Awọn ọrẹ Yusuf ko fẹ ko mu igbo mọ, ni wọn ba gun un nigo sakasaka

Spread the love

Lagbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, lawọn ọrẹ ọmọkunrin kan, Yusuf Jelili, ti fi afọku igo da ọgbẹ si i lara, ileeṣẹ ọlọpaa si ti wọ wọn lọ sile-ẹjọ lọsẹ to kọja. Awọn olujẹjọ naa ni; Jamiu Abdulsalam, Waheed Hassan,  Abdulrasaq Bọlaji, Abubakar Taofeeq, Samson Babaleke, Dauda Abdullahi, Abubakar Usman, Hassan Isiaq  ati Salihu Yahaya.

 

Inspẹkitọ Isaac Yakubu to ṣoju ijọba ṣalaye pe Yusuf lo mu iṣẹlẹ naa lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Tankẹ, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii.

 

Jẹlili ṣalaye nile-ẹjọ pe awọn ọrẹ oun to n jẹjọ naa pẹlu ọkan to n jẹ Baba Musa, toun ti sa lọ bayii lo kọlu oun. O ni wọn ko afọku igo ati okuta lati da ọgbẹ soun lara nitori bi wọn ṣe loun ko figbo mimu silẹ.

Agbefọba naa ni awọn olujẹjọ ọhun fi okuta ati afọku igo ya ori ati apa ọmọkunrin yii. O ni wọn tun ji foonu rẹ to to ẹgbẹrun marundinlọgọta Naira, ati owo to le ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgọta Naira lọ.

O ṣalaye pe lasiko iwadii ileeṣẹ ọlọpaa, ọhun tawọn olujẹjọ naa sọ ni pe awọn fẹẹ kọ ọ lọgbọn ni, nitori bo ṣe kọ lati tẹle ikilọ awọn.

Ṣugbọn wọn lawọn ko jẹbi ẹsun naa, nigba tile-ẹjọ ka a si wọn leti.

Adajọ W. B Saka gba oniduuro wọn ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira ẹni kọọkan ati oniduuro meji.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.