Ayọdele yinbọn pa ọrẹ rẹ l’Okelusẹ, lo ba n pariwo pe ẹlẹdẹ loun yinbọn si

Spread the love

Awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba gbe Ayọdele Aruliawoya, lori ẹsun yinyinbọn pa ọrẹ rẹ, Michael Anthony, niluu Okeluṣẹ, nijọba ibilẹ Ọsẹ, nipinlẹ Ondo.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn ọdọ kan ninu ilu naa ni wọn ko ara wọn jọ laarin ọsẹ to kọja yii lati lọọ sọdẹ bi wọn ti maa n ṣe ninu oṣu kin-in-ni, ọdọọdun.

 

Niṣe lawọn ọdẹ ọhun ti wọn to ogun niye pin ara wọn si oriṣiiriṣii ọna lẹyin ti wọn de inu igbo ti wọn ti fẹẹ ṣọdẹ pẹlu erongba ati fi awọn ẹran ti wọn fẹẹ pa si aarin.

 

Lẹyin bii wakati diẹ ti wọn ti bẹrẹ ọdẹ ṣiṣe ni Ayọdele sọ pe oun ri kinni kan to jọ ẹlẹdẹ igbo, loju ẹsẹ lo doju ibọn kọ ọ ohun to pe lẹranko ọhun.

 

Igbe oro to gbọ lati ẹnu Michael lo fi mọ pe eeyan loun yinbọn lu, ki i ṣe ẹlẹdẹ gẹgẹ bo ṣe ro.

 

Ọkunrin ọhun funra rẹ lo lọọ fara rẹ le awọn ọlọpaa to wa ni teṣan Ifọn lọwọ, to si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.

 

Ariwo ta a gbọ pe Ayọdele n pa ni teṣan to ti lọọ fẹjọ ara rẹ sun ni pe ẹlẹdẹ loun ri toun si yinbọn si, bi ẹranko ṣe pada waa di ọrẹ oun ti tawọn jọ n ṣọdẹ lo ṣe oun ni kayeefi.

 

Wọn ti fi oun ati ibọn rẹ ṣọwọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Akurẹ, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ. Bakan naa ni wọn ti gbe oku Michael pamọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa niluu Ifọn.

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.