Awọn onimọto wan-ṣansi mẹta bọ sọwọ ọlọpaa l’Atan-Ọta

Spread the love

Ikọ ẹlẹni mẹta kan ti wọn maa n fi mọto wọn ja awọn ti wọn ba wọ ọ lole lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ri mu lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, to ṣẹṣẹ pari yii. Orukọ awọn mẹta naa ni Aisu Anago, Muritala Alubarika ati Noah Joel.
Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ latọdọ Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, agbegbe Atan-Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo-Ọta lọwọ ti ba wọn lọjọ yii, nigba ti obinrin kan ti wọn ja lole, Abilekọ Taye Olotu, lọọ fẹjọ wọn sun awọn ọlọpaa to n wọde laduugbo naa, ti wọn si tẹle e de ibi tawọn oni wan-ṣansi naa wa.
Alaye ti Abilekọ Olotu ṣe fawọn ọlọpaa ni pe oun wọ mọto awọn eeyan mẹta yii lasiko kan ninu oṣu keji, to pari yii, o loun n lọ s’Idiroko lọjọ naa ni. O ni yatọ si dẹrẹba, awọn meji kan jokoo sẹyin ọkọ naa, oun si ṣikẹta wọn.
Obinrin naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe igba tawọn de idaji ọna ni awọn meji toun ba ninu ọkọ kọju ija soun, bi wọn ṣe gba gbogbo ohun toun ni lọwọ tan ni wọn ti oun jade ninu mọto naa, ti wọn ba tiwọn lọ.
Obinrin yii sọ pe lẹyin iṣẹlẹ naa loun tun ri awọn onimọto to ja oun lole yii ti wọn n pero si mọto kan naa, oun si da wọn mọ daadaa. O loun si mọ pe ọpọ eeyan ni yoo tun fi aimọkan wọnu ọkọ naa, ti wọn yoo lu wọn, ti wọn yoo tun gba dukia wọn. Abilekọ Olotu ni idi niyẹn toun fi ta awọn ọlọpaa toun ri nitosi ibẹ lolobo, ti wọn fi mu wọn.
Lẹyin tawọn ọlọpaa mu Aisu, ẹni ọgbọn ọdun, Muritala, ẹni ọdun mejilelogoji ati Noah, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, wọn jẹwọ pe mọto naa ki i ṣe mọto ero tootọ, wọn ni ole lawọn fi n ja.
Awọn gende mẹta naa ṣalaye pe ọna tawọn n gba ṣiṣẹ naa ni ko ye awọn ero to n wọ mọto awọn, ti wọn fi n bọ sọwọ.
Wọn ni bi dẹrẹba ba ti jokoo laaye tiẹ tan, ẹyin lawọn meji yooku maa n jokoo si, awọn yoo si ri i daju pe aarin lawọn faaye silẹ si fẹni ti ko dakan mọ to fẹẹ wọ mọto naa.
Wọn ni nigba tawọn ba de idaji ọna, paapaa nibi ti ko ba si ero lawọn yoo fokun de e, awọn yoo yọ ada si i lati ma jẹ ko le pariwo, nigba naa lawọn yoo gba gbogbo ohun to ba ni pata, lawọn yoo ba ju u si titi.
Wọn jẹwọ pe loootọ lawọn ja obinrin to fẹjọ awọn sun yii lole ninu oṣu to kọja. Wọn ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira(100,000), lawọn gba lọwọ ẹ, kawọn too ti i bọ silẹ ninu mọto wan- ṣansi naa.
Nigba ti wọn yẹ ara awọn mẹta yii wọ, ada kan ati okun ti wọn fi n de ẹni ti wọn ba gbe lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn.
Ẹka to n ri si igbogun ti idigunjale ni CP Iliyasu Ahmed paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ, fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.