Awọn ọta ni wọn wa nidi ọrọ satifikeeti mi – Ademọla Adeleke ..Idojuti lo jẹ fun PDP – OCGC

Spread the love

Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun latinu ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ni ariwo to n lọ kaakiri lọwọlọwọ nipa ọrọ iwe-ẹri oun ko ṣẹyin iṣẹ ọwọ awọn agbesunmọmi kan ti wọn ko fẹ ki oun di gomina ipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn ajọ kan ti ki i ṣe tijọba, Osun State Coalition for Good Governance (OCGC) sọko ọrọ sawọn adari ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu

PDP fun bi wọn ṣe ja awọn araalu ni tan-mọ-ọn pẹlu oludije ti wọn gbe silẹ.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin ipolongo Adeleke, Ọlawale Rasheed, fi sita lọjọ isinmi to kọja ni Adeleke ti sọ pe ọpọlọpọ ni bi oun ṣe jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ PDP l’Ọṣun jẹ iyalẹnu fun, idi si niyi ti wọn fi pinnu lati maa sọ oriṣiiriṣii nnkan nipa oun.

O ni ko bojumu lati da ọmọ tuntun nu pẹlu baafu iwẹ, ko si yẹ ki wọn maa wo aṣiṣe ranpẹ to wa ninu deeti iwe ‘mo pari’ (testimonial) ti oun gba nileewe ‘Ẹdẹ Muslim Grammar School’, bi ko ṣe ki wọn wo boya oun kunju oṣunwọn lati dari ipinlẹ Ọṣun tabi bẹẹ kọ

Adeleke ni iṣẹ takuntakun loun ti ṣe nile igbimọ aṣofin agba toun wa laarin ọdun kan pere, oniruuru erejẹ ijọba tiwa-n-tiwa loun si ti mu ba awọn eeyan oun, eleyii ti ọpọlọpọ to ni satifikeeti gan-an ko ṣe, idi si niyi to fi n dun awọn ọta oun pẹlu bi awọn araalu ṣe n fẹran oun lojoojumọ.

 

Amọ ajọ OCGC ni ṣe lawọn ẹgbẹ oṣelu PDP ri awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fin pẹlu oludije ti ko ni iwe ẹri ti wọn gbe kalẹ lati koju Gomina Rauf Arẹgbẹṣọla ti gbogbo eeyan mọ si ọlọpọlọ pipe, “bo tilẹ jẹ pe ko lo ọgbọn rẹ lọna ti yoo gba tu awọn araalu lara.”

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Akin Akinsọla, ni ọrọ iṣejọba kuro ni eyi ti ẹnikan ti ko ni ọgbọn atinuda ati imọ kikun nipa aato ilu le deede jẹ gaba le, wahala tijọba APC si ti da silẹ nipa eto ọrọ aje ipinlẹ Ọṣun bayii kuro ni ẹru ọmọde, o nilo ẹni to gbọn ninu, gbọn lode.

Akinṣọla ṣalaye pe, “Ẹgbẹ oṣelu PDP nikan ni ireti awọn araalu lati gba wa ninu iṣejọba inira ti APC ko wa si l’Ọṣun, a mọ bi ilu ṣe ri laye Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, koda, nnkan ko buru bayii laye iṣejọba Oloye Bisi Akande, ko sẹni ti ko ni imọlara iṣejọba onidaji owo oṣu ti Gomina Arẹgbẹsọla n ṣe bayii, idi si niyẹn ti a fi gbagbọ pe nnkan yoo yipada loṣu kẹsan-an, ọdun yii, tijọba yii ba le kogba wọle.

 

“Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe oludije ti wahala wa lori ọrọ iwe-ẹri girama rẹ ni wọn fa kalẹ lati ṣe gomina le wa lori, laye to jẹ pe awọn obi ti wọn ko lowo lọwọ gan-an n tiraka, ti wọn si n lakaka lojoojumọ lati ri i pe awọn ọmọ wọn kẹkọọ to ye kooro nileewe.

 

“Ki lo de ti ẹgbọn oludije wọn, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si olowo rẹpẹtẹ ko lo aburo rẹ gẹgẹ bii oludari ni ẹka kankan ninu awọn okoowo oriṣiiriṣii to ni to ba mọ pe o kunju oṣuwọn, ṣugbọn to waa jẹ pe ṣe lo ni ko waa dari iṣejọba ipinlẹ Ọṣun, nibi ti nnkan ti bajẹ kọja aala.

 

“Awa n fi asiko yii sọ fun awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP lati tun ero wọn pa lori ọrọ yii, aimọye awọn ti wọn kunju oṣuwọn ninu ẹgbẹ naa ti wọn le ṣe gomina, to waa jẹ pe ẹni ti gbogbo eeyan mọ pe oye iṣejọba ko ye ni wọn fa kalẹ. Mo fẹ ki wọn mọ pe anfaani nla ni wọn ni lasiko yii tawọn eeyan n beere fun ayipada to dara, bi wọn ba ti ṣi i lo, ọdun mẹjọ mi-in ni wọn ṣetan lati lo gẹgẹ bii ẹgbẹ alatako niyẹn.”

 

Lọna mi-in ẹwẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ni anfaani wa mọ fun ẹgbẹ to ba fẹẹ paarọ orukọ ẹni ti wọn yoo lo gẹgẹ bii igbakeji gomina, ọrọ naa o ti i loju ninu ẹgbẹ PDP bayii, o si da bii ẹni pe ṣe ni yoo tubọ mu iyapa ba wọn si i.

 

Ohun ti a gbọ ni pe ni kete ti wọn ti kede Ademọla Adeleke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori lo ti mu Ọnọrebu Albert Adeogun lati ilu Ileefẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ, o si ti fi orukọ rẹ silẹ lọdọ awọn ajọ eleto idibo orilẹede yii (INEC).

 

Ṣugbọn nigba ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa l’Abuja da si ọrọ ede aiyede to bẹ silẹ laarin Adeleke ati Ogunbiyi ti wọn jọ dije pamari naa ni wọn sọ pe ṣe ni ki wọn pin ipo ọhun. Wọn gba Adeleke niyanju lati yọnda ki ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ wa lati ọdọ Dokita Akin Ogunbiyi, niwọn igba to jẹ pe alagbara jọ lawọn mejeeji.

 

Bayii lawọn alatilẹyin Ogunbiyi dabaa orukọ awọn mẹta fun Adeleke lati mu ẹni kan laarin wọn. Awọn mẹtẹẹta ọhun ni Ọjọgbọn Durotoye, Dokita Ayọade Adewọpo ati Kọla Daisi Aina.

 

Nigba ti wọn pada de Oṣogbo, wọn ranṣẹ si Adeogun pe ko waa kọwe gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin idibo pe oun finu-findọ yọnda ipo igbakeji gomina fun ẹlomi-in, ṣugbọn a gbọ pe Adeogun sọ fun wọn pe ki wọn jẹ koun lọọ jiṣẹ fawọn eeyan wọọdu oun, latigba naa ni wọn ko ti gburoo eegun to n jẹ Ajikẹ mọ.

 

Ohun tawọn eeyan Ogunbiyi n sọ ni pe ṣe ni Ademọla Adeleke mọ-ọn-mọ sọ fun Adeogun pe ko gbọdọ yọnda ipo yẹn fun ẹnikẹni nitori wọn ko nigbẹkẹle kikun ninu ẹnikẹni to ba wa lati ọdọ Ogunbiyi lati ṣe igbakeji Adeleke.

 

Idi si niyi ti ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe n sọ pe ti nnkan ba n lọ bẹẹ titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an tidibo gomina yoo waye, irọrun lo ba de fun oludije latinu ẹgbẹ oṣelu APC.

(119)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.