82), kan, Ọdẹjide  Kọlawọle, ki ika bọ Aisha, ọmọ ọdun mẹfa, labẹ nile rẹ to wa ni opopona Kayanfada, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa.

Alaroye ri i gbọ pe Aisha ti iya rẹ gbe ọja worobo le lori pe ko kiri lọ ni Kọlawọle tan wọnu ile rẹ pe oun fẹẹ ba a raja, ṣugbọn ọtọ lọrọ to tun pada n ba ọmọ naa sọ nigba ti wọn wọle tan.

Nigba ti ọmọ naa fẹẹ maa sa lọ ni baba yii fi ẹẹdẹgbẹta Naira tan an, eyi to mu ọmọ yii gbara duro fun un to fi n ti ọwọ bọ ọ loju ara. Ko pẹ pupọ ni ẹjẹ jade lara ọmọ naa. Aisha ko le farada inira oju ara rẹ to n ṣẹjẹ yii, lẹsẹkẹsẹ lo sunkun sita titi ti awọn ayalegbe baba naa fi ba a nibi to ti n huwa ma-jẹ-a-gbọ yii.

Ibẹru ki Ọdẹjide ma le wọn jade nile ko jẹ ki awọn ayalegbe naa le lọọ sọrọ rẹ fawọn ọlọpaa, wọn fi ọrọ naa ṣe oku oru. Ṣugbọn iwadii akọroyin wa fidi ẹ mulẹ pe awọn obi Aisha pada gbọ si ọrọ naa, wọn si mura lati fi ọlọpaa mu Ọdẹjide. Ṣugbọn nitori baba agbalagba yii n bẹ wọn pe ki wọn ma jẹ koun farugbo ara ṣẹwọn, ti wọn si lọ si ṣetan lati san ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun itọju ọmọ naa ni awọn obi rẹ ṣe moju kuro ninu iwa palapala to hu sọmọ wọn.

Akọroyin wa gbiyanju lati ba Ọdẹjide sọrọ lori iroyin ti a gbọ yii, ṣugbọn ọkunrin naa ni ọrọ naa ki i ṣe tawọn oniroyin, gbogbo ibeere ti akọroyin wa si n bi i lo kọ lati da a lohun.

Amọ baba ọmọ naa ba akọroyin wa sọrọ, o ni nnkan to ja julọ ni itọju ọmọ naa nileewosan, ohun to lo ṣe pataki julọ niyẹn.

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.