Ayo ọlọrẹẹsọrẹẹ: Naijiria yoo koju Ukraine lalẹ oni

Spread the love

Ti nnkan ko ba yipada, aago meje aabọ alẹ oni lẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ wa yoo koju ilẹ Ukraine nibi ayo ọlọrẹẹsọrẹẹ ti yoo waye ni Dnipro, lorilẹ-ede wọn lọhun-un.

William Troost-Ekong ati Oghenekaro Etebo ni yoo ṣaaju awọn agbabọolu Naijiria lọ sibi ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin ti Ahmed Musa to jẹ balogun ikọ naa farapa lọsẹ to kọja.

Eyi ni ayo akọkọ ti Eagles yoo ti kopa lẹyin idije Afrika to waye laarin oṣu kẹfa si oṣu keje, ọdun yii, nilẹ Egypt, nibi ti Naijiria ti ṣe ipo kẹta.

Lara awọn agbabọọlu ti Gernot Rohr to jẹ kooṣi Eagles pe la ti ri awọn oju tuntun, eyi si waye lati ṣayẹwo fawọn agbabọọlu naa.

Awọn agbabọolu ti Rohr kọkọ pe ati kilọọbu ti wọn wa lọwọlọwọ ni:

Amule: Francis Uzoho (Anorthosis Famagusta, Cyprus); IkechukwuEzenwa (Heartland FC, Naijiria); Emil Maduka Okoye (Fortuna Dusseldorf, Germany).

Ẹyin: Ọlaoluwa Aina (Torino FC, Italy); Tyronne Ebuehi (FC Benfica, Portugal); Chidozie Awaziem (FC Porto, Portugal); William Ekong (Udinese FC, Italy); Leon Balogun (Brighton & Hove Albion, England); Kenneth Omeruo (CD Leganes, Spain); Jamilu Collins (SC Padeborn 07, Germany); Oluwaṣemilogo Ajayi (West Brom, England).

Aarin: Alexander Iwobi (Everton FC, England); Wilfred Ndidi (Leicester City, England); Oghenekaro Etebo (Stoke City FC, England); Kelechi Iheanacho (Leicester City, England); Joe Aribo (Glasgow Rangers, Scotland).

Iwaju: Ahmed Musa (Al Nassar FC, Saudi Arabia); Victor Osimhen (Lille OSC, France); Moses Simon (Levante FC, Spain); Henry Onyekuru (AS Monaco, France); Samuel Kalu (Girondins Bordeaux, France); Paul Onuachu (FC Midtjyland, Denmark); Samuel Chukwueze (Villarreal FC, Spain).

 Latari awọn ayipada to waye, awọn agbabọọlu marun-un lo kuro ni ikọ naa. Awọn ni: Ahmed Musa, Kenneth Omeruo, Tyronne Ebuehi, Henry Onyekuru ati Wilfred Ndidi.

Fun idi eyi ni Rohr fi pe Dennis Bonaventure lati Club Brugge, ilẹ Belgium, Josh Maja lati Bordeaux, ilẹ France, Anderson Esiti lati PAOK, ilẹ Greece, ati Bryan Idowu lati Lokomotiv Moscow, ilẹ Russia.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.