Aye yii ma le o Awọn ọmọ Buhari ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Tinubu lọwọ poo

Spread the love

Nibi ti nnkan wa bayii, o da bii pe ọwọ awọn ọmọ Buhari ti ba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ibi ti ọwọ wọn si ti ba a ko daa rara, ohun ti wọn fẹẹ ṣe fun un yoo da wahala silẹ, ko si si tabi ṣugbọn nibẹ, wọn ti ko ṣẹkẹṣẹkẹ si aṣaaju awọn oloṣelu ilẹ Yoruba naa lọwọ. Ọna meji lawọn ọta rẹ pin si lẹyin Buhari, awọn kan wa ti wọn ko fẹ ko sun mọ Aarẹ mọ, wọn ni o da bii pe baba naa n ba Aarẹ sọrọ, ohun to ba sọ ni Aarẹ maa n fẹẹ gbọ, ati pe Buhari ni awọn ọwọ ati apọnle kan fun un. Awọn eeyan yii ko fẹ bẹẹ, wọn ni yoo maa fi ṣe akọ kaakiri ni, iyẹn ni wọn ṣe fẹẹ le e lẹyin Buhari. Ṣugbọn awọn kan wa nibẹ ti wọn ni ki i ṣe bẹẹ, Tinubu n tan wọn ni, o fẹẹ ja Buhari kulẹ nigba ti iyẹn ko ni i le ṣe nnkan kan mọ ni. Awọn yii ti sọ fun Buhari laimọye igba pe Tinubu ki i ṣe ẹni to le fọkan tan rara.

Awọn mejeeji ti waa wa loju kan bayii o, ati awọn ti wọn n binu, ti wọn ṣi n wa ọna gbogbo lati din agbara Tinubu ku, ati awọn ti wọn ni ọkunrin oloṣelu naa fẹẹ ja Buhari kulẹ ni, awọn mejeeji ti pade loju kan naa bayii, ibi ti wọn si ti pade naa ni pe wọn ti ri ọna ko ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, ko si si ọna to le gba yọ ninu rẹ, nitori bo ba ti n sare sọtun-un, tabi sosi, bẹẹ ni ṣẹkẹṣẹkẹ naa yoo maa tubọ de e lọwọ si i. Ko sẹni to mọ ẹni to kọ wọn ni iru ọgbọn buruku bẹẹ, tabi ọna ti wọn gba ri i, ohun to ṣa ṣẹlẹ ni pe ọgbọn naa ṣiṣẹ, jinnijinni si mu Jagaban ati awọn to yi baba naa ka, nitori awọn paapaa gbọ ọrọ naa ni, wọn ko mọ ibi ti yoo ja si rara. Ileeṣẹ Tinubu kan ni wọn lọ, ileeṣẹ ti wọn n pe ni Alpha Beta, awọn aṣiri kan n jade lori ọrọ ileeṣẹ naa bayii, aṣiri naa lewu pupọ fun Tinubu.

O ti pẹ gan-an ti ẹnu ti n kun ileeṣẹ yii, o pẹ ti awọn eeyan ti mọ pe Aṣiwaju Bọla Tinubu lo ni ileeṣẹ naa, bo tilẹ jẹ pe o fi orukọ awọn eeyan kan digẹrẹwu. Iṣẹ ti ileeṣẹ Alpha Beta n ṣe fun ijọba ipinlẹ Eko ni lati ba wọn gba owo-ori wọn, iyẹn ni pe gbogbo owo-ori ti ijọba ipinlẹ Eko n gba patapata lati ọdun 2002, ileeṣẹ Alpha Beta lo n ba wọn gba a, nigba ti Tinubu funra rẹ si n ṣe gomina ipinlẹ Eko ni wọn ti gbe iṣẹ naa fun wọn. Bi ileeṣẹ yii ba gba owo-ori oṣu kan, owo ti wọn n ri gba maa n le ni biliọnu mẹẹẹdọgbọn owo Naira, ninu owo ti wọn ba si gba yii, bii ida ogun ni wọn yoo yọ sẹyin gẹgẹ bii owo iṣẹ tiwọn, iyẹn jẹ pe ti wọn ba gba biliọnu mẹẹẹdọgbọn fun ijọba Eko, biliọnu marun-un ni yoo jẹ tiwọn.

Bi owo-ori Eko ṣe n pọ si i, bẹẹ ni owo ileeṣẹ yii n pọ si i, o si pọ debii pe ẹnikan ko mọ iye ti owo naa n jẹ loṣu kan mọ bayii. Lati igba ti iṣẹ naa ti bẹrẹ lawọn eeyan ti n pariwo pe ọna ti Tinubu fi n ko owo Eko ree, ti awọn mi-in si n sọ pe ileeṣẹ naa ko ṣe iṣẹ gidi kan, nitori ọpọ iṣẹ ti wọn ni wọn n ṣe yii naa, awọn oṣiṣẹ ijọba ni Alausa ni wọn n ṣe e, awọn ni wọn n rin kiri lati gba owo-ori lọwọ awọn ileeṣẹ gbogbo, o kan jẹ orukọ Alpha Beta ni wọn fi n gba a ni. Lasiko ti ariwo naa pọ, Tinubu ati awọn eeyan rẹ da wọn lohun pe inu lo n run wọn, wọn kan n binu ori lasan ni, ẹni ti owo rẹ ba sọnu, ko lọ si kootu ko pẹjọ, bo si jẹ ọdọ awọn ọlọpaa ni yoo gba lọ. Ṣugbọn ko sẹni to le pẹjọ, tabi ti yoo lọ si tọlọpaa, nitori wọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ gan-an, ko si sọna ti wọn fi le ba ileeṣẹ naa ja.

Iyẹn lọrọ ṣe di họwuhọwu lọsẹ to kọja nigba ti ọga agba ileeṣẹ Alpha Beta tẹlẹ, ọkunrin kan tẹni kan ko gbọ orukọ rẹ fungba pipẹ, Ọgbẹni Dapọ Apara, jade, to ni ole lawọn n fi ileeṣẹ awọn ja ijọba ipinlẹ Eko, nitori bi awọn ti n ṣiṣẹ to, ti awọn si n ri owo nla nla loṣooṣu, awọn funra awọn ki i san owo-ori, ati pe ọpọlọpọ igba lo jẹ pe awọn maa n fi orukọ ileeṣẹ naa ko owo ijọba Eko jẹ ni. Bi ko ba ṣe pe Apara ni ọga agba fun ileeṣẹ naa lati ọdun yii wa ni, ko sẹni ti yoo gba ọrọ naa gbọ, wọn yoo ni awọn onibajẹ kan lo wa nidii rẹ ni. Ṣugbọn lati igba ti wọn ti da ileeṣẹ naa silẹ, Apara ni olori ileeṣẹ yii, oṣu to si lọ yii ṣẹṣẹ ni wọn ni ko kuro nileeṣẹ naa, nibẹ ni akara si ti tu sepo.

Akara ko le ṣe ko ma tu sepo, nitori orukọ ọkunrin naa wa ninu orukọ awọn ti wọn ni ileeṣẹ yii, nigba ti wọn fi n da a silẹ, ninu akọsilẹ ijọba, ida ọgbọn, taati pasẹnti (30%) lo ni ninu ileeṣẹ Alpha Beta. Ṣugbọn o jọ pe wọn kan fi orukọ rẹ digẹrẹwu lasan ni, nitori ẹtọ to tọ si i, ati owo to yẹ ko kan an gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti wọn jọ ni ileeṣẹ naa ko kan an, ẹjọ to si n ro bayii ni pe bii biliọnu marundinlaaadọta lowo ti awọn Tinubu jẹ oun ni ileeṣẹ Alpha Beta, ati pe awọn jọ ni ileeṣẹ naa ni, bo tilẹ jẹ pe wọn ko fun oun ni awọn ẹtọ oun. Ọkunrin yii ko mu ọrọ naa ni kekere rara, nitori ọdọ awọn EFCC lo gbe ẹjọ rẹ lọ, o ti kọwe si wọn, o si gba lọọya, lọọya yii, Adetunji Adegboyega, lo kọwe si EFCC.

Ohun to wa ninu iwe to wa lọwọ awọn EFCC yii ni pe ẹri wa gidigidi loju mejeeji lati fihan bi ileeṣẹ Alpha Beta ti n ji owo ijọba Eko ko, to jẹ ileeṣẹ naa fẹrẹ lowo ju ijọba funra rẹ lọ. Ninu lẹta ti wọn kọ yii ni wọn ti ṣalaye pe awọn ọna pọ loriṣiiriṣii ti awọn fi n ji owo ko, ati pe Apara to jẹ olori ileeṣẹ naa mo gbogbo ọna naa, ko si ohun ti wọn si fẹẹ mọ ti ko ni i sọ fun wọn. N lawọn EFCC ba sare gba iwe, wọn si ti kede bayii pe awọn yoo wadii ileeṣẹ naa, wọn yoo si mọ boya wọn ko owo jẹ tabi wọn ko ko owo jẹ. Apara ni loootọ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i le ẹmi oun kiri latigba ti oun ti kọwe si EFCC, ti awọn Tinubu si ti sare gbe ẹnikan, Doherty, lọ sibẹ pe ko maa ba awọn ẹri jẹ nibẹ, sibẹ, awọn ẹri to wa lọwọ toun bii olori ileeṣẹ naa fun ọpọlọpọ ọdun pọ ju ohun ti wọn le bajẹ lọ.

Nibi yii gan-an ni wahala ti de. Meji lọrọ naa pin si. EFCC le ṣe ẹjọ naa rabaraba. Ki i ṣe pe wọn yoo ṣe e rabaraba bẹẹ naa o, wọn yoo mọ idi otitọ, wọn yoo ko gbogbo iwe naa jọ, wọn yoo si ri i pe bi ọrọ naa ba de gbangba, ko si ki wọn ma da Tinubu lẹbi, bi wọn ba si da a lẹbi, ko si ki iru ẹjọ bẹẹ ma la ẹwọn lọ. Ṣugbọn ibi ti ẹjọ naa yoo lọ yoo duro lori iha ti Buhari ba kọ si i. Bi Buhari ba fẹ ki wọn ṣe ẹjọ naa, iyẹn bo ba jẹ iwa Tinubu ko tẹ ẹ lọrun, ẹjọ naa yoo de gbangba, yoo si di wahala si ọrun Jagaban. Nibi ti ṣẹkẹṣẹkẹ awọn ọmọ Buhari ti mu ọwọ Tinubu ree, wọn si ti fi de e lọwọ, wọn yoo maa fun kinni naa mọ ọn lọrun ọwọ nigbakigba ti wọn ba fẹ ni, ko si le bọ kuro nibẹ, nitori ko ni i le sọ pe oun ko ṣiṣẹ mọ fun Buhari layelaye.

Ṣugbọn, ọpọ awọn ẹgbẹ ajijagbara lo ti n da si ọrọ yii, wọn fẹẹ mọ abọ iwadii ti EFCC yoo ṣe, ati ibi ti wọn yoo fi ori ẹjọ naa ti si. Awọn ọmọ Eko naa ti n ṣara jọ bayii, wọn ni o pẹ ti wọn ti n sọ pe Tinubu n ji owo awọn ko. Ṣugbọn ijọba Eko funra wọn ti ni awọn ki i da si iru ọrọ bẹẹ, nigba ti EFCC ba pe awọn, awọn yoo mọ ohun ti awọn yoo sọ fun wọn.

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.