Ayederu ọga ṣọja ba ara rẹ l’ọgba ẹwọn n’Ilọrin

Spread the love

Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ni wọn wọ ayederu ọga ṣọja kan, Stephen Afọlabi, ẹni ọdun mejilelogoji, lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ilọrin, Adajọ Ibrahim Dasuki si ti paṣ̣̣ẹ ko wa lahaamọ ọgba ẹwọn ni Mandalla, fun pipe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ.

Agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni Ọlọrungbọn Ayọdeji ti kọkọ pe ASC Arẹmu Mayaki, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Sifu Difẹnsi to fi iṣẹlẹ naa to ẹka to n ṣewadii nileeṣẹ NSCDC niluu Ilọrin leti.

Ọkunrin to n ṣiṣẹ ni ẹka ileeṣẹ NSCDC niluu Ọffa, ọhun sọ pe Afọlabi n pe ara rẹ ni Lieutenant Colonel, eyi ti ko ri bẹẹ rara.

O ni iwadii ileeṣẹ ọlọpaa pada fi han pe olujẹjọ naa ko si lẹnu iṣẹ ologun rara.

Agbefọba ṣalaye pe lasiko ti ọwọ tẹ olujẹjọ naa, wọn ba fila awọn ologun to fi si iwaju ọkọ rẹ, nigba ti wọn si bi i leere ibi to ti ri i, o ni ẹgbọn oun kan torukọ rẹ n jẹ Ọlayẹmi Afọlabi lo ni i, bo tilẹ jẹ pe ko ti i si aridaju pe iyẹn jẹ ọmọ ileeṣẹ ologun.

Bakan naa niwadii tun fi han pe olujẹjọ naa n lo kinni ọhun lati maa fi gba owo ni tipa lọwọ awọn araalu.

Nigba ti ile-ẹjọ ka ẹsun naa si i leti, o ni oun ko jẹbi.

Adajọ Dasuki paṣẹ pe ko wa lahaamọ, o si sun ẹjọ naa si ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun yii.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.