Awọn tọọgi oloṣelu ṣakọlu si oludije ẹgbẹ APC l’Ọwọ

Spread the love

Ija oṣelu to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ondo, tun  gba ọna mi-in yọ lọsẹ to kọja yii. Awọn tọọgi oloṣelu kan lo ṣe akọlu si ọkan ninu awọn oludije ẹgbẹ oselu naa ninu eto idibo ọdun to n bọ, Ọnarebu Ọlayatọ Aribo, ati awọn alatilẹyin rẹ meji mi-in. Ori lo ko awọn eeyan naa yọ lọwọ awọn janduku yii ti wọn ko fi ri wọn pa.

Ọlayatọ to fẹẹ dije-dupo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja ninu eto idibo ọdun to n bọ ni wọn ṣakọlu si lasiko to wa ninu ọkọ ipolongo rẹ laarin aago mẹwaa si mọkanla alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn tọọgi ọhun ti wọn lo ṣee ṣe ki wọn ti maa ṣọ Aribo tẹlẹ lo deede ya bo oun pẹlu awọn alatilẹyin rẹ lagbegbe Post Office, niluu Ọwọ, ti wọn si ṣina ibọn fun ọkọ ti wọn wa ninu rẹ. Ibinu pe ọnọrebu ọhun ati awọn to wa ninu ọkọ pelu rẹ lasiko akọlu naa raaye sa lọ ni awọn tọọgi naa fi dana sun ọkọ yii.  Nibi ti awọn eeyan kan ti n ṣaajo pe ki ọkọ naa ma jona di eeru ni awọn tọọgi naa tun ti ṣẹyọ, ti wọn si le gbogbo wọn danu, wọn si duro ti ọkọ naa titi to fi jona di eeru.

Nigba ti Ọnarebu Ọlayatọ n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, o ni oun ti fi to awọn ọlọpaa leti, pẹlu afikun pe awọn ọlọpaa ko ti i ri ẹnikankan mu lori iṣẹlẹ naa.

Gbogbo akitiyan wa lati ri Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ba sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ja si pabo, nitori nọmba rẹ ko lọ rara.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.