Ayederu dokita fun Bidemi labere iku l’Ondo

Spread the love

Diẹ lo ku ki Isa Bidemi ku iku ojiji nigba ti ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Mọgaji Sanusi, to n gbe lagbegbe Sango, niluu Oṣi, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, fun un labẹrẹ mẹta gẹgẹ bii ogun inu rirun ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu ta a wa yii.

Sanusi ni wọn sọ pe o n pe ara rẹ ni babalawo fawọn eeyan agbegbe Sango, nibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye. Wọn ni Bidemi sọ fun Sanusi nirọlẹ ọjọ naa pe inu kan n yọ oun lẹnu, o si beere boya ọkunrin ti wọn mọ si babalawo naa le ri nnkan ṣe si i.

Loju ẹṣẹ ni wọn ni Sanusi ti kọwọ bọ apo rẹ, o ko abẹrẹ mẹta jade, to si sọ fun Bidemi pe ko tete gbe awọn abẹrẹ mẹtẹẹta naa mi to ba fẹ ki inu to n yọ ọ lẹnu ọhun dohun igbagbe kiakia.

Bi Bidemi ṣe gbe abẹrẹ yii mi ni wọn lo ti ṣubu lulẹ, to si n japoro iku, ni wọn ba sare gbe e lọ sileewosan, nibi wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun un lati tete ko awọn abẹrẹ mẹtẹẹta naa jade ninu rẹ ko too pẹ ju.

Ọkan ninu awọn ẹbi Bidemi, Ọgbẹni Ahmed Adebisi lo pada lọọ fẹjọ Sanusi sun ni teṣan ọlọpaa to wa niluu Osi, ti wọn si fi panpẹ ọba gbe ọkunrin ọhun.

Ọjọru, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja yii lawọn ọlọpaa pada wọ Sanusi lọ sile-ẹjọ majistreeti to wa niluu Igoba, nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe o fun Bidemi ni abẹrẹ mẹta lo gẹgẹ bii oogun, ati biba oogun abẹnugọngọ ni ikawọ rẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan an yii ni Agbefọba, Sajẹnti Ọmọlade Ṣọla, ni o tako abala ofin ẹẹdẹgbẹta o le mẹsan-an, to si tun ni ijiya labẹ abala ofin ojilelugba o le mẹta (243) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo tọdun 2006.

Sanusi gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, eyi lo mu ki agbefọba naa rọ Abilekọ Oluwafunmilayọ Ẹdwin to n gbọ ẹjọ naa pe ko si idi pataki kankan lati maa sun igbẹjọ siwaju mọ niwọn bi olujẹjọ rẹ ti gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. O ni ṣe lo yẹ ki igbẹjọ afurasi naa bẹrẹ lai fi akoko ṣofo.

Lẹyin ọpọlọpọ ẹri ti agbefọba ti fi siwaju ile-ẹjọ ni Abilekọ Edwin fidi ẹ mulẹ pe Sanusi jẹbi awọn ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, ati pe o di dandan ko lọọ fẹwọn oṣu mẹfa mẹfa jura lori ọkọọkan awọn ẹsun naa, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ogun naira gẹgẹ bii owo itanran.

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.