Awọn SARS gba aṣẹ tuntun, bẹẹ ni ọga-agba ọlọpaa ṣẹkilọ fawọn ileewosan

Spread the love

Ọga-agba ọlọpaa nilẹ yii, Ibrahim Idris, ti paṣẹ fawọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale, iyẹn FSARS, pe wọn ko gbọdọ gbe ibọn lai wọṣọ iṣẹ, bẹẹ lawọn ileewosan gbọdọ bẹrẹ itọju ẹni tibọn ba ba ki wọn too sọ fawọn.

Awọn aṣẹ wọnyi waye lẹyin oriṣiiriṣii iroyin to n lọ nigboro nipa bi awọn FSARS ṣe n ṣiṣẹ lọna ti ko bofin mu ati bawọn eeyan ṣe n padanu ẹmi wọn nigba tawọn ọsibitu ba kọ lati tọju wọn nigba ti wọn ba ni ọgbẹ ọta ibọn.

Nigba to n sọrọ nipasẹ igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa kan, Adepọju Ilọri, ọga-agba naa ni, ‘’ Ko si ọmọ ikọ to n gbogun ti idigunjale to gbọdọ gbe ibọn lai wọṣọ iṣẹ. Iṣẹ ti wọn yoo maa ṣẹ ni ki wọn maa ṣewadii iṣẹlẹ idigunjale ati ijinigbe. Ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ yii yoo jiya nla.’’

Adepọju ni oun ati ACP Abayọmi Shogunlẹ pẹlu awọn mi-in ti lọ kaakiri ibudo awọn FSARS nilẹ Yoruba lati ṣayẹwo fun wọn, ati lati mọ boya awọn afurasi to wa lọdọ wọn ṣẹ ẹṣẹ to jẹ mọ iṣẹ ikọ naa, eyi to jẹ ọna lati ṣe atunto.

Adepọju ni, ‘’ Ni ibamu pẹlu aṣẹ aarẹ ilẹ yii lati ṣe atunto FSARS, ọga-agba ọlọpaa ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣayẹwo gbogbo awọn afurasi to wa lọdọ wọn. Aṣẹ ti wa pe aṣọ ọlọpaa ni SARS yoo fi maa ṣiṣẹ lati asiko yii lọ, ṣugbọn a maa pese aṣọ tiwọn laipẹ. Eyi jẹ ọna lati yago fun kawọn adigunjale maa fi orukọ ọlọpaa ṣọṣẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Shogunlẹ ni awọn ti ṣe awọn aṣeyọri kan lori atunto yii. O darukọ ọlọpaa kan, Charles Ọmọtọṣọ, ẹni to wa ni teṣan kan niluu Ikorodu, l’Ekoo, tọwọ si tẹ ẹ pe o n gba owo lọwọ awọn eeyan. O ni awọn ti le e danu, awọn mi-in ti wọn lọwọ ninu iwa naa si ti gba idajọ tiwọn pẹlu bi awọn ṣe din ipo wọn lẹnu iṣẹ ku.

Awọn aṣoju ọga-agba ọlọpaa naa waa ke sawọn araalu lati maa fi ọrọ awọn ọlọpaa to ba tapa sofin to ileeṣẹ naa leti, ki atunto to n lọ lọwọ le nitumọ.

 

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.