Awọn Yewa gbena woju INEC, wọn lawọn ko fẹ Dapọ Abiọdun

Spread the love

Ero rẹpẹtẹ lo wọ lọ si olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, laaarọ kutu Ọjọbọ to kọja yii. Ohun ti wọn ba wa pẹlu akọle ifẹhonu han lọwọ ni pe awọn ko fẹ Dapọ Abiọdun ti APC fa kalẹ, wọn ni ki INEC fagile ọmọ Ipẹru-Rẹmọ to fẹẹ di gomina Ogun yii.

Awọn olufẹhonu han naa ti wọn wa lati ẹkun idibo Yewa(Yewa Collective Action Movement), ti wọn si jẹ ọmọ ẹgbẹ APC ni wọn yari kanlẹ pe afi kawọn wọnu ọgba INEC lati fi ẹhonu awọn han laaarọ ọjọ yii.

Gbogbo bawọn agbofinro ṣe n di wọn lọna to, ti wọn ni awọn yoo yinbọn fẹni to ba kọja aaye ẹ, ko da awọn olufẹhonu han naa duro rara, niṣe ni wọn ni ija ẹtọ lawọn n ja, awọn ko kọja aaye awọn. Bi wọn si ti kuro lọfiisi ajọ eleto idibo bayii, ile ẹgbẹ APC lapapọ ni wọn wọ lọ.

Koko ohun tawọn eeyan naa n wi bi wọn ti to igba niye, ni pe awọn ko faramọ Dapọ Abiọdun ti APC fa kalẹ bii ondije dupo gomina ipinlẹ Ogun. Ohun ti wọn kọ sara paali ti wọn gbe dani ni pe ki ajọ INEC yọ orukọ ọkunrin naa kuro, ki awọn ajọ alaabo si ṣewadii Dapọ Abiọdun gidi.

Wọn ni awuruju ni ilana to gbe Dapọ wọle bii ondije dupo gomina.

Ẹ o ranti pe ọsẹ to kọja yii ni agbẹjọro kan pe Dapọ Abiọdun lẹjọ lori ẹsun ai ṣe agunbanirọ, eyi ti ko jẹ ko ri iwe-ẹri isinru ilu naa mu silẹ fawọn ajọ eleto idibo, to jẹ iwe-ẹri girama lasan ni wọn lo fẹẹ fi dije. Bẹẹ, iwa to lodi sofin ni keeyan ma sinru ilu lasiko ti ọjọ ori rẹ ko ti i kọja.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe kekere ṣi ni tawọn ara Yewa ti wọn n binu yii, wọn ni ọtẹ ṣi pọ ti yoo dide si ondije dupo yii, bẹẹ ni ẹsun mi-in yoo tun jade si ọkunrin to n polongo ibo kiri naa.

Ṣugbọn pẹlu gbogbo ẹsun to n dide si Dapọ Abiọdun yii, paapaa julọ, eyi to ni i ṣe pẹlu ai ṣe agunbanirọ, ọga elepo yii ko fesi si eyikeyii ninu wọn rara, niṣe lo n polongo ibo kiri ọdọ awọn ọba alaye, to n wa bi wọn yoo ṣe fi ontẹ lu oun gẹge bii ayanfẹ, bẹẹ lo si n kede ohun rere toun yoo ṣe fun ipinlẹ Ogun, bi wọn ba fi le gbe oun wọle sipo aṣẹ toun n du yii.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.