Aye ma waa le o! Taiwo fọgi mọ iya ẹ lori l’Ekoo O loun fẹẹ lo ẹjẹ rẹ ni

Spread the love

Niṣe ni gbogbo eeyan n kọ haa, kọ jẹ jẹ bẹẹ, nigba ti wọn gbọ iroyin pe ọmọkunrin kan, Taiwo Akinọla, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ṣa iya rẹ, Alice Iyabọ Akinọla pa. Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ni ojule keji, adugbo Raji Ajanaku, Alaja Road, Ayọbọ, niluu Eko. Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oogun owo ni ọmọkunrin naa fẹẹ fi iya rẹ ṣe, eyi ti wọn n pe ni ‘yahooplus.’

Nnnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ niṣẹlẹ naa waye, nigba ti ọmọkunrin naa lọọ ba iya yii ninu ile, to si ba ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbọn rẹ, Faruk, ọmọ ọdun mẹrinla lọdọ rẹ. Iwadii awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe ọmọkunrin ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ọhun lọ si ṣọọbu ti iya yii ti n ta atẹ, to si sọ fun un pe oun lọrọ pataki kan toun fẹẹ ba a sọ ninu ile, ko dakun, ko kuro ninu ṣọọbu naa, kawọn le jọ sọrọ. Lẹsẹkẹsẹ lo ran Faruk pe ko lọọ ba oun ra siga wa.

Bi iya yii ṣe wọle ni Taiwo bẹrẹ si i fi igi lu u lori, to si n jan ayọọnu ati waya ṣaaja mọ ọn, eyi to fi ri i daju pe ẹmi bọ lara iya to bi i lọmọ naa. Nigba ti Faruk to ran ni siga de ti ko ri iya-iya rẹ ni ṣọọbu lo wọ inu yara lọ, ṣugbọn inu agbara ẹjẹ lo ba obinrin naa, eyi lo si fa a ti ọmọ yii fi fariwo bọnu. Ariwo yii lo ta awọn araadugbo lolobo iṣẹlẹ yii.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn pe awọn ọlọpaa teṣan Ayọbọ, ti wọn si fi panpẹ ọba gbe Taiwo lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba. Lọwọlọwọ bayii, wọn ti gbe mama naa lọ si ọsibitu ti awọn ọlọpaa ko darukọ rẹ fun wa, ti Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, si ti san diẹ lara owo itọju naa, o ni ki wọn maa fi itọju iya naa falẹ rara.

Alukoro ọlọpaa, Chike Oti ni nigba tawọn n bi Taiwo leere, o sọ pe wọn ni ki oun pa iya oun ni koun baa le lowo, nitori ẹjẹ rẹ lawọn yoo lo. Ninu yara rẹ ti awọn ọlọpaa tu ni wọn ti ba igba meji, eyi ti agbari eeyan wa ninu rẹ, igi ti wọn fi eekanna eeyan si lara, ayọọnu ti ẹjẹ kun ara rẹ, ankaṣiifu to fẹẹ fi gbe ẹjẹ naa atawọn nnkan mi-in.

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.