Awọn wo lo n dẹruba Ẹbọra Owu o

Spread the love

Iru ariwo wo ni Baba Ọbasanjọ n pa yii. Baba ma lọgun gan-an ni. Wọn ni awọn kan ti waa sọ fawọn pe gbogbo ọna ni Buhari n wa bayii lati ka ẹsun awuruju kan mọ oun lẹsẹ, bo ba si ti ka ẹsun naa soun lẹsẹ lawọn ọlọpaa yoo waa gbe oun, boya awọn SSS ni, wọn yoo si lọọ ti oun mọle. O ni eto ti Buhari n ṣe ni lati ti oun mọle fun ọjọ pipẹ, boya ni wọn yoo si jẹ ki oun jade ninu tubu ti wọn ba fi oun si titi ti wọn yoo fi ṣeto idibo to n bọ lọdun 2019. Iyẹn yoo le diẹ o! Baba naa ni oun ko fẹẹ ka ọrọ naa si nnkan kan tẹlẹ, ṣugbọn nigba to jẹ awọn ti wọn jẹ agbofinro, awọn ti wọn wa nidii eto naa tawọn Buhari gbe iṣẹ fun ni wọn ta oun lolobo lo jẹ ki oun tete pariwo jade. Ariwo naa daa loootọ. Ṣugbọn ẹni to tu itọ silẹ to fẹsẹ ra a mọlẹ, o mọ ohun ti awọn eeyan n fi itọ ṣe ni. Baba funra ẹ mọ ohun ti awọn n lo EFCC fun ati awọn ọlọpaa ijọba, to jẹ ẹni ti ko ba ti fẹ tẹni to wa nijọba, mimu ni wọn yoo mu un timọle lori ẹṣẹ awuruju. Ọbasanjọ naa gbọdọ ranti awọn ti oun ti mọle bẹẹ, o gbọdọ mọ awọn ti oun ṣe ohun ti Buhari fẹẹ ṣe fun un yii fun, nigba to jẹ ole ni i mọ ẹsẹ ole i tọ lori apata. Ṣugbọn ki Baba fọkanbalẹ, awọn Buhari kan fẹẹ halẹ mọ ọn lasan ni. Wọn fẹ ko sa ni, ko sa lọ siluu oyinbo ko le jẹ ki wọn raaye ṣe tiwọn, bi ko ba si sa lọ, ko sinmi jẹẹ nibi to ba jokoo si. Ẹni ti ko ṣe ohun itufu ko gbọdọ maa kiyesi ẹkule, bi Ọbasanjọ ko ba ti ṣe ohun kan ti ko dara, ko maa jaye ori ẹ nile. Wọn o sa gbọdọ beere lọwọ ẹ pe nibo lo ti rowo kọ otẹẹli ati ibudo nla to kọ si Abẹokuta, nigba to jẹ oju gbogbo aye lawọn eeyan ṣe fun un lowo, afi ti wọn ba fẹẹ sọ pe ko yẹ ko gba owo lọwọ awọn eeyan nigba to n ṣejọba nikan ni. Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, ko sẹni to to bẹẹ, wọn o le mu baba, Ẹbọra Owu ko ṣee gbe bẹẹ ko ma dijangbọn, ẹni ba dan an wo yoo dan an tan!

(86)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.