Awọn tọọgi ka baba arugbo mọ inu oko n’Ikọya, ni wọn ba sa a yanna yanna

Spread the love

Ori ko baba agbalagba kan, Adeniran Ọladunjoye, yọ lọwọ iku ojiji latari bawọn tọọgi kan ṣe ka a mọ inu oko niluu Ikọya, nijọba ibilẹ Okitipupa, ti wọn si ṣa a ladaa yanna-yanna.

 

Baba ẹni aadọrin ọdun naa ati ọmọ re kan to n jẹ Alaba, ni wọn jọ wa ninu oko laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, nigba tawọn tọọgi ọhun tun de, ti wọn si n ṣa wọn ladaa.

 

Awọn to wa nitosi lasiko iṣẹlẹ ọhun ni wọn sare gbe baba ati ọmọ rẹ lọ sileewosan ijọba to wa niluu Okitipupa fun itọju, lẹyin tawọn to ṣe akọlu naa ti ba tiwọn lọ.

 

Nigba to n sọ ohun toju rẹ ri fun wa nileewosan to ti n gba itọju niluu Okitipupa, Alagba Adediran sọ pe gbogbo ohun to wa lọkan awọn tọọgi ọhun ni lati gbẹmi oun sinu oko. O ni ọpẹlọpẹ ọmọ oun tawọn jọ lọ soko atawọn eeyan mi-in to wa nitosi ti wọn gba oun silẹ lọwọ awọn oniṣẹẹbi ọhun ti wọn ko fi ri oun pa.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lati nnkan bii oṣu diẹ sẹyin lawọn tọọgi kan ti wa n yọ awọn eeyan Odojọmu, niluu Ikọya, lẹnu lori ọrọ ilẹ kan ti wọn ti n fa mọ ara wọn lọwọ lati ọjọ pipe.

 

Gbogbo igba ni wọn ni wọn maa n ya bo awọn olugbe agbegbe naa pẹlu ada atawọn nnkan ija oloro mi-in nibi ti wọn ba ti n sisẹ ninu oko, ti wọn yoo si ṣe wọn lese.

 

Ibẹru akọlu ti wọn n ṣe si wọn yii ti da jinni jinni nla bo awọn eeyan ilu naa, to si ṣoro fun wọn lati maa lọ sẹnu isẹ wọn.

 

Awọn eeyan agbegbe ọhun to ba wa sọrọ rọ ijọba ipinle Ondo lati tete ba wọn da sọrọ naa. Wọn ni tijọba ko ba tete gbe igbesẹ lori rẹ, o ṣee ṣe kawọn wa gbogbo ọna tawọn yoo fi gbeja ara awọn, leyii to le dija igboro.

 

 

 

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.