Awọn ti wọn n ju satimọle yii nkọ, ṣe gbogbo wọn lọdaran ni

Spread the love

Nigba ti aarẹ kan ba wa lori ipo ti ko ba ṣe daadaa tobo ṣe yẹ, lara apẹẹrẹ ti eeyan yoo maari ni pe awọn agbofinro yoo maahe awọn oniroyin orilẹ-ede bẹẹ, ati awọn ajafẹtọọọmọ eniyan, ati awọn ti wọn ko ni ẹṣẹ gidi kan ti wọn ṣẹ, wọn yoo si maarọ wọn da si itimọle. Iru ohun ti awọn ileeṣẹDSS to wa lọdọ tiwa nibi n ṣe lati ọjọ yii wa niyẹn. Ọkunrin to wa nibẹ tẹlẹ, Lawal Daura, ko fẹ ki ẹnikẹni sọrọ to lodi si Buhari, ko fẹ kinni kan ti ko ni i jẹ ki Buhari tun wọle lẹẹkeji, iyẹnlo ṣe jẹ pe gbogboẹni to ba sọrọ si Buhari, ọta rẹ ni wọn, kia ni yoo si ṣeto ti wọn yoo fi gbe tọhun pamọ. Ohun to tumọ si ni pe awọn agbofinro DSS ti sọ ara wọn di oloṣelu ni, wọn n huwa oṣelu, nitori wọn n tẹle Buhari. Ọpọlọpọ awọn ti wọn ko pamọ laye Daura ni ọga tuntunto ṣẹṣẹ de si ileeṣẹ DSS yii ti n ṣi silẹ bayii nigba ti wọn wo ọwọ wọn ti wọn ko ba kinni kan nibẹ ju pe wọn sọrọ lọ. Oniroyin kan ti wọn ti mu lati ọdun 2016 ni Bayelsa, eyi tiwọn ṣẹṣẹ mu ni Abuja, ati awọn eeyan ti wọn ti rọ da si itimọle nitori ọrọ ti ko to ọrọ, tabi ọrọ ti ko tilẹ kan Buhari rara, gbogbo wọn ni ijọba DSS tuntun ti n ṣi silẹ. Ko si ohun meji to n fa eleyii ju peẹni to ṣẹṣẹ debẹ yii ko ṣe oṣelu lọ, ko si jẹ ki awọn ọmọẹyin rẹṣe oṣelu tawọn Buhari n ṣe bayii. Arun to n ṣe DSS yii lo n ṣe EFCC, ohun naa lo n yọ awọn ọlọpaa lẹnu. Ẹnikẹni to ba ti sọrọ odi si Buhari, tabi to ba ti kuro ninu ẹgbẹ Buhari, EFCC yoo wa ọran si i lẹsẹ, nigba naa ni wọn yoo ranti pe o kowo jẹ lọdun mẹwaa sẹyin. Ṣugbọn awọn ti wọn fẹ ti Buhari, ti wọn n ko owo jẹ lọwọlọwọ bayii, EFCC yooṣe bii ẹni pe oun ko ri wọn ni. Ẹni ba n sọrọ to  n tako Buhari,kia ni ọga awọn ọlọpaa pata naayooran eeyan lọọ mu un, wọn yoo gbe e janto, tabi ki wọn le e karakara, ki wọn si sa pada bi ọrọ naa ba di ariwo. Awọn yii ko ṣiṣẹ funNaijiria, Buhari ni wọn n ṣiṣẹ fun. Lara aburu to siwa nidii ki olori ijọba kan to ti wa niponi Naijiria tun fẹẹ tun ipo naadu lẹẹkeji niyi. Awọn aṣofin koni i ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, awọn agbofinro ko ni i ṣe tiwọn, awọn ọlọpaa yoo maa muuyan, awọn DSS yoo maahalẹ, awọn ṣọja yoo si maa yọbọn si alaiṣẹ kaakiri. Gbogbo awọn nnkan wọnyi ko le tun Naijiria ṣe o. Ẹ jẹ ka kuro nidii ẹ, ka ma fọwọ ara wa ba Naijiria yii jẹ patapata.

 

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.