Awọn Saraki si ti sa lọ ni tiwọn

Spread the love

Nigba ti ijọba ba n lọ bo ti ṣe n lọ yii, ojuṣe awọn aṣofin ni lati tun nnkan ṣe, awọn ni wọn le pe aarẹ to ba fẹẹ ko gbogbo ilu wọgbo pada, awọn ni wọn yoo fi ofin ati ijiroro ta iru aarẹ bẹẹ ji. Bi aarẹ ọhun ba si ya aletilapa, awọn naa ni wọn le yọ ọ kuro nipo rẹ, nitori nigba ti wọn ba sọ fun un ti ko gbọ, bi wọn ba ti gbe awọn ti yoo yọ ọ nipo naa dide, kia ni yoo tun ero rẹ pa, ti yoo si ṣe ohun to ba yẹ ko ṣe. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ fawa, ko ri bẹẹ rara, nitori awọn aṣofin tiwa to yẹ ki wọn da si eto ijọba ko si nile, wọn ko si ti i ṣetan ti wọn yoo pada wa sile-igbimọ lati ṣe ofin. Bo ba jẹ wọn wa nile ni, bi Buhari yoo ba yan ẹnikẹni si ipo to lagbara bẹẹ, o di igba ti wọn ba fi ọwọ si i ko too le ṣe e. Ṣugbọn Buhari ti ri i pe wọn ko si nile, o ti sare yan eeyan sipo olori DSS, oju si n kan an debii pe lọjọ to yan an naa lo ni ki iyẹn bẹrẹ iṣẹ. Gbogbo aye kan n pariwo pe Naijiria ko ni ilọsiwaju ni, awọn oṣelu ti a n ṣe yii ko le jẹ ki ilọsiwaju kan ba orilẹ-ede yii. Ohun ti ko si dara nibẹ ni pe Buhari yii lọpọ ọmọ ilẹ yii ti ro pe yoo tun nnkan ṣe fun wa, aṣe aṣiṣe gbaa la ṣe, nitori eyi ti oun n bajẹ yii, bii ogun ọdun si ọgbọn ọdun si asiko yii, ko ni i ti i ṣee tun ṣe. Awọn ọmọ Naijiria ko fẹran ara wọn mọ, oun si ti fi ẹlẹyamẹya ya gbogbo wọn sọtọ, Hausa n fojoojumọ koriira Yoruba ati Ibo, Yoruba n fojoojumọ koriira Ibo ati Hausa, awọn Ibo naa ko si ṣọrẹ ẹnikankan ninu awọn mejeeji. Oṣelu jẹunjẹun lawọn aṣofin ati awọn oloṣelu to ku n ṣe, wọn ti pa gbogbo iṣẹ ijọba ti bayii, ipo oṣelu ni wọn n wa, bi wọn yoo ti di olori orilẹ-ede yii, tabi ti wọn yoo di gomina, tabi ti wọn yoo tun pada si ile-igbimọ aṣofin ni wọn n le kiri. Bẹẹ gbogbo eleyii ki i ṣe nitori ifẹ ilu, wọn kan fẹẹ maa fi wa jẹun lasan ni. Ọlọrun o, lọjọ wo lo fẹẹ gba wa lọwọ awọn ika eniyan wọnyi o!

(38)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.