Aye Akeredolu yii, nnkan ni l’Ondo o

Spread the love

Laye Lamidi Adedibu, Alaafin Molete niluu Ibadan, la ti ri i bi awọn tọọgi, awọn agbero, ṣe n fibọn, ada, igo ati kumọ gbajọba lọwọ awọn oloṣelu, ti wọn yoo si le awọn ọlọpaa sa wọgbo. Igba ti Adedibu ti ku lawọn eeyan ti ro pe ko tun si ibikibi nilẹ Yoruba ti awọn tọọgi yoo ti gbajọba lọwọ awọn oloṣelu ti araalu dibo yan, loju ọlọpaa ati loju awọn eeyan ilu gbogbo. Afi eyi to tun ṣẹlẹ l’Ondo lọsẹ to kọja yii. Ni tootọ, aye Rotimi Akeredolu yii, nnkan ni. Ohun to si n mu ọro yii ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe ọga awọn agbẹjọro, lọọya nla ti wọn n pe ni SAN ni Akeredolu, ko sẹni to ro pe iwakiwa ti ko ba ofin mu yoo jade si gbangba lasiko rẹ. Iroyin naa baayan ninu jẹ pe awọn agbero, awọn tọọgi ya lọ si ile-igbimọ aṣofin Ondo lọsẹ to kọja, ohun ti awọn eeyan naa si n sọ ni pe awọn gbọ pe wọn fẹẹ yọ gomina nipo lawọn ṣe lọ, ti wọn si le awọn aṣofin, ti wọn n lu wọn nigi, ti wọn yọ ada ati kumọ si wọn, ti wọn ṣe wọn ṣikaṣika bii ẹni ti ko jẹ nnkan kan. Wọn ti ṣe gbogbo aburu yii tan ki wọn too maa waa sọ pe awọn ko gbọ ọrọ naa daadaa ni, ẹni to pe wọn lati ọfiisi gomina ko mọ pe ki i ṣe gomina ni wọn fẹẹ yọ, olori ile-igbimọ aṣofin naa ni wọn fẹẹ yọ kuro nipo rẹ, ki i ṣe Akeredolu. Ṣugbọn ẹni to pe wọn lati ọfiisi gomina sọ pe Akeredolu ni awọn aṣofin fẹẹ yọ, iyẹn lawọn tọọgi ṣe ko ara wọn jọ ti wọn lọọ da ile-igbimọ naa ru. Bo ba tilẹ waa jẹ Akeredolu naa ni wọn fẹẹ yọ, ki lo kan awọn tọọgi, ki lo kan ẹgbẹ agbero, ki lo kan awọn ọmọ onimọto ninu ohun to ba ṣẹlẹ nile-igbimọ aṣofin gbogbo eeyan Ondo. Nibi ti awọn ti wọn n ṣejọba ba aye ara wọn jẹ de lẹ ri yẹn! Nibi ti awọn ti wọn n ṣejọba fi ara wọn wọlẹ de lẹ ri yẹn! Wọn ko le lo ọlọpaa, wọn ko le lo agbofinro mi-in, wọn ko si le lọ si ile-ẹjọ, awọn tọọgi lo ku ti wọn n lo! Ṣe ẹyin naa ri i pe aye Akeredolu yii, nnkan ni o!

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.