Awọn to n ta ọwọ Naira foju bale-ẹjọ niluu Ilọrin

Spread the love

Awọn afurasi mẹrinla kan, ninu eyi tawọn obinrin meji wa ninu wọn nileeṣẹ ọlọpaa wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti fẹsun tita owo Naira.

Mujibat Shuaibu ati Zainab Akeyede ti wọn n ṣiṣẹ lọja Baboko, tawọn eeyan tun mọ si Ọja Tuntun, niluu Ilọrin, lọwọ tẹ pẹlu awọn mejila mi-in loṣu kọkanla, ọdun yii.

Awọn to ku ni; Haruna Yusuf, Adebayọ Habeeb, Gbadamọsi Noah, Abdulganiyu Jamiu, Isiaka Abdulekeem, Alaro Abdulkabir, Tayọ Ọlajide, Azeez Abdulakeem, Abdulateef Babatunde, Adebayọ Kazeem, Garuba Onimago Abdulgafar ati Abdulrasak Suleiman, ti gbogbo wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n tẹ iwe, ‘Lasoju Printing Press’ l’ọja Baboko.

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ pẹlu awọn DSS atawọn ẹka to n gbogun ti tita owo Naira ti banki apapọ lorilẹ-ede Naijiria, Central Bank, ni wọn gba awọn eeyan naa mu nibi ti wọn ti n ta owo.

Nigba ti wọn yẹ gbogbo ara wọn wo, wọn ba igba ati aadọta Naira tuntun ni beeli to le ni ẹgbẹrun lọna igba. Bakan naa ni wọn tun ba owo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹta Naira ti wọn ti pa ninu apoti kan ti wọn gbe sinu ileeṣẹ itẹwẹ ti wọn n ba ṣiṣẹ.

Awọn agbofinro naa tun fi panpẹ ọba gbe Ọgbẹni Suleiman to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ itẹwẹ naa.

Suleiman jẹwọ pe loootọ oun loun ni awọn owo naa, ati pe o ti pẹ toun ti n ṣowo tita owo tuntun.

Aṣoju ijọba, Isaac Yakubu, ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn. O rọ ile-ẹjọ lati sun ẹjọ naa siwaju kawọn ọlọpaa le pari iwadii wọn.

Adajọ M.D. Dasuki gba beeli awọn olujẹjọ naa pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ẹnikọọkan pẹlu oniduro meji niye kan naa. O sun ẹjọ si ọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019.

 

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.