Baale Olnilala ti Lanlate ti won yo nipo loun yoo pejo ko-te-mi-loru

Spread the love

Lẹyin ọdun mejidinlogun (18) ti awọn idile oye mẹta niluu Lanlatẹ, ni ipinlẹ Ọyọ, ti bara wọn fa wahala lori ọrọ oye ọba ilu naa, ile-ẹjọ ti rọ baalẹ ọhun, Abdullateef  Ọlawuyi Ọlagoke, loye, ṣugbọn ọkunrin naa ti n leri pe oun yoo pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

 

Idile oye meji ọtọọto, idile Oguntayi ati Adio lo n ba idile oye kan ṣoṣo ti wọn n pe ni Bioku fa a, wọn ni ọna eru lawọn Bioku gba fi ọkan lara wọn jẹ Onilala ti Lanlatẹ, nitori naa, awọn fẹ ki ile-ẹjọ le ijoye ọhun kuro nipo ọhun.

 

Sunday Bọlawaye Ọladẹjọ, Ọlagoke Atunwa, Ọmọọba Oyeleke Jọlaoṣo ati Raufu Adelọwọ  lati idile Adio ati Oguntayi ni wọn pẹjọ tako Oloye Ọlagoke ti i ṣe Onilala ti Lanlatẹ atawọn meji mi-in ti wọn ṣoju idile Oguntayi, iyẹn idile Baalẹ.

 

Gomina ipinlẹ Ọyọ wa lara awọn mẹrin yooku ti wọn jẹ olujẹjọ ninu ẹjọ naa. Awọn mẹta yooku ni alakooso eto idajọ ni ipinlẹ yii, kọmiṣanna fun eto oye jijẹ ati ọrọ gbogbo to jẹ mọ ijọba ibilẹ pẹlu ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa.

 

ALAROYE gbọ pe lọdun 2008 ni wọn fi Oloye Sunday Oluṣẹgun Ọladẹjọ jẹ Onilala ti Lanlatẹ, ni ibamu pẹlu ofin oye jijẹ tuntun (tọdun 2006). Ṣugbọn lọdun ọhun kan naa ni wọn rọ ọ loye, ti wọn si gbe Ọlagoke gori itẹ lọdun 2008 ọhun kan naa.

 

Eyi lo mu ki baalẹ ti wọn rọ loye atawọn idile oye ti wọn wa lẹyin rẹ gba kootu lọ lati tako igbesẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn lawọn idile ti ọrọ oye yii kan ti n ba ara wọn fa wahala lori ọrọ oye yii lati ọdun mẹjọ ṣaaju.

 

Ninu awijare awọn olupẹjọ ni kootu, wọn ni ofin oye jijẹ to ti wa nilẹ lati ọdun 1958 ni wọn lo lati fi Oloye Ọlagoke jẹ Onilala ti Lanlatẹ, dipo ofin tuntun tijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe lọdun 2006.

 

Awọn olupẹjọ sọ pe ki i ṣe Ọlagoke ni ipo ọhun tọ si nitori ipo naa ko ti i sun kan idile Bioku, nitori naa, ko ti i yẹ ki ẹnikẹni ninu wọn jọba bayii.

 

Ṣugbọn awọn idile Bioku ti wọn jẹ olujẹjọ sọ pe ko si ofin mi-in ti wọn fi n joye ni Lanlatẹ ju ofin ọdun 1958 lọ, ati pe ofin ọhun ko ri awọn olupẹjọ gẹgẹ bii idile to lẹtọọ lati jọba ilu naa.

 

Lọjọ Jimọh to lọ lọhun-un ni Onidaajọ B.A Taiwo ti ile ẹjọ giga to wa niluu Eruwa gbe idajọ ẹ kalẹ lori ọrọ yii lẹyin ọdun mejidinlogun ti awọn idile to n jija oye yii ti wa lẹnu ẹ.

 

Adajọ paṣẹ fun ijọba lati le Ọlagoke kuro lori ipo ti ko tọ si i to wa ọhun, ki wọn si da Ọladẹjọ ti wọn rọ loye lọna aitọ pada sipo ọba ẹ, ki wọn si da gbogbo ẹtọ to ti padanu lasiko ti wọn rọ ọ loye pada fun un.

 

Bakan naa l’Onidaajọ Taiwo kilọ fun baba to fi eru gbabukun naa lati yee pera ẹ ni Onilala ti Lanlatẹ mọ, bẹrẹ lati asiko idajọ yii lọ.

 

Pẹlu ahesọ iroyin ti wọn lo n lọ nigboro ilu Lanlatẹ, o ṣee ṣe ki awọn idile Bioku naa tun gba kootu lọ lati pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun tako idajọ naa, nitori wọn ni kinni ọhun ko dun mọ awọn ninu rara. Ṣugbọn awọn idile Ọladẹjọ sọ pe ẹnu lasan ni wọn fi n ṣe e, awọn ko ti i ri iwe ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun wọn latigba ti ile-ẹjọ ti da awọn lare.

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.